‘Ní ìgbà kan, ìdùnnú la fi ń ṣe àyájọ́ òmìnira, ṣùgbọ́n báyìí inú ogun la wà’ àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ èrò wọn nípa àyájọ́ òmìnìra

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede Naijiria n ṣe ayajọ ominira rẹ eyi to gba lọjọ kini oṣu kinni ọdun 1960. Lẹyin ọdun mẹrinlelọgọta, awọn ọmọ Naijiria sọ ero wọn lori ipo ti orilẹede naa wa, yala ni ibamu pẹlu erongba awọn aṣiwaju to ja fun ominra rẹ ni tabi ti awọn ọmọ orilẹede naa to n gbe ninu rẹ bayii.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, awọn to sọrọ ṣalaye pe nnkan o rọrun , nnkan nle sii ni, lọpọ igba si ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria si n wo o pe ṣe ajọyọ ni ayajọ ọjọ yii nilo ni tabi ikarisọ.

Inu ogun la wa, ko si idunnu fun ẹnikẹni lati ṣe ajọyọ ominira orilẹede Naijiria – Oloye Ọladele

Ninu ọrọ rẹ, Oloye David Ọladele ṣalaye pe ko si idunnu ninu ajọyọ ayajọ ominira Naijiria mọ gẹgẹ bi ti igba kan.

Oloye Ọladele ṣalaye pe iriri ti awọn eeyan ti ri bi orilẹede Naijiria ṣe n dagba sii ko dun mọ ọpọ ninu ko si fun ọpọ ni idi lati rẹrin lasiko ajọyọ ayajọ naa mọ.

“O da bi ẹni pe Ọrọ Ọlọrun lo n ṣẹ̀ lorilẹede Naijiria. Agbara kankan o si ti a ro pe boya ijọba kankan le ṣe fun wa kọja eyi ti a ti n ba bọ.

“Ọgọfa Naira ni owo oṣu mi ni nnkan bii aadọta ọdun sẹyin. Mo ni iyawo, mo ni ọmọ. Mo ni aburo iyawo mi to n gbe ọdọ mi nigba naa. Nnkan ko wọn to gbogbo bayii nigba naa. Ọwọngogo to n ṣẹlẹ bayii, inu ogun la wa bayii, ki Ọlọrun ko la wa ni.”

Oloye Ọladele ni ko si idunnu kankan fun araalu lati fi ṣe ajọyọ ominira nitori pe ọpọ ni ko ri ounjẹ ẹẹmẹta jẹ lojumọ.

Ninu gbogbo nnkan, o yẹ ki a maa dupẹ - Ọmọwe Elizabeth

Ni tirẹ, Ọmọwe Funkẹ Elizabeth gbagbọ pe ko si idi fun awọn ọmọ Naijiria lati sọ pe awọn ko ni ṣe

ajọyọ naa nitori pe ninu ohun gbogbo ti ẹda ba ba ara rẹ, ọpẹ lo yẹ ko maa da.

Ọmọwe Elizabeth ṣalaye pe igbagbọ oun ni pe ọrọ awọn ọmọ Naijiria tọpẹ bi o tilẹ jẹ wi pe nnkan le ma a ri gẹgẹ bi kaluku ṣe fẹ.

O ni ni awọn akoko kan lorilẹede Naijiria, nṣe ni inu awọn ọmọ maa n dun ni ireti ajọyọ ayajọ yii. Amọṣa o ni ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii nitori pe nnkan ti yipada.

Ẹ wo fidio yii lati mọ ohun ti awọn ọmọ Naijiria ni i sọ lori ayajọ ominira Naijiria lẹyin ọdun mẹrinlelọgọta.