You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ètò ìṣèjọba rere ló lè dẹ́kun ìdìtẹ̀-gbàjọba tó ń wáyé láwọn orílẹ́èdè àjọ Ecowas - Tinubu
Aarẹ orilẹede Naijiria to tun jẹ alaga ajọ awọn orilẹede iwọ-oorun ilẹ Afirika, Ecowas, Bola Tinubu ti rọ awọn olori orilẹede ajọ naa lati gbajumọ iṣejọba rere ati igbayegbadun awọn araalu.
Aarẹ Tinubu sọrọ yii nibi ipade ajọ Ecowas to waye lọjọ Aiku niluu Abuja.
Tinubu ni ‘’ọna kan gboogi niyii lati dẹkun iditẹ-gbajọba to n ṣẹlẹ lemọlẹmọ ni ẹkun iwọoorun ilẹ Afirika.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin aarẹ Tinubu, Ajuri Ngelale fi sita lọjọ Aiku, aarẹ Naijiria ni eto iṣejọbo rere gan an lo le jẹ ki idagbasoke to gbewọn waye lawujọ.
Alaga ajọ Ecowas ṣalaye pe ‘’nipa pipese eto iṣejọba-rere, iṣoro iṣẹ ati osi to n bawọn eeyan finra yoo di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ, ati pe ko ni si iditẹ-gbajọba.’’
Bakan naa ni Tinubu tun ṣalaye ajọ Ecowas yoo tun bawọn olori ijọba ologun awọn orilẹede ti iditẹ-gbajọba ti waye lẹkun iwọ-oorun Afirika sọri lori ati da ijọba pada fun ijọba alagbada.
Tinubu sọ pe dida ijọba pada fun alagbada lawọn orilẹede yii ko gbọdọ pẹ rara.
Aarẹ Naijiria fikun ọrọ rẹ ajọ Ecowas ṣetan lati ṣe atilẹyin fawọn orilẹede tọrọ kan pẹlu eto ati da ijọba pada.
Tinubu tun lo anfani to ni lati lu aarẹ George Weah orilẹede Liberia lọgọ ẹnu lori bi o ti gba pe oun fidi rẹmi ninu ibo aarẹ to waye laipẹ lorilẹede naa.
Lori laasigbo to n ṣẹlẹ ninu eto iṣejọba lorilẹede Sierro Leone ati Guinea Bissau, Tinubu sọ pe ajọ Ecowas ko ni faye gba ijọba to lodi sofin lẹkun iwọ-oorun Afirika.