You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn ikú Akeredolu, amúgbálẹ́gbẹ́ mẹ́ta kọ̀wé fipò sílẹ̀, Gómìnà Ayedatiwa yan àwọn èèyàn tuntun sípò
Ẹni to jẹ Akọwe agba fun ikede ati iroyin, fun Gomina Rotimi Akeredolu to di oloogbe, Ọgbẹni Richard Olatunde, ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Yatọ si Olatunde, oludamọran pataki fun Akeredolu lori ọrọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, Dare Aragbaiye, naa ti fi iṣẹ silẹ.
Awọn mejeeji kọwe fi ipo wọn silẹ lẹyin wakati diẹ ti Gomina Akeredolu ku.
Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Akeredolu ku lẹyin ti jẹjẹrẹ koropọn ba a finra fun igba pipẹ.
Ninu iwe to kọ si akọwe fun ijọba ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Olatunde sọ pe pẹlu ọkan to wuwo ati ibanujẹ to pọ, ni oun fi kọ iwe naa lati fi ipo silẹ gẹgẹ bi Akọwe ikede fun gomina.
O ni lọgan si ni iṣẹ oun tan.
“Igbesẹ mi ko ṣẹyin iku ojiji to pa adari wa, ọga mi, to tun jẹ bi baba, Gomina Rotimi Akeredolu.”
Bakan naa ninu lẹta ti oun naa fi kọwe fi ipo silẹ,Ọgbẹni Dare Aragbaiye, sọ pe oun ṣe bẹẹ nitori iku ọga oun – to jẹ akinkanju ati adari to jẹ olotitọ, Gomina Rotimi Akeredolu, “ti mo jẹ olotitọ si, koda lẹyin iku rẹ”.
Yatọ si awọn meji yii, oludamọran pataki fun gomina lori awn akanṣe iṣẹ ati ilana gbogbo, Ọmọwe Oladoyin Odebowale, naa kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Gomina Lucky Aiyedatiwa yan awọn oluranlọwọ tuntun
Wakati diẹ lẹyin ti wọn kede iku Gomina Akeredolu, ni igbakeji rẹ, to tun jẹ adele fun, Lucky Aiyedatiwa, di gomina.
Eyi waye lẹyin ti adajọ agba nipinlẹ Ondo bura fun nile ijọba to wa ni Alagbaka, nilu Akure.
Ni kete ti wọn bura fun si ni iroyin sọ pe o ti yan awọn eeyan kan si ipo.
Lara awọn iyansipo naa ni ti Akọwe agba fun ikede ati iroyin, Ọgbẹni Ebenezer Adeniyan, ati Sunday Abire gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki lori iroyin ori ayelujara.
Awọn miran ti Gomina Aiyedatiwa tun yan sipo ni Smart Omodunbi gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki fun gomina lori eto oṣelu, Motunrayo Oyedele (oluranlọwọ pataki lori aworan yiya), ati Temitayo Iperepolu (oluranlọwọ pataki fun gomina lori amojuto ile ijọba.
Aiyedatiwa ni gomina keje ti yoo dari ipinlẹ Ondo.