You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ Davido àti Chioma ṣe bẹ̀rẹ̀, tí wọn fi bí Ifeanyi?
Ta ni Davido àti Chioma, tí wọn bí Ifeanyi tó jáde láyé
Ile ẹkọ fasiti Babcock University ni gbajugbaja akọrin takasufe nni, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Davido ti kawe gboye imọ ijinlẹ akọkọ.
Ileẹkọ fasiti naa si ni Chioma Avril Roland naa lọ lati kẹkọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ.
Nibẹ si ni Davido ati Chioma ti pade ara wọn, ti wọn fi bẹrẹ si ni jade bii ọrẹkunrin ati ọrẹbinrin.
Ọmọ bibi ẹya Igbo ni Chioma amọ ọmọ bibi ilẹ Yoruba lati ipinlẹ Osun ni Davido
Lasiko ti Chioma n se ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtalelogun lọdun 2019, ni iroyin oun ati Davido gba ori ayelujara kan.
Davido se awo orin Assurance fun Chioma lati fi idaniloju ifẹ rẹ han
Asiko yii si ni Davido gbe awo orin kan jade to pe ni ‘Assurance’ nibi to ti fi ọkọ bọginni kan ta ọmọbinrin naa lọrẹ bii ẹbun ifẹ.
Orukọ to sọ ọkọ naa ni ‘Assurance’ eyi to tumọ si idaniloju.
Ọpọ ọdọmọbinrin lo n tara poro nipa ifẹ awọn mejeeji, ti wn si n fi iru ọkunrin bii Davido tọrọ pe ki ọba oke fi jinki awọn.
Awọn obinrin naa lo n bẹbẹ pe ki awọn ri iru Davido ti yoo fi ọkọ olowo iyebiye sikẹ awọn naa.
Asiko yii si ni ariwo Assurance gbalẹ kan laarin awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin pẹlu.
Lẹyin bii osu diẹ lẹyin ayẹyẹ ọjọ ibi naa si ni ariwo tun gbalẹ kan pe Chioma ti loyun fun Davido, ti ọpọ eeyan si n ba dun
nu.
Ko pẹ, ko jinna ni awọn mejeeji se ayẹyẹ mọ mi-n mọ ọ laarin ẹbi wọn wọn mejeeji, ti wọn si n gbe pọ bii tọkọ taya.
Bi o tilẹ jẹ pe ariwo gbalẹ kan pe wọn fẹ se igbeyawo amọ eyi ko waye rara titi di akoko yii.
Alaye ree lori bi wọn se bi Ifeanyi, ọmọ Chioma ati Davido to ku
Lẹyin osu mẹsan, Chioma bi ọmọkunrin lanti lanti kan, ti wọn si pe orukọ rẹ ni Ifeanyichukwu David Adedeji Adeleke Jnr.
Ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2019 ni Ifeanyi dele aye, ilẹ United Kingdom si ni wọn bi si.
Ifeanyi si wa lara awọn ọmọ gbajumọ ti aye n yọnu si julọ lorilẹede Naijiria lati ọjọ ti wọn ti bi.
Bi ọmọdekunrin naa tilẹ jẹ akọbi fun Chioma amọ oun ni ọmọ kẹta fun Davido.
Idi ni pe awọn obinrin meji miran ti bi ọmọ fun gbajumọ akọrin takansufe naa saaju ki Chioma to bi Davido.
Orukọ awọn ọmọ Davido meji saaju Ifeanyi ni Imade Aurora Adeleke tii se ọmọ ọdun meje ati Hailey David Adeleke tii se ọmọ ọdun marun.
Amọ o se ni laanu pe Ifeanyi ni ọmọ Davido to kọkọ jade laye ni ọjọ Aje, ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹwa ọdun 2022.
Ọmọ ọdun mẹta ni ọmọ naa nigba to ku sinu odo ti wọn ti n luwẹẹ to wa lẹyin ile wọn ni agbegbe Banana Island nilu Eko.
Ta ni David Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si Davido?
Ọmọbibi ilu Ede nipinlẹ Osun ni David Adeleke, ta tun mọ si Davido.
Ọjọ Kọkanlelogun osu Kọkanla ọdun 1992 si lo dele aye lati ipasẹ baba rẹ, Adedeji Adeleke amọ iya rẹ ti jade laye.
Isẹ orin kikọ ni lo yan laayo, gbajumọ akọrin takansufe si ni Davido lorilẹede Naijiria ati lawujọ agbaye lapapọ.
Ọdun 2010 si lo bẹrẹ isẹ orin kikọ, eyiun ọdun mejila sẹyin.
Lara awọn orin rẹ to gbajugbaja julọ ni ‘Ẹ ma da mi duro, emi lọmọ baba olowo ati orin Assurance to fi sọri Chioma.
Davido ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ orin kikọ labẹle ati loke okun.
Ta ni Chioma Avril Roland?
Ọjọ kinni, osu Karun ọdun 1995 ni wọn bi Chioma Avril Roland nilu Owerri nipinlẹ Imo.
Asiko to wa nile ẹkọ fasiti Babcock ni o bẹrẹ ifẹ pẹlu Davido, to si di gbajumọ lorilẹede Naijiria.
Akọsẹmọsẹ ase ounjẹ ni Chioma, to si bi Ifeanyi to jade laye fun Davido.
Davido àti Chioma pàdánú ọmọ ọdún mẹ́ta wọn!
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ati afẹṣọna rẹ ti padanu ọmọ wọn ọkunrin, Ifeanyi Adeleke.
Ọmọkunrin to ṣẹṣẹ pe ọdun mẹta ni Ọgunjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2022 ni iroyin o ku lẹyin to ri sinu omi.
Iṣẹlẹ naa ni wọn ni pe o waye ni ile wọn ni Banana Island, ni ipinlẹ Eko.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa.
Hundeyin n ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ni inu ile wọn lo fi iroyin naa to ọlọpaa leti ni nkan bi aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Ọjọ kọkanlelọgbọn, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
O ni awọn mẹjọ ni wọn wa ni panpẹ ọlọpaa lọwọlọwọ lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo fikun un pe Davido ati Chioma naa wa si agọ ọlọpaa.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ni oku ọmọ naa wa ni ile igbokusi Iroyin ni o pẹ diẹ ki wọn to ri ọmọ naa ninu omi ni Ọjọ Aje, Ọjọ kọkanlelọgbọn, Oṣu Kẹwaa
Ohun ti awọn eniyan n sọ nipa iṣẹlẹ naa
Awọn iroyin miran ni lẹyin ti wọn ri ọmọ naa ni wọn gbe digba-digba lọ si ile iwosan Evercare Hospital, ki dokita to kede pe ọmọ naa ti ku.
Davido ati ololufẹ rẹ Chioma ni iroyin gbe pe wọn lọ si ibi aṣeyẹ kan ni ilu Ibadan, ti wọn si fi ọmọ naa si ile pẹlu awọn alagbatọ rẹ.
Amọ ohun ti wọn sọ nipe wọn ko mọ bi ọmọ naa ṣe wọ inu omi naa to si ri si ibẹ.
Iroyin fikun un pe wọn ti fi panpẹ ọlọpaa mu awọn ti wọn wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Awọn ilumọọka fi ọrọ ikẹdun ranṣẹ si Davido ati Chioma
Ọpọlọpọ awọn ilumọọka lo ti n fi ọrọ ibanikẹdun wọn ranṣẹ si Davido ati Chioma lati ba wọn kẹdun.
Awọn ẹlomiran fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ naa, ti wọn si ni ki wọn fi panpẹ ọba mu awọn to n ṣe itọju ọmọ.
Oṣerebinrin ni Nollywood, Iyabo Ojo fi ibanikẹdun rẹ sita pẹlu igbe pe iroyin naa ba oun ni inu jẹ pupọ, to si ni ohun lero pe iroyin naa ko ni jẹ otitọ.
Gbajugbaja oṣere miran, Muyiwa Ademọla ninu ọrọ tirẹ ni a ko lee dakẹ lori iṣẹlẹ naa bi ẹni pe ko si nkankan to ṣẹlẹ.
Ademola gbadura fun awọn obi ki wọn ma mọ saree ọmọ, to si ni ki Ọlọrun tọju awọn obi naa, ko pẹtu si wọn lọkan.
Eyi ni oṣere miran ti ọmọ rẹ ku sinu omi iluwẹ 'Swimming pool'
Ọdun 2018 ni iroyin jade pe gbajugbaja olorin takasufẹ, D'banj ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin ni inu iṣẹlẹ riri si inu omi 'pool' to wa ninu ile wọn.
Ọmọ naa, Daniel Oyebanji to jẹ ọmọ ọdun kan nigba naa ni iṣẹlẹ iku rẹ bani ninu jẹ julọ.
Lasiko naa lọhun ni Dbanj fi aworan dudu si oju opo ikansiraẹni Instagram rẹ pẹlu ọrọ pe asiko ewu ni awọn wa amọ igbagbọ ohun ni pe Ọlọrun jẹ otitọ ni igba gbogbo.
Dbanj lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ni ko si ni Naijiria, to si wa nibi Ami ẹyẹ BET to n waye ni Los Angeles nigba naa lọhun.
Iroyin gbe e pe lẹyin naa ni Dbanj pada wa si ile lati wa ṣedaro pẹlu iyawo rẹ ni Naijiria.
Amọ idunnu subu lu ayọ fun wọn ni ọdun to kọja nigba ti tọkọ-taya naa bi ọmọbinrin tuntun jojolo.