You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló dé tí Ààrẹ Tinubu kò fi bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ ní àyájọ́ June 12, àti bí ìwọ́de June 12 ṣe lọ́ sí?
Ṣaaju ọdun yii, ni gbogbo igba ti ayajọ ijọba awarawa ba n waye ni Naijiria, yala nigba to ṣi wa ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ni tabi igba ti wọn sun un si ọjọ kejila oṣu kẹfa, ọrọ ti aarẹ fẹ ba awn ọm NAijiria sọ jẹ ọkan gboogi lati awọn eto ayẹyẹ naa.
amọṣa ki lo yi eyi pada lọdun 2025?
ni ọjọ kọkan la oṣu kẹfa ni atẹjade jade pe aarẹ Naijiria ko ni le ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni owurọ ọjọbọ tii ṣe ayajọ ijọba tiwantiwa ni NAijiria. eredi ti wọn la kalẹ ni pe dipo eyi, aarẹ yoo lọ ba apapọ igbimọ ile aṣofin apapọ Naijiria sọrọ ni.
Bawo ni ayajọ ọjọ June 12 ṣe wa lọ kaakiri Naijiria?
Naijiria, orilẹede ilẹ adulawọ to ni ọpọ ero ninu n ṣe ayajọ ijọba awarawa pelu ohun to waye ni Ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 1993, eto idibo ti ọpọ ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi ti ko ni magomago ninu lorilẹede Naijiria.
Pẹlu bo ti jẹ pe wọn wọgile eto idibo naa, ohun to waye ni June 12 fa ọpọ rogbodiyan titi wọ akoko yii.
Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lo mu ayipada ba ọjọ ti ayajọ ijọba awarawa ma n waye lati ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Karun un to jẹ ọjọ ti ijọba Ologun gbe agbara fun ijọba alagbada si Ọjọ kejila oṣu Kẹfa lati bu ọla fun Moshood Abiola to bori eto idibo aarẹ ọdun 1993.
O ti to ọdun mẹrindinlọgbọn bayii ti orilẹede Naijiria Ii n ṣe ijọba awarawa lai si idasi lati ileeṣẹ Ologun.
Ẹwẹ, ayẹyẹ ti ọpọ n lọ bayii ko ju lati ṣe ifẹnonuhan kaakiri orilẹede Naijiria.
Awọn to n ṣe agbatẹru iwọde yii ni awọn n ṣe bẹẹ lati tako ijọba lori iniran ti araalu n koju labẹ iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu.
O kere ju, iwọde yoo waye ni ipinlẹ Ogun, ti awọn ipinlẹ bii Oyo, Ondo ati Akure si ti bẹrẹ iwọde bayii.
Iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu tig be ọpọ igbesẹ bi yiyọ owo iranwọ epo ati ofin mii to fa ki ọwọngogo gbode lorilẹede Naijiria.
Niluu Ibadan, iwọde ayajọ ijọba awarawa n lọ lọwọ, ṣugbọn iwọde naa ko fi bẹẹ fi ẹsẹ mulẹ nitori eeyan perete lo jade sita lati fi ẹhonu han.
Ninu atẹjade ti awọn to ṣe agbatẹru iwọde naa fi ṣọwọ si awọn oniroyin saaju asiko yii, alaye ti wọn ṣe ni pe aago mẹjọ owurọ ni iwọde naa yoo bẹrọ ni agbegbe Mọkọla Roundabout, ṣugbọn a ko ri ẹnikẹni to fi ara han ni agbegbe naa titi di aago mọkan owurọ ku iṣẹju meje.
Ọna ibomii ni awọn eeyan perete to jade fun iwọde naa gba lọ, bẹrẹ lati opopona Sabo lọ si Dugbe ki wọn to morile ọna Oke Ado.
Bi wọn ṣe n wọde lọ naa ni awọn agbofinro n mojuto iṣiṣẹ wọn.
Akọroyin wa jabọ wi pe awọn agbofinro gan pọ ju awọn eeyan to n ṣe iwọde lọ.
Àwọn agbègbè tí ìwọ́de June 12 yóò ti wáyé rèé àti bó ṣe kàn ọ́
Ajọ Take It Back Movement, to n ṣagbatẹru iwọde June 12 ti kede awọn gbegbe ti iwọde naa yoo ti waye kaakiri Naijiria lọdun yii.
Ọla ọjọ Kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 ni iwọde June yoo tun waye ni iranti MKO Abiola to jawe olubori ninu idiboAarẹ June 12, ọdun 1993.
Iwọde naa ni wọn ni yoo waye lati fi erongba wọn han ijọba apapọ latari ọwọngogo to gbode ati bi nnkan ṣe le koko ni Naijiria.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin, adari ajọ Take It Back Movement, Juwon Sanyaolu sọ pe ojuko bii ogun ni iwọde naa yoo ti waye kaakiri Naijiria.
Awọn agbegbe wọnyii ni iwọde naa yoo ti waye kaakiri Naijiria
Niluu Abuja, Juwon Sanyaolu sọ pe gbagede Eagle Square ni awọn oluwọde yoo korajọ si laago mẹjọ aarọ.
O ni, niluu Akurẹ, awọn yoo korajọ siwaju Cathedral Junction, ni Benin to jẹ olu ilu ipinlẹ Edo, Museum Ground ni wọn yoo ti pade laago mẹsan an aarọ nigba ti wọn yoo pade ni Gida Matasa nipinlẹ Niger.
Sanyaolu fi kun pe "Ni Yobe a maa pade ni Maiduguri Bypass Roundabout niluu Damaturu laagọ meje abọ aarọ.
"Nipinlẹ Oyo, a o pade ni Mokola Roundabout laago mẹjọ aarọ. Ni Bauchi, a o pade ni Bauchi School of ACR to wa ni Yelewam Makaranta, nigba ti a o pade ni orita Olaiya niluu Osogbo."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, agbegbe marun un ọtọtọ ni wọn yoo ti pade ni ipinlẹ Delta. Ni Adamawa o ni wọn yoo korajọ loju ọna Juppu Jam to wa niluu Yola; ni Borno, wọn yo pade labẹ afara Kasuwan Gamboru.
Eredi iwọde June 12 ọdun yii
Sanyaolu ṣalaye pe eredi iwọde naa ko ṣẹ yin bi nnkan ṣe le koko faraalu ni Naijiria lọwọ yii.
O mẹnuba atẹjade ajọ Amnesty International kan to sọ pe ẹgbẹrun mẹwaa ọmọ Naijiria lo ti padanu ẹmi wọn nitori eto abo to mẹhẹ labẹ iṣejọba Bola Tinubu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o le lọgọrun miliọnu eeyan to n jẹ ọpalamba iya ninu ijọba yii, akoko si ti to fun awọn araalu lati gba orilẹede wọn pada lọwọ awọn to fẹ run un.
O ni ẹtọ araalu ni lati ṣe ifẹhonuhan labẹ ofin, lẹyin naa lo kilọ fun awọn agbofinro ki wọn ma ṣe fiya jẹ eyikeyi ninu awọn olufẹhonuhan, kaka bẹẹ, o ni ṣe lo yẹ ki ọlọpaa atawọn agbofinro mii daabo bo awọn oluwọde ọhun.
Ki ni ojuṣe rẹ?
Gẹgẹ bii ọmọ Naijiria ẹtọ rẹ ni labẹ ofin lati kopa ninu iwọde ki ọlọpaa si daabo bo ọ.
Amọ ṣa, o ṣeeṣe ki wahala bẹ silẹ laarin awọn ọlọpaa lasiko iwọde ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe maa n waye tẹlẹ.
Fun apẹrẹ, ọpọ igba ni ọlọpaa ti fi ṣikun ofin mu awọn oluwọde lai ni idi, nigba mii ẹwẹ, awọn kọlọrọsi kan maa n darapọ mọ awọn oluwọde lati da ilu ru.
Lẹyin iṣẹlẹ ifẹmisofo to waye ni iloro Lekki Toll Gate lasiko iwode EndSARS ọdun 2020 ni awọn ọlọpaa ko ti fẹ maa gba ifẹhonuhan aaye mọ lẹyin ti awọn eeyan ba ọpọ dukia jẹ lọdun naa lọhun.
Bo tilẹ jẹ pe illeeṣẹ ọlọpaa ko tii sọ nnkankan nipa iwọde ti wọn n mura rẹ lọwọ yii, o ti maa n sọ ṣaaju pe ko tọ ki awọn kan maa fi iwọde tiwọn di awọn mii to n lọ soju ọna ounjẹ oojọ wọn lọwọ.
Ọlọpaa tun ti sọ ṣaaju ri pe ko ni si aye fun awọn oluwọde ti ko ba kọkọ gba ontẹ ijọba lati ṣewọde ki wọn ma baa ba dukia ilu jẹ.
Ẹwẹ, ọpọ igba ni awọn oluwọde maa n kede ojuko ti wọn ti fẹ ṣe iwọde amọ ti wọn yoo lo ibomiran.
Wọn maa n ṣe eyii lọna ati bọ lọwọ awọn ọlọpaa to maa n duro lati mu wọn ni ojuko ti wọn ti kọkọ kede ṣaaju fun irufẹ iwọde bẹẹ.
Wayi o, o san ki o joko sile rẹ ti o ko ba ni ibi kankan lati lọ lasiko iwọde ti o ko si nifẹ lati darapọ mọ iwọde ọhun.
Amọ ti o ba ni ibi lati lọ bii ibiṣẹ oojọ rẹ tabi ibomii to ṣe pataki, o san lati yẹra fun awọn agbegbe ti iwọde yoo ti waye latari idiwọ tabi sunkẹrẹ-fakẹrẹ to le waye lawọn agbegbe bẹẹ.