You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba kéde kónílé-ó-gbélé lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé ní Sierra Leone
Ìjọba orílẹ̀ èdè Sierra Leone ti kéde òfin kónílé ó gbélé lẹ́yìn tí àwọn agbébọn kan yawọ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sì tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni àwọn agbébọn kan yawọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Central Pademba Road ní Freetown tó jẹ́ olú ìlú Sierra Leone tí wọ́n sì tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.
Òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fìdí ìròyìn yìí múlẹ̀ fún BBC News.
Ṣaájú ni àwọn agbébọn ọ̀hún ti kọ́kọ́ ṣe ìkọlù sí bárékè àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ tó wà níní ìlú náà.
Àwọn olùgbé bárékè ọ̀hún tó súnmọ́ ilé ìgbé ààrẹ ní àwọn ń gbọ́ ìró ìbọn tó ń dún lákọlákọ.
Èyí lé mú kí ilé iṣẹ́ ètò ìròyìn orílẹ̀ èdè náà kéde òfin kónílé gbélé.
Ìjọba ní kí àwọn ènìyàn dúró ní ilé wọn àti pé gbogbo ọkọ̀ òfurufú tó lè wọ orílẹ̀ èdè náà ni wọ́n ti dá dúrò fún ìgbà kan ná.
Ààrẹ Julius Maada Bio ni àláfíà ti padà sílùú àti pé àwọn ti dá àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sígboro láti ṣàwárí àwọn tó iṣẹ́ láabi náà.
Àmọ́ akọ̀ròyìn BBC, Umaru Fofana, tó ń gbé ní Freetown ní ìlú náà kò ì tíì fararọ rárá.
Ó ní òun kọjá lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ tí wọ́n gbé àwọn ohun ìjà tó lágbára dání tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ ọlọ́pàá àti pé òun tún rí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń kọrin pé àwọn fẹ́ fọ Sierra Leone mọ́.
A kò lè sọ iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sa kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Central Pademba Road ní pàtó àmọ́ ìwádìí Amẹ́ríkà kan lọ́dún 2019 ní àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ọgbà náà lé ní ẹgbẹ̀rún méjì.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn ará ìlú náà tó ń gbé ní agbègbè ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ṣe ń kó ẹrù wọn láti sálọ.
Láti ìgbà tí wọ́n ṣètò ìdìbò lóṣù Kẹfa ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn ti wà ní inú fu àyà fu lẹ́yìn tí wọ́n kéde ààrẹ Bio pé òun ló tún wọlé ìbò fún sáà mìíràn.
Ní oṣù Kẹjọ ọdún 2023 ni wọ́n tún fi àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ kan sí àhámọ́ pé wọ́n ń gbèrò láti dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ ààrẹ Bio.
Orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ mẹ́jọ ni ìdìtẹ̀gbàjọba tí wáyé láìpẹ́ yìí tó fi mọ́ Guinea tó súnmọ́ Sierra Leone.
Amẹ́ríkà, àjọ ìṣọ̀kan Yúróòpù, UK àti ECOWAS ló ti bu ẹnu àtẹ́ lu rògbòdìyàn tó wáyé náà.
Sierra Leone: wo ohun tí àjọ EU Ecowas,US àti ìlẹ́ Gẹ́ẹ̀sì ń sọ nípa rúgúdù tó n wàyé
Iṣẹlẹ to n waye lorileede Sierra Leone ti n mu iriwisi wa lati ọdọ awọn olori ikọ ati orileede agbaye tawọn kan si n pe fun alaafia ki ọrọ naa ma ba kọja agbara.
Lowurọ ọjọ Aiku ni iro ibọn gbalẹ ni ilu Freetown nibudo awọn ologun kan to wa ni agbegbe Wilberforce.
Ibudo yi sunmọ ile igbe aarẹ orileede naa.
Kete ti ọrọ yi bẹrẹ si ni rugbo bọ lawọn ijọba orileede naa kede konileogbele jakejado ilẹ naa.
Aarẹ Julius Maada Bio fi ọrọ soju opo rẹ ni Twitter to si sọ pe awọn ti da alaafia pada ati pe awọn agbofinro ti n tọ pinpin awọn to fẹ fipa wọ ibudo ologun ti wọn ko nkan ija si.
Ka to diju ka to ya, awọn kan ti tu awọn ẹlẹwọn silẹ lọgba ẹwọn to wa ni Central Padema Road lolu ilu Freetown.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ ọgba ẹwọn ilẹ naa fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC.
Ọrọ ti aarẹ Sierra Leone fi soju opo X rẹ ree nipa iṣẹlẹ yi.
Ecowas,EU,US, ati ilẹ Gẹẹsi naa ti da si ọrọ yii
Ninu atẹjade ọtọọtọ ajọ Ecowas to n ṣakoso eto ọrọ aje awọn orileede to wa ni iw oorun Guusu Africa ti da si iṣẹlẹ yi ti wọn si bẹnu atẹ lu ikọlu tawọn kan ṣe lati fipa da omi alaafia orileede naa ru.
Wọn ni awọn ko ni faaye gba igbajọba ti ko ba iwe ofin mu.
Iru ọrọ to jọ mọ eleyi naa lo waye lati ẹnu ajọ EU, olu ileeṣẹ orileede America to wa ni Sierra Leone ati ti ilẹ Gẹẹsi.
Gbogbo wọn lawọn yoo tẹsiwaju iranwọ lati jẹ ki alaafia ati iṣejọba awarawa lorileede naa.
Awọn araalu Freetown lolu ilu Sierra Leone ji lowurọ ọjọ Aiku yi si ariwo iro ibọn kikan kikan.
Iroyin gbode tawọn araalu si n sọ pe awọn n gbọ iro ibọn yi lati o kere tan ibudo awọn ọmọ ogun meji.
Awọn alaṣẹ lorileede naa si ti kede konileogbele jakejado ilẹ ni kiakia.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ iroyin orileede Sierra Leone fi sita, wọn ni awọn eeyan kan lo gbiyanju lati jawọ ibudo ti wọn ko ohun ija si ni bareke kan to wa ni agbegbe Wilberforce.
Atẹjade yi fi kun pe awọn ti kọdi awọn to fẹ yabo ibudo yi.
Awọn ọmọ ogun ti gba igboro kan
Akọroyin BBC to rin kaakiri FreeTown lati mọ bi nkan ti ṣe ri n jabọ pe oun ri awọn ọmọ ogun ti wọn di oju ọna lawọn agbegbe kọọkan.
O ni awọn ọmọ ogun kan to kọja lẹgbẹ oun n pariwo pe ọrọ yi ko kan awọn araalu ati pe ko si wahala ki wọn fọkanbalẹ.
O ni wọn tun sọ pe ''a fẹ ṣe afọmọ Sierra Leone ni, ẹ lọ fọkan balẹ''
O ni ni ibi kan ti wọn n pe ni Congo Cross ti ko jina si ibudo awọn ọmọ ogun, oun ri ti awọn ọmọ ogun tan ọkọ ọlọpaa kan pe ko yida pada ti wọn si da duro lọna.
''Mo ri ti awọn ọmọ ogun yi gbe nkan ija ti wọn fi n yin ado oloro lọwọ. Mi o le ṣalaye nkan to n ṣẹlẹ bayii' tori lati okere lati n yọju wo wọn''
O ni ko si awọn ọmọ ogun pupọ to n ṣọ oju ọna tawọn eeyan n gba lọ si ile ijọba.
A ko le fidi ọrọ mulẹ bayi boya iditẹgbajọba ti n waye tabi ko ri bẹẹ.
Laarin ọdun mẹta sẹyin ọpọ awọn orileede iwọ oorun Afrika lo ti n koju iditẹgbajọba.
Niger ati Mali wa ninu wọn.
Guinea pẹlu wọn laipẹ to si jẹ wi pe lọwọ bayii, o wa labẹ ijọba ologun.