You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá ṣàwárí ọkọ̀ Mercedes o ní N55m tí oníbàrà jí gbé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan
Ileeṣẹ ọlọpaa ti sawari ọkọ Mercedes Benz GLB 250 kan ti oníbàrà kan jígbé niluu Abuja lọ́sẹ̀ to kọja.
Ọgbọnjọ, oṣu Kẹfà, ọdun 2023 ni oníbàrà naa ti wọn pe orúkọ rẹ ni Henry ji ọkọ̀ naa ti owo rẹ to miliọnu marundinlọgọta Naira, gbe lọ nibi tó ti fẹ́ ẹ ra.
Iroyin sọ pe Henry lọ si ibudo kan ti wọn ti n ta ọkọ, to si ná ọkọ Mercedes naa.
Lẹyin ti wọn fi ẹnu ko lori iye ti wọn fẹ ta ọkọ, N55m, Henry ati aṣojú ile itaja naa gbé ọkọ̀ si ojupopo lati mọ bi iṣẹ́ rẹ ṣe dara sí.
Láìpẹ́ ni wọn gbe ọkọ naa yà si ile epo lati ra epo. Nibi ti ẹni naa ti sọkalẹ lati lo ẹ̀rọ POS, ni Henry ti wa ọkọ sálọ.
Iroyin ole jija naa tàn kaakiri ori ayelujara.
Àmọ́ ni òwúrọ̀ Ọjọ́rú , ọjọ karùn-ún , oṣù Keje, ni iroyin jade pe wọn ti ri ọkọ naa nipinlẹ Delta.
Iwe iroyin Punch jábọ̀ pé ìlú Ughelli ni wọ́n ti ri ọkọ naa ni nnkan bi aago kan òru, nibi ti wọn gbé e si ninu igbó.
Ẹni to ni ọkọ̀, Mohammed Manga, sọ fun awọn akọroyin pe ọwọ́ ko tii tẹ afurasí to gbe ọkọ sálọ.
Kọmíṣọnnà ọlọpaa nipinlẹ Delta, Wale Abass sọ pe awọn ṣi n wa afurasí naa.