You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí Saudi Arabia ṣe lé Gumi padà sílé láì dúró ṣe iṣẹ́ Hajj
Awọn alaṣẹ lorilẹede Saudi Arabia ti fofin de olori ẹsin kan lorilẹede Naijiria, Sheikh Ahmad Gumi lati ma wa si orilẹede naa fun sise iṣẹ Hajj ọdun yii.
Gumi fun ara rẹ lo gbe ikede yii si oju opo Facebook rẹ pe, ijọba Saudi fun oun ni fisa lati wa si orilẹede naa ṣugbọn wọn ko gba oun laye lati lọ si ilu Medina fun iṣẹ ẹṣin.
"Nitori awọn iha ti mo kọ si oṣelu agbaye, awọn alaṣẹ Saudi kọ fun mi lati wa nibi iṣẹ Hajj ọdun yii bo ti lẹ jẹ pe wọn fun mi ni fisa," Gumi gbe eyi soju opo ayelujara rẹ.
"Mo dupẹ lọwọ awọn alaṣẹ Naijiria ti wọn da si ọrọ naa, ti wọn si ba awọn alaṣẹ Saudi sọrọ.
Iroyin to tẹ BBC lọwọ ni pe Sheikh Ahmad Abubakar Gumi wa lara awọn onimọ ti ajọ to n mojuto Hajj lorilẹede Naijiria- NAHCON ṣe onigbọwọ fun lọ si Saudi Arabia fun Hajji.
Gumi balẹ si Medina ni ọjọ Ṣatide to kọja ni dede ago mẹwaa abọ pẹlu ọkọ ofurufu Umza ṣugbọn bi o ṣe de papakọ ofurufu, ni awọn asọbode gbegi dina rẹ, ti wọn ko si fun ni anfani lati wọ orilẹede naa.
Gumi ti pada si orilẹede Naijiria bayii, to si ti tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ to jẹ olukọ.
Ta ni Sheikh Ahmad Abubakar Gumi?
Onimọ nipa ẹsin Islam ni Sheik Ahmad Gumi jẹ, oun si ni akọbi Shaykh Abubakar Gumi, ti wọn bi ni ilu Kano,
Oun ni Mufti ati Mufassir Mọsalasi gbogboogbo ni ilu Kaduna
Ẹya Fulani ni Gumi, to si jẹ onimọ ati ọmọogun tẹlẹ pẹlu ileeṣẹ ologun Naijiria,
Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni Ahmad Abubakar Gumi, to si lọ si ileewe Sadauna Memorial College ati fasiti rẹ ni Ahmadu Bello University to ti kọ iṣẹ gẹgẹ bi dokita,
Lẹyin naa lo darapọ mọ ileeṣẹ ọmọọogun Naijiria, Nigeria Defence Academy to si ṣiṣẹ de ipo Captain pẹlu ikọ ọmọogun Naijiria, ko to fẹyinti lẹnu iṣẹ.
Oun lo fi akori ọrọ kan ''My Vote, My Pride'' sita ni ọdun 2014.