Ọlọ́pàá tó gún èèyàn lọ́bẹ pa nítorí igba náírà, ohun tí a mọ̀ rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọlọpaa kan, Mohammed Bulama, ti ipo rẹ jẹ ‘Inspector’ lẹnu iṣe naa ni iroyin kan laipẹ yii, pe o gun ẹnikan lọbẹ, nipinlẹ Yobe, ẹni naa si pada jade laye.

Igun ọlọpaa 41 Division to wa ni Damaturu, olu ipinlẹ Yobe, ni Bulama ti n ṣiṣẹ, ẹni ti wọn si ni o gun lọbẹ pa ni Abdulmalik Dauda.

Ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ni Dauda to di oloogbe, inagijẹ ti wọn si mọ ọn si ni Baksha.

Ki ọlọpaa Bulama too gun Dauda pa yii, ijakadi ni wọn lo kọkọ ṣiwaju, iyẹn lọjọ iṣẹlẹ naa ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an ọdun 2024.

Agbegbe Pompomari, ni Damaturu ni wahala naa ti ṣẹlẹ, nibi kan ti wọn n pe ni Zango.

Kí ló fà á tí ọlọ́pàá fi ń wọ̀yá ìjà, kó tóó gúnbẹ?

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Yobe, DSP Dungus Abdulkarim, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kin-in-ni oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii, pe,

“Ni nnkan bii aago mẹfa kọja ogun iṣẹju lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2024 yii, ọrọ kan ṣẹlẹ laarin Inspector Mohammed Bulama ati Abdulmalik Dauda.

‘’Ọrọ naa pada di ohun ti wọn n lu ara wọn, ninu rẹ la si ti gbọ pe Bulama gun Dauda lọbẹ láyà, o tun fi ori ṣeṣe’’.

‘’Ẹsẹkẹsẹ ni wọn mu ọlọpaa Bulama ni teṣan ọlọpaa C Division, nibi to sa si lẹyin ija to ran Dauda si ajule ọrun.

‘’Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ko ni i fi aaye gba iwakiwa latọdọ awọn oṣiṣẹ rẹ, a maa ri i daju pe idajọ ododo waye, ẹni to huwa aitọ yoo si foju wina ofin.’’

Alukoro ọlọpaa Yobe koro oju si iṣẹlẹ yii, o ba ẹbi Oloogbe Dauda kẹdun, o si fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe idajọ ododo waye.