Èmi kọ̀ ló pa ọkọ mí; ohun tí mo mọ̀ tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó kú rèé- Wumi, aya Mohbad

O to wakati mẹta ti Iyawo Mohbad, Wunmi Alọba, fi ṣalaye ohun to mọ nipa iṣẹlẹ to fa iku ọkọ rẹ, Ileri Oluwa Alọba tawọn eeyan mọ si Mohbad, iyẹn nibi ti wọn ti n gbọ ẹjọ iwadii iku oloogbe naa nipinlẹ Eko, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Ọkọ mi ati ọrẹ ẹ ja n’Ikorodu loootọ, o fi ara pa, ara rẹ ko balẹ mọ lẹyin ti nọọsi fun un labẹrẹ, iku ni mo gbọ lẹyin iyẹn

Wunmi ṣalaye pe ija kan waye laarin ọkọ oun ati ọrẹ ẹ, Prime Boy, lẹyin ti Mohbad pari ere n’Ikorodu lalẹ ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan-an, tawọn fẹe maa lọ sile ṣugbọn ti awọn ololufẹ rẹ ko jẹ ki awọn ri ọna gba.

O ni aburo Mohbad, Adura Alọba, to fẹẹ lọọ pe awọn ti yoo le awọn ero to wa lọna kuro pẹ ko too de, eyi si dohun ti Prime Boy binu si aburo Mohbad tiyẹn naa si da a lohun pada.

Ọro naa lo ni o dija laarin Mohbad ati Prime Boy, ti Oloogbe fi ṣilẹkun mọto rẹ to si ni ki Prime Boy sọkalẹ.

Wumi sọ pe oun ko mọ ohun to pada ṣẹlẹ mọ nitori oun ti kuro nibẹ lati pe awọn eeyan pe ki wọn waa da si i, nigba toun de loun ri i pe Mohbad ti fi ọwọ ṣeṣẹ

O fi kun un pe Mohbad ko lọ sọsibitu boun ṣe gba a nimọran lọjọ keji to fi ọwọ ṣẹṣe nibi ija naa, oun ba a fi nnkan pa a.

Ọrẹ rẹ, Spending, to n gbe pẹlu awọn lo si ba a pe nọosi to fun un labẹrẹ naa.

Nitori nọọsi to maa n tọju Mohbad ko si nitosi.

Ilé-ẹjọ́ dá Nọ́ọ̀sì tó gún Mohbad lábẹ́rẹ́ àti ọ̀rẹ́ Olóògbé padà sí àhámọ́

Ile-ẹjọ Majistreeti to fikalẹ si Yaba nipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe ki nọọsi to gun gbajumọ olorin sufee-taka nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba (Mohbad) labẹrẹ, iyẹn Fisayọ Ogedengbe ati ọrẹ Mohbad, Ayọbami Sadiq, pada si ahamọ. Kootu ko faaye beeli silẹ fun wọn.

Ọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe Mọnde ni Adajọ Adeọla Ọlatunbọsun, paṣẹ pe ki Nọọsi Fisayọ, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) pada si atimọle ti wọn ti gbe e wa si kootu lati jẹwjọ. Bakan naa lo ni ki Ayọbami toun naa jẹ ọrẹ Oloogbe ati afurasi lori iku Mohbad yii ṣi lọọ maa naju lahaamọ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Mọnde yii naa ni Azeez Fashọla tawọn eeyan mọ si Naira Marley ati Samson Balogun Eletu ( Sam Larry) ri anfaani beeli pẹlu miliọnu lọna ogun naira, eyi tile-ẹjọ sọ pe awọn yoo faaye oniduuro silẹ fun wọn bi wọn ba ti yanju eto beeli ọhun.

Ṣugbọn ni ti nọọsi ti wọn ni abẹrẹ rẹ lo fa iku Mohbad yii, pẹlu ọrẹ ọmọkunrin naa, Ayọbami, Adajọ ko faaye oniduuro silẹ rara.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹjọ naa bawọn ọlọpaa ṣe wi.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla yii ni igbẹjọ mi-in yoo tun waye, gẹgẹ bi Adajọ Ọlatunbọsun ṣe sun un siwaju fun amọran lati ọdọ awọn DPP to n gba kootu nimọran.