Ẹ múra sílẹ̀ fún òjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta pẹ̀lú ìjì líle àti àrá - Nimet

Aworan ara

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ Nimet to n ri si bi oju ọjọ ṣe ri ni Naijiria ti kede pe ojo ọlọjọ mẹta yoo rọ pẹlu iji lile ati ara bẹrẹ lati ọjọ Aje ọsẹ yii.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita lọjọ Aiku ọjọ kẹtala oṣu yii ni wọn ti sọ pe ojo iji lile n bọ pẹlu ara lawọn apa ibikan ni Naijiria nigba ti oorun yoo si jade lawọn ibomiran.

Ajọ naa ni o ṣee ṣe ki ara san lọsan an lasiko ti ojo ba n rọ tabi lalẹ lawọn ipinlẹ bii Adamawa, Taraba ati ipinlẹ Kaduna.

Laarin gbungbun ẹkun ariwa Naijiria, ajọ Nimet ni kurukuru yoo wa loju ọrun, o si ṣee ṣe ki ara san ki iji lile si fẹ nipinlẹ Plateau, Abuja, Niger, Nasarawa, Kwara, Kogi ati nipinlẹ Benue lọsan an tabi lọwọ alẹ.

Nimet ni kawọn eeyan to wa lẹkun guusu Naijiria maa reti ojo tori o ṣee ṣe ki ara san laarọ lawọn apa ibikan nipinlẹ Cross River ati Akwa Ibom.

Ajọ naa sọ pe kawọn eeyan to n gbe lawọn ipinlẹ to wa lẹkun guusu yoku naa mura silẹ fun ara ati iji lile lọwọ alẹ.

Ni ọjọ Iṣẹgun, ajọ Nimet ni oorun yoo jade lọpọ agbegbe ni ẹkun ariwa Naijiria, amọ, o ṣee ṣe ki ara san lasiko ti ojo ba n rọ ni ipinlẹ Kaduna, Taraba ati Adamawa lọsan tabi lalẹ.

Ajọ Nimet ni oorun yoo jade lẹkun aarin gbungbun apa ariwa, ṣugbọn awọn eeyan ipinlẹ Kogi, Nasarawa, Plateau, Benue ati Abuja gbọdọ mura silẹ fun iji lile ati ara.

Iji lile yoo fẹ pẹlu ara laarọ nipinlẹ Akwa Ibom, Bayelsa, Rivers ati Cross River.

Amọ, lọsan an ni kawọn eeyan maa reti iji lile ati ara lọpọ agbegbe ẹkun guusu.

Ni Ọjọru, Nimet ni oorun yoo ran lawọn apa ibikan lẹkun ariwa ṣugbọn o ṣee ṣe ki iji lile fẹ ki ara si san ni ipinlẹ Sokoto, Kebbi, Kaduna, Taraba ati Adamawa lọsan an tabi ni irọlẹ.

Ajọ Nimet sọ pe kawọn eeyan ipinlẹ Delta, Rivers, Cross River ati Akwa Ibom maa reti iji lile ati ara l'Ọjọru.

Ojo pẹlu iji lile ati ara n bọ lawọn apa ibikan l'Ọjọru lẹkun guusu Naijiria

Ajọ Nimet sọ pe ojo pẹlu iji lile ati ara n bọ lawọn apa ibikan l'Ọjọru lẹkun guusu Naijiria

Ajọ Nimet ko ṣai kilọ pe awọn ipinlẹ kan yoo si gbona kaakiri orilẹede Naijiria eyi ti yoo jẹ ki ooru mu ọpọ eeyan.

Ajọ naa rọ awọn araalu lati duro sibi ti boogi ba wa ki wọn si mu omi daadaa, ati pe ki wọn ma rin ninu oorun ni nnkan bii ago mẹta ọsan.

Bakan naa ni ajọ Nimet rọ awọn eeyan lati fọwọ wọn, ki wọn si yago fun ibi tawọn ero ba ti pejọ.

Ajọ Nimet ko ṣai ṣe ikilọ pe kawọn araalu lo ibomu wọn ki wọn maa ba ko arun kan tabi omiran.

Lakotan, ajọ Nimet rọ awọn to n wa ọkọ ofurufu lati beere bi oju ọjọ ṣe ri ki wọn to fo loke.