Láti le jẹ́ kí ó wà láàyè, wọn ti gé ẹsẹ̀ Mr Ibu kan- Mọ̀lẹ́bí

Awọn mọlẹbi gbajugbaja oṣere tiata lorilẹede Naijiria, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr Ibu kede pe oṣere naa ti padanu ẹsẹ rẹ kan lori igbiyanju wọn lati mu nwa layẹ.

Mr Ibu lo ti wa ni ile iwosan lati ọsẹ dọe bayii ti ọpọ ọmọ Naijiria si ti pese ranlọwọ ti apa wọn kan lẹyin ti agba oṣere naa bọ sita lati tọrọ iranlọwọ lori ayelujara.

Ninu atẹjade ti mọlẹbi fi soju opo ayẹlujara Mr Ibu, salaye pe Mr Ibu ti ṣe isẹ abẹ meje sugbọn lati ri pe o wa laaye, wọn ni lati ge ọkan lara ẹsẹ rẹ.

“O nira fun wa lati gba sugbọn lati le mu wa laaye, a ni lati tẹwọgba ipò baba wa bayii.

“Lẹyin isẹ abẹ meje, wọn lati ge ẹsẹ Baba wa kan.”

Mọlẹbi wa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijria to dide iranlọwọ si lati igba ti John Okafor i wa lori idubulẹ aisan ni ile iwisan.

Ki lo waye saaju?

Mr Ibu lo ti pariwo sita lori bẹẹdi ile iwosan to wa pe ki awọn eeyan, paapaa awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn jẹ ololufẹ oun dide iranlọwọ fun oun, latari aisan kan to da a gunlẹ.

Oṣere naa, ẹni ọdun mejilelọgọta naa lo pariwo yii sita lẹyin ti apa kun un pẹlu bi o ti na owo pupọ sori aisan ọhun.

Ninu fọnran ti o gbe jade loju opo ayelujara Instagram rẹ lo ti ni adura ati iranlọwọ loun nilo bayii, ki wọn mọ ba ge ẹsẹ oun, nitori pe ko si ibi toun tun fẹẹ gba mọ.

Mr Ibu sọ lori ibusun aisan to wa pe "bi ẹ ṣe n wo mi yii, mo ti wa lori idubulẹ aisan fun ọpọlọpọ ọsẹ bayii, ohun ti mo n reti lati ọdọ yin ni adura ati iranlọwọ yin.

Mo ṣi wa ni ọsibitu bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii.

Alakoso eto ilera ni ọsibitu ti mo wa yii ba mi sọrọ, o si jẹ ki n mọ pe bi gbogbo ọgbọn toun n da lori aisan mi ko b ṣiṣẹ, ohun ti yoo dara ni lati ge ẹsẹ mi.

Ẹ kan wo mi bi mo ṣe wa yii, bi wọn ba ge ẹsẹ mi, nibo ni mo fẹẹ lọ bayii?

Ẹ jọwọ, ẹ gbadura fun mi, ẹ ba mi ba Ọlọrun alagbara sọrọ, nitori pe mi o fẹ ki wọn ge ẹsẹ mi.

Ẹ ṣeun mo dupẹ. Ọlọrun a bukun fun yn yin."