You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkọ̀ ojú omi dojúdé lójú agbami ní ìpínlẹ̀ Niger, èèyàn 61 kú, ọgọ́rùn ún míràn di àwátì
Nnkan bii eeyan ọgọrun ni wọn ṣi n wa bayii nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi kan to waye ni alẹ ọjọ Iṣẹgun.
Iroyin sọ pe awọn ero bii ọọdunrun lo wa ninu ọkọ oju omi naa eyi to gbera irinajo ọhun lati ileto kan ti wọn n pe ni Mundi.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe ọgọta eeyan lo ti ku ninu ijamba ọkọ oju omi naa. Iroyin naa sọ pe ọpọ awọn ero ọkọ naa ni wọn jẹ obinrin ati ọmọde n lọ si ibi ajọdun ọdun musulumi kan ti wọn pe ni Maulid ni ilu Gbajibo.
Olori ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Niger,, Abdullahi Baba Arah ṣalaye ninu atẹjade kan pe ajọ naa ti bẹrẹ igbesẹ ti bẹrẹ lati wa awọn eeyan to ṣi wa ninu agbami naa pẹlu iranwọ awọn omuwẹ lagbegbe naa.
Ọgbẹni Baba Arah sọ pe bi awọn eeyan agbegbe naa ṣe taraṣaṣa dide iranwọ fun idoola ẹmi awọn eeyan naa kun ara oun to mu ko ṣeeṣe lati doola ẹmi awọn aadọjọ eeyan ti wọn ti ri gbe jade. O ṣalaye siwaju sii pe iṣẹ ati ṣe awari awọn to ṣi ku sinu odo naa ṣi n lọ lọwọ.
Ko tii si ẹni lee sọ ni pato ohun gan to ṣokunfa ijamba ọkọ oju omi yii. Amọṣa gbọnmọgbọnmọ ijamba ọkọ oju omi n waye lori odo ọya Niger, paapaa julọ lasiko ojo nigba ti odo naa maa n kun. Bakan naa lọpọ awọn onwoye ti sọ lọpọ igba pe awọn ọkọ oju omi ti wọn n lo fun igbokegbodo irinna oju omi nibẹ ati lọpọ agbegbe lorilẹede Naijiria ti di ẹgẹrẹmiti ti wọn si maa n ko ero akoju. Bakan naa si ni awọn panti, ẹka igi ati iti igi ti agbara ojo n gba si oju omi yii maa n ṣe akoba fun awọn ọkọ oju omi wọnyii.
Ni oṣu kẹsan an ọdun to kọja, ko din ni eeyan mẹrinlelogun to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ oju omi to fi ara pẹ eyi lagbegbe naa. Aadọta ero ni ọkọ oju omi naa ko nigba naa lasiko ti wọn n lọ si oko lati kore oko wọn ni ọkọ oju omi ti wọn wa dojude loju agbami.