Wo kókó pàtàkì tàwọn olórí yóò fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé Ecowas tí yóò wáyé ní Abuja

Awọn olori ajọ idagbagsoke ọrọ aje agbegbe iwọ oorun ilẹ Africa ,Ecowas, yoo joko ipade lọjọ Aiku yi lolu ilu Naijiria tii ṣe Abuja.

Ipade naa yoo jiroro lori ọrọ to niiṣe pẹlu ọrọ aje agbegbe naa ati awọn ipenija mii bi iditẹgbajọba to n waye.

Bẹẹ naa ni wọn yoo forikori lori awọn ijiya ti wọn fẹ gbe lori orileede Niger ati eleyi to ti wa lori rẹ tẹlẹ.

Ipade ajọ naa to waye kẹyin mẹnu ba bi nkan ti ṣe ri ni Niger lẹyin iditẹgbajọba ologun to waye ni ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Keje eyi to mu ki wọn yẹ aga nidi aarẹ ti araalu dibo yan Mohamed Bazoum.

Molly Phee,to jẹ igbakeji akọwe lori ọrọ agbegbe ia oorun nilẹ Africa forileede America ti de si Naijiria lati kopa nibi ipade yi.

Lasiko abẹwo rẹ yi, yoo jiroro, paapa pẹlu alaga ajọ Ecowas tii ṣe Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, lori ọna ti ilẹ America fi le ṣatilẹyin lori dida orileede Niger pada soju ọna ijọba awarawa.

Wọn yoo tun ṣepade lori mimu idagbasoke aabo ati ifọkanbalẹ to peye ba agbegbe iwọ oorun ilẹ Africa.

Ajọ Ecowas ti ṣaaju gbe awọn ijiya kan lelẹ lori Niger ti eleyi si n mu ipalara ba awọn eeyan orileede naa.

Onwoye kan lori ọrọ agbegbe yi totun jẹ oludari ajọ Center for Democratic Development to wa ni Abuja, Ọjọgbọn Jibrin Ibrahim sọ fun BBC pe ipade yi ṣe pataki.

O ni idi ni pe mẹrin ninu awọn orileede mẹẹdogun to kora jọ ninu ajọ naa ni iditẹgbajọba ti waye.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o di dandan bayi ki Ecowas ṣagbeyẹwo nkan to ba fẹ ṣe nipa ipenija iditẹgbajọba to n waye yi .

Bẹẹ naa lo sọ pe wọn ni lati fidi ohun to yẹ ki wọn ṣe lati ri pe awọn ọmọ ogun to gbajọba da ijọba pada ki wọn faramọ ijọba awarawa ki iru iditẹgbajọba yi si ma waye mọ lawọn orileede to ku.

Ọjọgbọn Jibrin fikun pe ko yẹ ki ipade yi gbẹsẹ kuro lori awọn ijiya to gbe lori Niger.

O ni Ecowas naa sọ pe ''ti a ba gbẹsẹ kuro lori ijiya wọnyii, awọn ologun yi yoo ro pe ko si nkan ti ẹni kan le ṣe ffawọn tori naa wọn yoo tẹsiwaju pẹlu iṣejọba wọn.''

Idi ree gẹgẹ bo ṣe salaye ti Ecowas ko fi gbọdọ gbẹsẹ kuro lori ijiya wọnyii