You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kìkọlù Niger jẹ ìgbésẹ̀ tó kẹ́yìn tí ECOWAS yóò gbé - AbdulSalam Abubakar
Olori fun ijiroro lori awuyewuye lorilẹede Niger, ẹni to tun jẹ Olori ijoba ologun tẹlẹri fun orilẹede Naijiria, Ọgagun AbdulSalam Abubakar tí sọ fun BBC pe kikọlu orilẹede Niger pẹlu ọmọ ologun jẹ igbesẹ to kẹyìn ninu igbiyanju lati wa ọna abayọ si rogbodiyan naa.
O ni oun ati awọn igbimọ tí Ajọ ECOWAS da silẹ ti bẹrẹ ijiroro pẹlu Olori ijọba ologun, Ọgagun Abdourahmane Tchiani tí ireti si wa pe dun dun ni ọsan yoo so.
Ọgagun Tchiani kede lọsẹ to kọja pe awọn yoo gbe ijọba silẹ lẹyin ọdun mẹta, eyi ti Ajọ ECOWAS tako.
ECOWAS sọ pe aye sì fun ijiroro sugbọn ikede Ìjọba ologun lati da ijọba pada lẹyin ọdun mẹta ti dori awọn olori orilẹede kodo lori irufẹ esi ti wọn yoo fọ.
Ṣugbọn Ọgagun Abubakar sọ fun BBC pe isẹ ti oun se lọ si Niger ti fi aye silẹ lati yanju ọrọ naa.
"Gbogbo eto ni a gbọdọ seto láti gba ijọba pada kuro lọwọ ologun... Ko nilo fun wa lati lọ si ogun bakan naa ko ẹnikẹni to n gbero lati lọ sogun nitori tí a ba bẹrẹ ogun, ko si ẹni to ibi tí yoo ba ja"
Ọgagun Abubakar tun fi oju gan ni Aarẹ Mohamed Bazoum.
O ni Aarẹ kọminu lori bi awọn ologun ṣe n itọju rẹ.
"A ti fìdí rẹ mulẹ pe wọn yọ ina mọnamọna silẹ lọdọ Aarẹ ti wọn fi si ahamọ.
"Inu Aarẹ ko dun bí awọn ologun ṣe n se si, o ni wọn ti oun mole lai ni idi kankan..
Olori ijọba ologun tẹlẹ naa ni igbesẹ ajọ ECOWAS lati fofin de orilẹede Niger ti da ọpọlọpọ wahala silẹ, to si n ṣe ọpọlọpọ akoba fun orilẹede naa.