Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ yóò gbọ́ àwọn ẹ̀sùn tí Atiku ní lórí èsì ìdìbò ààrẹ l'ọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Igbimọ to n gbọ awọn awuyewuye ati ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo aarẹ, ti da ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, lati gbọ awọn ẹsun ti oludije PDP sipo aarẹ, Atiku Abubakar, pe lori idibo naa.

Amọ, Ọjọru, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni igbimọ to n gbọ ẹsun to ṣuyọ lẹyin idibo aarẹ yoo bẹrẹ igbẹjọ ni pẹrẹu.

Ikede naa waye lẹyin ti awọn adajọ to n dari igbimọ naa, sun ọjọ ti wọn o gbọ awọn ẹsun ti oludije sipo aarẹ lati ẹgbẹ osẹlu Labour, Peter Obi, pe aarẹ ti ilu dibo yan, Bola Tinubu, ati ajọ INEC, si ọjọ kẹwaa bakan naa.

Ọjọru yii kan naa ni igbimọ naa yoo gbọ awọn ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party, APP, fi kan Bola Tinubu ati ajọ INEC bakan naa.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu Action Alliance (AA) kede pe awọn ko ba Bola Ahmed Tinubu ati INEC, ṣe ẹjọ mọ.

Ni ibẹrẹ igbẹjọ naa ni ọjọ Aje, ni olori igbimọ ọhun, Onidajọ Haruna Tsammani, ti ṣeleri lati ṣe idajọ to yẹ fun gbogbo awọn ti ọ̀rọ̀ kàn.

Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ èsì ìdìbò Ààrẹ bẹ̀rẹ̀ ìjókòó l’Abuja, ẹgbẹ́ òṣèlú AA ní òun kò ṣe ẹjọ́ mọ́

Igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun lori idibo Aarẹ Naijiria ti bẹrẹ ijoko niluu Abuja.

Wamuwamu ni awọn ẹṣọ alaabo ro niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun, Court of Appeal, nibi ti igbẹjọ naa yoo ti maa waye l’Abuja.

Nnkan bii aago mẹwaa abọ aarọ oni ọjọ Aje ni igbẹjọ naa bẹrẹ, nibi ti ọpọlọpọ awọn agbẹjọro awọn olupejọ wa.

Oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi wa nile ẹjọ bi igbẹjọ ṣe n lọ lọwọ, nigba ti gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, ṣoju fun Bola Tinubu, ti ajọ INEC kede kede pe awọn araalu dibo yan nibi igbẹjọ ọhun.

Lara awọn agbẹjọro to wa nibẹ ni; Solomon David, to n ṣojú fún Action Alliance, AA, nigba ti Barrister May n ṣoju fun ajọ eleto idibo, INEC.

Awọn àgbẹjọ́rò tó ń sójú fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni Adeniyi Akintola, Afọlábí Fashanu, olóyè Arábìnrin Olanbisi Soyebo, Olóyè Abiodun A. J. Owonikoko, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayode ati olóyè Akeem Afolabi.

Ẹwẹ, agbẹjọro fun ẹgbẹ oṣelu AA, Solomon David, ti sọ pe awọn ko ṣe ẹjọ mọ, ile ẹjọ naa si ti da ẹjọ wọn nu nigab ti ẹjọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ku n tẹsiwaju.

Lónìí ni ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ èsì ìdìbò Ààrẹ yóò bẹ̀rẹ̀ ìjókòó nílùú Abuja

Loni ni igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun lori idibo aarẹ Naijiria to waye yoo bẹrẹ ijoko.

Igbẹjọ yi n waye ni bo ṣe ku ọsẹ mẹta din diẹ ti wọn yoo bura wọle sipo fun Bola Ahmed Tinubu, ti ajọ eleto idibo kede pe o jawe olubori ninu idibo naa.

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun agba to wa ni ilu Abuja ni awọn agba adajọ yoo ti joko gbọ atotonu awọn agbẹjọro oludije to n tako esi yi.

Awọn alatako taa n wi yi ni Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ati Peter Obu ti ẹgbẹ Labour Party.

Wọn beere lọtọọtọ pe ki ile ẹjọ kede awọn gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo to waye lọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Keji.

Ninu idibo yi, Bola Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi INEC ṣe kede ri ibo 8,794,726 lati bori awọn oludije mẹtadinlogun miran.

Atiku Abubakar ri ibo 6,984,520 ti Peter Obi si ri ibo 6,101,533.

Bi ijoko yoo se lọ

Adajọ ti yoo lewaju ijoko yi ni ààrẹ ilè ẹjọ kotẹmilọrun , Adajọ Monica Dongban-Mensem.

Yoo ṣide ijọko pẹlu awọn adajọ miran loni.

Iṣide ijoko yi ni yoo fi aaye silẹ lati jiroro lori awọn ọrọ ibẹrẹpẹpẹ.

Eleyi yoo fun igbẹjọ lanfaani lati gbe igbesẹ lori awọn ibeere ti agbẹjọro kọọkan ba gbe wa siwaju ile ẹjọ ti wọn yoo si le sọ bi eto yoo se lọ ni ṣiṣẹ n tẹle.

Bẹẹ lawọn agbẹjọro kọọ́kan yoo sọ atotonu ati awijare wọn lẹyin igba ti awọn adajọ yoo le gbe idajọ kalẹ lori ẹri ti wọn ba mu wa.

Baa ti ṣe sọ saaju, ọtọtọ ni Atiku ati Obi gbe ẹjọ wọn wa ti onikaluku si fẹ ki igbimọ wọgile ijaweolubori Tinubu.

Wọn n sọ pe kudiẹkudiẹ pọ ninu esi yi tori naa ki wọn kede awọn gẹgẹ bi aarẹ to jaweolubori.

Amọ ṣa awọn igbimọ agbẹjọro Ahmed Tinubu ti wọn kede gẹgẹ bi ẹni tara ilu dibo yan n sọ pe ko si nkankan to mẹhẹ ninu idibo to gbe wọle.

Wọn lawọn fẹ ki adajọ fọwọ rọ gbogbo ẹjọ ti wọn pe danu sẹgbẹ kan.

Awọn oludije miran naa n takò esi idibo yí.

Ninu wọn la ti rí oludije labe asia ẹgbẹ Action Alliance Ọgbẹni Solomon Okangbuan.

Oludije ẹgbẹ APM naa Princess Chichi Ojei ati ẹgbẹ rẹ.

Pupọ awọn ti n tako esi yi da ọrọ wọn lori aitẹle ofin eto idibo 2022 ati awọn ilana ti INEC la kalẹ fún idibo yí.

Wọn ní ojoro pọ ninu idibo naa nitori ailo ẹrọ Irev lati fi esi idibo ranṣẹ gba oju opo INEC lati awọn ibudo idibo kọọkan.

Oludije ẹgbẹ oṣelu Labour baa se gbọ sọ pe Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ Kashim Shettima ko lẹtọ lati kopa ninu idibo naa.

Awon tí wọn pe lẹjọ ni àjọ eleto idibo Inec Ahmed Tinubu,Kashim Shettima ati ẹgbẹ to wà lori aleefa APC.

Igba akọkọ kọ ní yí tawọn ẹgbẹ oṣelu yoo tako esi idibo ni ile ẹjọ.

Wọn kò ti kede orukọ awọn adajọ tí yoo gbẹjọ yi ṣugbọn Ileesẹ iroyin redio àpapọ Naijiria FRCN ni eeyan kan tawọn lolobo pe awọn adajọ to ti n gbọ awọn ibeere ibẹrẹ ninu ẹjọ yi naa ni yoo tẹsiwaju gbọ ẹjọ naa.

Awon wonyi ni Adajọ Haruna Tsammani, Adajọ Stephen Adah, Adajọ Abba Mohammed, Adajọ Joseph Ikyegh ati ààrẹ ilè ẹjọ kotẹmilọrun Adajọ Monica Dongban-Mensem.

Nkan bi oṣù mẹfa ni ilé ẹjọ ni lati gbẹjọ yi.