You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló dé tí wọn kò sin okù bàbá olówó lẹ́yìn ọdún mọ́kànlá tó jáde láyé?
- Author, Basillioh Rukanga
- Role, BBC News in Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ majistreeti kan ni Kenya sọ pe o ṣeeṣe ki wọn sin oku ọmọ ilẹ Gẹẹsi to ti wa nile igbokupamọsi lati ọdun mọkanla sẹyin.
Ninu ọsẹ yii wọn yoo pari ẹjọ nipa ohun to ṣekupa ọkunrin naa ti won ti n ṣewaadi rẹ bẹrẹ lọdun 2013.
Igbẹjọ naa kan ẹsun fifi majele ṣekupani, igbẹjọ to n wọ ẹsẹ nilẹ ati wiwu oloogbe lẹyin nnkan bii ọdun kan ti wọn ti kọkọ sin oku ọhun.
Ọrọ naa le to bẹẹ to fa ipinya laarin ọmọ iya mẹrin – ti wọn jẹ ọmọ rẹ ọkunrin lati igbeyawo rẹ akọkọ atawọn ọmọ rẹ obinrin meji lati igbeyawo rẹ keji.
Ninu ọkan ninu lawọn ọjọ igbẹjọ naa, adajọ ba ibatan meji Hellen ati Alexandra wi lori pe wọn jagbe mọ ẹlẹrii lẹnu pe irọ lo n pa, koda adajọ ọhun ni wọn le sun atimọle mọju.
Lasiko igbẹjọ mii Hellen Veeger wa sile ẹjọ pẹlu aṣọ kan to ni akọle lara pe "Ko si ẹnikẹni to gbẹmi baba mi."
Bo tilẹ jẹ pe igbẹjọ ẹni ọdun mẹrinlọgọta naa pẹ jọjọ, adajọ David Odhiambo sọ pe awọn ko le sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa latari bi ara rẹ ṣe jẹra to ṣaju iwadii.
O ti paṣe ki wọn gbe oku ọkunrin naa fun awọn mọlẹbi rẹ lati lọ sin si ibikibi to ba wu wọn.
Awọn agbẹjọro igun mejeji ti ba BBC sọrọ nibi ti wọn ti sọ igbesẹ to kan fun wọn.
Agbẹjọro Francis Kinyua Kamundi to n sọju awọn ọmọ rẹ ọkunrin Richard ati Philip sọ pe "Lẹyin ti mọlẹbi ti pin si meji tan, bawo ni ile ẹjọ ṣe maa sọ pe ki wọn yọnda oku fun mọlẹbi lati igba ti ija ti bẹrẹ lọdun 2013?"
Nigba to bẹrẹ si n ka idajọ rẹ to ni awẹ marundinlọgọrun, adajọ majistreeti naa sọrọ lori ija to n waye laarin awọn ọmọ baba ọhun.
Adajọ sọ pe "lootọ ni pe iku ololufẹ ẹni maa n mu irẹpọ wa laarin awọn ẹbi rẹ amọ iku eeyan tun le tu awọn mọlẹbi rẹ ka.
Ọgbẹni Odhiambo ni "Ohun to ṣẹlẹ lẹyin isinku rẹ tu mọlẹbi rẹ ka, eyii lo si bẹrẹ ogun igbẹjọ laarin igun mejeji."
Lapa kan igun naa ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin wa, nigba ti awọn ọmọ rẹ obinrin wa ni igun keji igbẹjọ ọhun pẹlu iya wọn, Azra Parvin Din.
Ilẹ Gẹẹsi lawọn ọmọ rẹ ọhun n gbe nigba ti baba wọn ati arabinrin Parvin Din, ti wọn ti wa papọ fun ọgbọn ọdun n gbe ni eti okun orilẹede Kenya.
Ija idile naa bẹrẹ lẹyin iku rẹ nile rẹ to wa niluu Mobasa, ni ayajọ awọn ololufẹ ninu oṣu Keji, ọdun 2013.
Awọn ọmọ rẹ rinrinajo lọ ba ni Kenya, kete ti wọn de ibẹ ni ija bẹrẹ.
Ija naa burẹkẹ si lọjọ kẹrindinlogun ninu oṣu Keji, to jẹ ọjo to ṣaaju ọjọ isinku rẹ.
Gẹẹ bii ohun ti Richard Veevers sọ nile ẹjọ, Parvin Din binu nigba ti wọn bere nipa iku oloogbe naa lọwọ rẹ. Philip tun sọ fun ile ẹjọ pe o kọ jalẹ nigba ti oun sọ pe ko jẹ ki oun wo oku baba oun.
Parvin Don sọ pe niṣe ni oloogbe ọhun fo ṣanlẹ ku lẹyin ti ọkan rẹ sadede kọṣẹ.
Nigba ti awọn ọmọ rẹ ọkunrin yoo ri oku rẹ lọjọ keji, wọn ni awọn ṣakiyesi pe oju rẹ pọn awọn awọ kan si yọ si ete rẹ.
Amọ wahala bẹrẹ nigba ti Parvin Din atawọn ọmọ rẹ binu pe awọn ọmọ rẹ ọkunrin ya aworan oku rẹ, ti wọn si bere pe ki wọn yọ aworan kuro lori ẹrọ ilewọ wọn.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ ni Alexandra Veevers sọ ninu ẹri rẹ pe oun ko ri apa kankan lara baba oun ati pe oju rẹ nikan loun ri nitori wọn ti fi aṣọ we oku ọhun.
Lẹyin awuyewuye laarin awọn ibatan naa ni wọn sin oku baba wọn lai ṣe iwadii ohun to gbẹmi rẹ, bẹẹ ni won ko fi lọ ọlọpaa.
Ile ẹjọ ni arabinrin "Pardin Din lo ni ki wọn lọ sin oku rẹ lai kọkọ ṣe iwadii ohun to gbẹmi rẹ, bẹẹ ni ko kan si ẹnikẹni lori rẹ."
Awọn ọmọ oloogbe ọkunrin tun ni awọn fura pe ejo lọwọ ninu iku baba awọn nitori ti wọn tete sin oku rẹ ni ilana ẹsin Musulumi amọ baba awọn kii ṣe Musulumi, orukọ mii si ni wọn fi sin in.
Gẹgẹ bii akọsilẹ awọn iwe ile ẹjọ, Richard Veevers "beere eredi ti wọn fi sin oku baba wọn bii Musulumi nigba to jẹ ọmọlẹyin Kristi ti wọn tun sọ pe ti wọn ba sin oku naa si gbangba, awọn kan le lọ wu oku naa lati ji wura ti wọn sin mọ ọ.
Parvin Din nigba to n fesi ni oloogbe naa ti gba ẹsin Musulumi ṣaaju iku rẹ.
Lẹyinorẹyin, awọn ọkunrin mejeji fẹsun kan Pardin Din atawọn ọmọ rẹ obrinrin pe awọn lo fun baba awọn ni majele jẹ ki wọn le jogun awọn dukia ati ọrọ rẹ, amọ wọn ni ọrọ ko ri bẹẹ.
Ohun to mu ki ọrọ naa buru si ni pe oloogbe ko ni akọsilẹ bi wọn yoo ṣe pin ogun rẹ lẹyin iku rẹ.
Awọn ohun to yi iku naa ka lo mu ki awọn ọmọ rẹ naa pe ẹjọ pe ki wọn wu oku baba wọn lati ṣe iwadii iku rẹ.
Nigba ti yoo di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2013, ile ẹjọ ni ki wọn lọ wu oku ọhun amọ wọn ko wu oku naa titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2014 - iyẹn lẹyin nnkan bii oṣu mẹsan an.
Agbẹjọro igun awọn ọkunrin ni awọn obinrin lo fa idiwọ naa.
Nigba ti wọn yoo wu oku naa, o ti jẹra kọja didamọ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, adajọ sọ pe nitori ara ọkunrin naa ti jẹra kọja bo ṣe yẹ, o ṣoro lati mọ nnkan to ṣokunfa iku rẹ ninu iwadii.
Lara awọn nnkan to mu ki ẹjọ naa falẹ ni orniruru awọn esi iwadii to yatọ si ara wọn.
Awọn oluwadii kan sọ pe awọn ri ohun to farajọ majele ninu ara rẹ ati ninu ilẹ ti wọn sin in si, awọn mii ni ko ri bẹẹ.
Yatọ si eyii, awọn idajọ kan ti waye amọ awọn ọmọ oloogbe ọkunrin n pe ẹjọ kotẹmilọrun tako awọn igbejọ naa.
Adajọ sọ pe oriṣiriṣi nnkan lo ti ṣẹlẹ lẹyin iku oloogbe ṣugbọn awọn ko le sọ boya iku rẹ ti ọwọ ẹnikẹni waye, yala ẹni naa mọọmọ ni o tabi o ṣeṣi.
O ni dokita to kọkọ yọju oloogbe naa lo yẹ ko gba iyawo rẹ, Pardin Din lamọran lati fi to ọlọpaa leti lẹyin iku rẹ, ko si bere iwadii ohun to pa a.
O ni kikuna lati ṣe eyii lo mu ko ṣoro lati mọ kulẹkulẹ ohun to fa iku rẹ, ohun lo tun jẹ ki igbẹjọ ọhun wọlẹ fun ọpọ ọdun.
Yatọ si ohun to gbẹmi rẹ, ede aiyede tun ti n waye lori ibi to yẹ ki wọn sin oku rẹ si.
Awọn ọmọ rẹ ọkunrin sọ pe ọmọ bibi ilẹ Gẹẹsi ni, nitori naa ilẹ Gẹẹsi ni wọn gbọdọ sin in si, amọ awọn ọmọ rẹ obirin kọ jalẹ pe pe ilẹ Kenya ni ki wọn sin oku rẹ si.
Adajọ ni o ṣoro lati paṣẹ ibi ti wọn gbọdọ sin oku rẹ si nitori ko si ofin to sọ nipa ibi ti wọn gbọdọ sin eeyan si ni Kenya.
Ni bayii, adajọ ti ni ki awọn ẹbi naa gbe ọrọ ibi ti wọn yoo sin oku rẹ si lọ ile ẹjọ mii.
Bẹẹ lo tun sọ pe ki wọn gba ile ẹjọ miran lọ lati ba wọn da si bi wọn yoo ṣe pin ogun rẹ.
Lẹyinorẹyin, bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ti yanju ọrọ ohun to ṣokunfa iku rẹ, ati sin oku oloogbe naa le maa ti ya kankan.