Àwọn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé nílẹ̀ adúláwọ̀ ni 2023

Awon awọn ọmọgun ilẹ Faranse ti wọn kuro ni Niger lẹyin iditẹgbajọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iditẹgbajọba ni awọn onimọ juwe bii lilo agbara, wahala ati ọna ti ko bofin mu lati gba iṣakoso lọwọ ijọba to gba oreọfẹ ofin, ti gbogbo araalu si da mọ.

Ni igba miran, eleyi a maa la ọpọlọpọ ẹmi lọ, paapaajulọ awọn to n ṣejọba ti awọn kan fẹẹ le kuro.

Ni ọpọ igba, awọn ọmọ ajọ ologun lo maa n hu iru iwa yii lati fi le olori ologun kan kuro lori aleefa abi lati gabjọba lọwọ olori tawọn araalu yan sipo.

Lati ọjo pipẹ ni iditẹgbajọba ti maa n waye.

Iditẹgbajọba akọkọ taa ri ninu akọọlẹ lagbaye ni lo waye ni ọrinlelẹgbẹrin ọdun o le mẹfa ṣaaju ki wọn too bi Jesu, to si waye ni Israel nigba ti Zimri pa Ọba Elah to si fi ara rẹ jẹ Ọba.

Igba akọkọ ti iditẹgbajọba waye nilẹ Afirika ni ọjọ kẹtala, oṣu kini, ọdun 1963 lorilẹede Togo nigba ti awọn ologun kan, to fi mọ Kléber Dadjo ati Gnassingbé Eyadéma, gba iṣakoso iṣejọba ti wọn si ṣekupa Sylvanus Olympio to jẹ aarẹ ilẹ naa.

Lati igba yii wa ni oriṣiriṣi iditẹgbajọba ti n waye nilẹ Adulawọ.

Iditẹgbajọba akọkọ ni Afirika lọdun 2023

Aworan awọnọmọ orilẹede Niger to n wọde lati ṣatilẹyin fawọn to ditẹgbajọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ala lo ri ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2023 ti iroyin gbode pe awọn kan ti ditẹgbajọba lorilẹede Niger.

Awọn kan tilẹ kọkọ wi pe irọ ni, tawọn kan naa si wi pe wọn kan gbiyanju rẹ ni amọ ko bọ sii.

Ẹwẹ, lẹyin wakati bii meji lawọn ileeṣẹ iroyin bẹrẹ si nii fidi rẹ mulẹ pe ni tootọ ni iditẹgbajọba naa waye.

Olori awọn ẹṣọ aarẹ, Ọgagun Abdourahamane Tchiani, lo kede ara rẹ gẹgẹ bii adari orilẹede naa, to si wi pe Aarẹ Mohamed Bazoum ni wọn ti fi si ihamọ.

Iditegbajọba yii ni ikarun iru rẹ lorilẹede Niger lẹyin to ti kọkọ waye nibẹ lọdun 1974.

Awọn onwoye ọrọ lawujọ wi pe igbe aye ti ko rọrun lorilẹede naa lo ṣokunfa idigbajọba ọhun, leyi to mu ki awọn araalu o maa ṣajọyọ kaakiri ilu leyin ti wọn gbọ iroyin naa.

Iditẹgbajọba tun waye lorilẹede Gabon

Aworan awọn araalu to n ṣajọyọ pe ologun gbajọba ni Gabon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kete ti ajọ eleto idibo orilẹede Gabon kede Aarẹ Ali Bongo gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori fun saa kẹta ninu idibo aarẹ ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹjọ, ni awọn ologun kan ninu awọn ẹṣọ aarẹ nilẹ naa fi Bongo satimọle ninu aafin rẹ.

Ko pẹ si akoko yii ni wọn kede Ọgagun Oligui Nguema bii ẹni ti yoo dari igbimọ awọn ologun ti yoo ṣeto bi wọn yoo ṣe da ijọba pada fawọn oloṣelu.

Awọn ọdọ orilẹede ni wọn ya wọ igboro lati maa ṣajọyọ iyọnipo Aarẹ Bazoum gẹgẹ bi a ṣe rii lori ẹrọ ayeluja ti Bazoum ti wọgi le ṣaaju ki eto idibo o too bẹrẹ lọjọ diẹ sẹyin.

Ohun to waa ṣe awọn eeyan ni kayeefi ni pe Bazoum to fofin de lilo awọn ikanni ayelujara lorilẹede naa le maa rawọ ẹbẹ sawọn to pe ni “awọn ọrẹ mi jakejado agbaye” lori ikanni ayelujara lati ibi ti wọn tii mọ pe ki wọn maa pariwo ki wọn lee yi iditẹgbajọba naa pada.

Ṣaaju iditẹgbajọba naa, Aarẹ Bongo ni idile rẹ ti n ṣejọba Gabon fun ọdun mẹrindinlọgọta.

Omar Bongo, to jẹ baba Ali, lo di aarẹ Gabon lọdun 1967, to wa si lori aleefa titi to fi papoda lọdun 2009, ti ọmọ rẹ si gbajọba lẹyin iku rẹ.

Awọn igbiyanju iditẹgbajọba ti ko yọri.

Burkina Faso

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun 2023, ni ijọba ologun to wa lori aleefa lorilẹede Burkina Faso wipe awọn dena igbiyanju iditẹgbajọba kan lorilẹede naa.

Olori ijọba ologun nilẹ naa, Ibrahim Traore lo ditẹ gba ijọba lọwọ Paul-Henri Sandaogo Damiba, ti oun funra rẹ ditẹgbajọba ni oṣu mẹjọ ṣaaju akoko naa.

Sierra Leone

Freetown, to jẹ olu-ilu orilẹede Sierra Leone, in iro ibọn ji awọn olugbe ibẹ laarọ kutu ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2023.

Ohun taa gbọ lẹyin eyi ni pe awọn ologun kan n gbiyanju lati wọ ile kan ti wọn ko awọn ohun ija ogun pamọ si lẹgbẹ ile aarẹ ilẹ naa, ti wọn si nii lọkan lati lọọ tu awọn kam silẹ lọgba ẹwọn meji ọtọọtọ lẹyin eyi.

Gẹgẹ bi ajọ ologun ilẹ naa ṣe fi lede, o kere tan, eeyan mọkandinlogun, ti ologun mẹtala wa ninu wọn, lo padanu ẹmi wọn lasiko akọlu naa ti wọn juwe bii igbiyanju iditẹgbajọba.