Ààrùn Ibà Lassa bẹ́ sílẹ̀ ní Kaduna, ó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́rin lọ

Oríṣun àwòrán, Web
Ijọba ipinlẹ Kaduna ti fidi rẹ mulẹ pe ko din eeyan mẹrin ti arun iba Lassa ti pa ni ile iwosan awọn oṣiṣẹ ologun ti 44 Nigerian Army Reference to wa nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina Uba Sani, Muhammad Shehu gbe jade l’Ọjọbọ ọsẹ yii, o ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn alakoso ile iwosan naa lori ọna lati fi opin sii.
Gomina Sani sọ pe wọn ti ṣawari ẹni to kọkọ ni arun naa lara, to si ko o ran awọn yooku, ati pe ẹni naa ti n gba itọju.
Gomina Kaduna bẹrẹ iṣẹ iwadii lọna ati mọ bi itankalẹ arun naa yoo ṣe dawọ duro
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “Ijọba ipinlẹ Kaduna ti gbọ nipa arun aṣekupani Viral Hemorrhagic Fever ti ọpọ mọ si Iba Lassa ni ile iwosan 44 Nigerian Army Reference to wa niluu Kaduna.
“Kete ti Gomina Uba Sani ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, lo ti paṣẹ fun ileeṣẹ to n mojuto eto ilera nipinlẹ naa lati bẹrẹ iṣẹ iwadii nipa aisan naa, ki wọn si fidi rẹ mulẹ.
“Siwaju sii, ikọ oluwadii naa tun ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lojuna lati mọ bi itankalẹ arun naa yoo ṣe dawọ duro, pẹlu ajọṣepọ awọn alakoso ile iwosan ọhun
“Ni bi a ṣe n sọrọ yii, eeyan mẹrin la ti akọsilẹ rẹ ti wọn ti jade laye ninu ọsibitu yii, nigba ti awọn mẹta yooku ti awọn naa ti ni arun yii ti n gba itọju to pe ye.
"A ti tilẹkun ile iwosan ti arun ti bẹ silẹ pa fawọn araalu titi digba ti arun naa yoo fi kasẹ nilẹ̀ tan"
“Ileeṣẹ eleto ilera ipinlẹ Kadanu ati awọn alakoso ile iwosan 44 Nigerian Army Reference, naa ti n ṣiṣẹ takuntakun lọsan ati loru lati rii pe wọn ṣawari gbogbo awọn to ti ni arun yii pata, wọn si fi wọn si ipamọ fun itọju.
“Bakan naa, a ti gba ẹjẹ wọn fun ayẹwo, a si ti fi ranṣẹ si ileeṣẹ to n mojuto idena ajakalẹ arun lorileede yii, iyẹn Nigeria Centre for Disease Control, ti awa naa si n tọpinpin bo ṣe n lọ.”
Gomina Sani wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti tilẹkun ile iwosan naa pa fun awọn araalu titi digba ti wọn yoo fi gbogun ti arun naa tan patapata.
Bẹẹ lo rọ araalu lati sọra fun iru ounjẹ ti wọn yoo maa jẹ, ki wọn si maa ṣe imọtoto ayika ati agbegbe wọn.
ki wọn tete fi to awọn tọrọ kan leti, bi wọn ba kofiri ẹni to ni arun naa lara.
Ẹ ma bẹru, ko si ewu kankan – Ileeṣẹ ologun
Ileeṣẹ ologun ti 44 Nigerian Army Reference ti wa sọ pe ki awọn araalu ma ṣe bẹru lori iroyin nipa arun Iba Lassa to tun gbode lati ọdọ wọn.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn, Onyema Nwachukwu fi sita, o ṣalaye pe awọn ti fun awọn ohun to le pa ajakalẹ arun naa ati oniruuru aisan tabi arun miran si gbogbo ayika ile iwosan ọhun lati dẹkun rẹ.
Nwachukwu ni awọn ti ile iwosan ọhun pa, ati pe gbogbo awọn to n gba iwosan pajawiri lawọn ti ko kuro.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu idena arun naa lawọn ti n ṣe, to si ni gbogbo awọn to ṣee ṣe ki wọn nii lara lo ti n gba itọju














