Jàpa: Ìjọba UK fòfin de ọgọ́rùn-ún iṣẹ́ tí àwọn àjòjì ń ṣe tẹ́lẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lojuna ati din bi awọn eeyan ṣe n japa lọ si orilẹede United Kingdom ku, ijọba ibẹ ti fofin de iṣẹ to le lọgọrun-un ti awọn ajoji ti n ṣe tẹlẹ lorilẹede naa.

Ọjọ Satide, ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni ọfiisi ijọba UK kede eyi loju opo X wọn.

Ikede naa ṣalaye pe awọn gbegidina awọn iṣẹ naa fun awọn ajoji, ki awọn oṣiṣẹ ọmọ Gẹẹsi le ni anfaani iṣẹ to tọ si wọn.

Wọn fi kun un pe eyi yoo yi ilana atijọ ti orilẹede naa ti n ba bọ nipa awọn ajoji ṣe n gba fisa ilu naa pada.

"Bi a ṣe fẹẹ din bi alaejo ṣe n wọle ku tumọ si fifun awọn to yẹ ni ẹtọ wọn.

"O le ni iṣẹ ọgọrun-un ti awọn ajoji ko le ṣe mọ bayii – eyi ti yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ilẹ Britain riṣẹ ṣe si i.

"Ilana to n pin in dọgba to si n lo awọn to kaju ẹ lo wọle de yii"

Bẹẹ ni atẹjade ti ọfiisi UK fi sita naa wi.

Àwọn iṣẹ wo ni òfin yìí kàn?

Diẹ lara awọn ẹka iṣẹ ti ofin naa kan ni:

Igbalejo bii iṣẹ otẹẹli, iṣẹ oluranlọwọ lẹka ilera, ṣiṣe eto lilọ bibọ nnkan eelo ati itọju wọn, awọn iṣẹ ti ijọba n ṣagbatẹru rẹ fun araalu ati awọn ileeṣẹ ọlọgbọn atinuda.

Awọn iṣẹ wọnyi ni ọpọlọọ ajoji maa n ni lọkan pe awọn yoo le maa ṣe bawọn ba de UK, nitori wọn jẹ iṣẹ ti ofin fọwọ si to si tọna labẹ ofin igbanisiṣẹ UK, iyẹn ṣaaju ofin to de yii.

Ọfiisi UK yii ko ti i fi ẹkunrẹrẹ awọn iṣẹ naa lede lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Igbesẹ yii n waye lẹyin ti Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer, gbajọba loṣu Keje ọdun to 2024.

Ṣugbọn awọn awoye ọrọ ti n koro oju si igbesẹ naa, wọn ni yoo wulẹ mu adinku ba awọn oṣiṣẹ lẹka ilera ati itọju ni.