Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ máa ná owó naira àtíjọ́ lọ - Gomina El-Rufai

Gomina ipinlẹ Kaduna, Gomina Nasir El-Rufai ti sọ fun awọn eniyan nipinlẹ naa lati maa na owo naira atijọ lọ.
Eyi ko ṣẹyin aarẹ Muhammadu Buhari ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Keji, ọdun 2023 to ba gbogbo awọn ọmọ Naijiria sọrọ pẹlu aṣẹ pe owo 200 naira atijọ nikan ni awọn eniyan le na.
Amọ Buhari kede pe ẹnikẹni to ba ni 500 naira ati 1000 naira si ile ko lee na mọ nitori o ti lukudeeti.
O paṣẹ fun awọn eniyan lati mu owo naa lọ si CBN fun ayipada sinu apo isuna wọn.
‘’Mo fi da ẹyin eniyan loju pe ko si ẹni ti yoo padanu owo rẹ ninu o jẹ owo atijọ.’’
Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-rufai lasiko to n ba awọn araalu rẹ sọrọ lẹyin ikede aarẹ paṣẹ fun awọn eniyan lati maa gba owo naira atijọ nipinlẹ naa.
O kesi awọn ara ipinlẹ Kaduna lati gba alaafia laaye, nitori ofin wa lati fi yanju ọrọ to n lọ naa nipa owo naira atijọ ni Naijiria.
El rufai ni ‘’Mo fi da ẹyin eniyan loju pe ko si ẹni ti yoo padanu owo rẹ ninu o jẹ owo atijọ.’’
Ẹ ma jẹ ki gbendeke kankan di yin lọna lati na owo naa, paapaa awọn to wa ni igberiko ati ilu kereje ti banki ko si nibẹ.
Ẹ ma da ara yin laamu lati maa wa ibi ti ẹ o ti na owo atijọ naa, ẹ mu dani ki ẹ si tẹlẹ aṣẹ ileẹjọ to gajulọ.
'Ijọba tiraka lati mu ki a gbe ẹjọ kuro ni ileẹjọ to gaju lọ, amọ a fariga'
Gomina ipinlẹ Kaduna naa ni ko si gbedeke kankan to lee tẹ oju ofin Naijiria mọlẹ
‘’Ofin to de banki apapọ Naijiria ti ọdun 2007 pọn dandan fun CBN lati gba owo atijọ lọwọ awọn eniyan ni igbakugba ti wọn ba gbe lọ si banki.’’
‘’CBN gbọdọ gba naira atijọ lọwọ awọn eniyan bi o tilẹ pe ọgọrun-un ọdun ki wọn to daa pada fun CBN.’’
El-Rufai ni ọrọ ti aarẹ Buhari sọ pe ki awọn eniyan maa na 200 naira ni awọn gomina ti kọ jalẹ fun Buhari nitori ko rọrun fun awọn araalu.
El-Rufai ni ijọba kede pe awọn ti jo 500 naira ati 1000 naira ti awọn araalu da pada lo mu ki awọn fi 200 naira pada sita.
Amọ gomina ipinlẹ Kaduna naa ni awọn kọ jalẹ fun ijọba apapọ nitori ẹri wa wipe awọn owo yii ṣi wa ni ikawọ banki apapọ.
‘’A maa ba yin gba owo yin pada’’
Gomina El-Rufai tun ṣeleri fun awọn araalu pe awọn yoo rii pe awọn ba wọn gba awọn owo naira atijọ naa papọ, ti wọn a si gba tuntun pada.
O ni awọn aṣojuṣofin wọn, to fi mọ awọn aṣoju ẹka si ẹka ni awọn yoo lo lati mu aye rọrun fun awọn eniyan nipa owo naira tuntun ni Naijiria.
Bakan naa ni gomina naa ni lẹrọlẹrọ ni yoo bade fun wọn nigba ti wọn ba da owo wọn pada fun wọn.
‘’A o ri pe aṣẹ ileẹjọ to gajulọ ni Naijiria bori’’
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Jigawa ti paṣẹ pe aṣẹ ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria ni yoo bori lori ọrọ yii.
Eyi tumọ si pe awọn eniyan gbọdọ maa gba owo atijọ naa, paapaa ni banki.
Kọmiṣọna fun awọn iṣẹ akanṣe, Anwal Sankara lo kede bẹẹ.
Wọn kilọ fun awọn banki, awọn ẹgbẹjẹgbẹ pe ẹnikẹni ti ko ba tẹle aṣẹ ijọba ipinlẹ naa nipa gbigba owo atijọ yoo fi oju wina ofin.
Aarẹ Buhari tàpá sofin ileẹjọ gíga pẹ̀lú ìkéde rẹ̀ lórí owó náírà tuntun - Agbẹjọro

Oríṣun àwòrán, Others
Agbẹjọro agba kan lorilẹede Naijiria, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Jiti Ogunye, ti ni aarẹ Muhammadu Buhari tapa si ofin ileẹjọ pẹlu bi o ṣe paṣẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa na 200 naira atijọ titi di Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹrin , ọdun 2023. Agbẹjọro Jiti Ogunye lasiko to n ba ileeṣẹ BBC sọrọ ní, ohun ti aarẹ Buhari ṣe lo ni awọn kọnu-n- kọhọ ninu.
O ni bio tilẹ jẹ pe ileẹjọ giga julọ lorilẹede yii ko lagbara lati gbe aarẹ rele ẹjọ nitori agbara ati aṣẹ "imuniti" to ni, ko bojumu lati tapa si aṣẹ ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria.
''Ile Asọfin gbọdọ yọ Buhari nipo lori ọrọ ọwọngogo Naira''
Ogunye ni awọn araalu gbọdọ ṣetan lati sọ fun awọn aṣoju ti wọn diboyan lọ silẹ igbimọ aṣofin lati mu aba ti yoo yọ aarẹ nipo wa si ile igbimọ aṣofin.
O ni botile jẹ wi pe aarẹ Buhari ti ń lo saa re tan lọ aba lati yoo nipo le ma nilo mo.
Ajafetọ ọmọniyan naa ni aarẹ Muhammadu Buhari fẹnu tẹmbẹlu ilana ofin Naijiria, nigbati oun lọ awọn abala ofin kan lati kede pe ki igba naira ó wà fun nina.
Agbẹjọro miran, Monday Ubani ni iṣẹ loye kí aarẹ Muhammadu Buhari duro kí ile ẹjọ to gajulo paari igbejọ rẹ lori owo naira tuntun, kí aarẹ to paṣẹ fun banki apapọ lati pese igba naira atijọ fun nina.
Aarẹ lo ti paṣẹ fun ile ẹsẹ banki apapọ orilẹ-ede yii pe ki wọn o fon ọpọlọpọ owo igba naira ti awọn eniyan n na tẹlẹ sita fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii lati maa na.
Ti a ko ba gbagbe, lọjọ keedogun oṣu yii nilẹ ẹjọ agba tori lẹ ede yi sun igbejọ ṣiwaju Lori ẹjọ ti awọn gomina ileyi kan pe lati fi tako side paṣipaarọ ati kiko awọn owo naira wa kan nilẹ.















