Bíṣọ́ọ̀bù àti olóyè ìjọ rí ẹ̀wọ̀n he lórí àparútu nílé ìjọsìn

Ileẹjọ giga nipinlẹ Ekiti to n joko niluu Ado Ekiti ti ran Bisọọbu agba Adereti Ebenezer ati Oloye ijọ, Akinyede Joseph lọ si ẹwọn ọdun mẹta.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn ojisẹ Ọlọrun mejeeji naa ni pe wọn lẹdi apo papọ lati ṣe mọdaru iwe ile ẹgbẹ kan nile ijọsin naa lati paarọ rẹ si tawọn ọmọ ẹgbẹ.

Awọn afurasi ọhun ti kọkọ fi oju ba ileẹjọ niwaju adajọ Lekan Ogunmoye lọjọ kejidinlogun, osu kẹwaa ọdun 2021.

Iwe ipẹjọ naa ni Oloye Akinyede Joseph, ẹni ọdun mejidinlaadọrin ati Bisọọbu Adereti Ebenezer, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, lọjọ kẹwaa, oṣu kinni ọdun 2016 ni agbegbe Ilado, Iwore, Ifaki Ekiti sisẹ pọ lati yi iwe ipade ẹgbẹ ile jọsin United Church of Cherubim ati Seraphim.

Bakan naa lo ni wọn kede ara wọn gẹgẹ ara ẹgbẹ ọhun, ti wọn si yi ile ofin ẹgbẹ naa pada ni ọna ti ko ba ofin .

Gẹgẹ bii agbẹjọro awọn olupẹjọ ṣe sọ, ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ọhun lo lodi sofin orilẹede Najiria ati ipinlẹ Ekiti.

Ninu atẹjade to fi ransẹ si ileeṣẹ ọlọpaa, ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Faseyi Albert ni, wọn yan oun ati awọn miran gẹgẹ bii aṣoju ẹgbẹ ile ijọsin naa lọdun 2001, ti wọn si fi iwe naa ransẹ si ijọba lati fi ontẹ lu.

“Lẹyin ipapoda olori ile ijọsin yii, Bisọọbu S.A Fadeyi, awọn igbimọ bisọọbu yan Bisọọbu Tunde Ogunseemi gẹgẹ bi olori tuntun lọdun 2015.

“Nigba ti a bẹrẹ iwadi lori iwe ofin ẹgbẹ naa, ni a ri pe Bisọọbu Adereti Ebenezer, to jẹ Bisọọbu kẹta nile ijọsin ọhun ati Oloye Akinyede Joseph, ti fi ọwọ ba iwe ofin ọhun .

Awọn eeyan yii si ti kọ sinu iwe naa pe ẹgbẹ ti yọọ orukọ Bisọọbu Tunde Ogunseemi kuro, to fi mọ iye isẹju ti wọn yoo maa fi se ipade ati awọn nnkan miiran.

Ki ni Adajọ sọ?

Awọn afurasi to gba ẹnu agbẹjọro wọn, Ayotunde Ibitoye, bẹ ileẹjọ lati fi oju aanu wo awọn.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Lekan Ogunmoye ni pẹlu awọn ẹri to wa niwaju ileẹjọ, o fi han gbangba pe awọn afurasi ṣe papọ lati ṣe mọdaru.

O wa palasẹ pe awọn afurasi naa lọ lo ọdun kankan lọgba ẹwọn pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun naira .