Ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́wàá tó ti wáyé ní Afrika láàárín ọdun márùn ún sẹ́yìn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Laarin ọdun marun un si asiko yii, o kere tan, iṣẹlẹ iditẹgbajọba mẹsan an ọtọto lo ti waye nilẹ Afrika.

Laipẹ yii ni ologun gbajọba ni Guinea-Bissau lasiko ti awọn araalu n reti esi ibo Aarẹ.

Eyii to ṣẹṣẹ waye yii ni ti orilẹede Benin ti awọn ologun jade lori ẹrọ agbohunsafẹfẹ pe awọn ti ditẹgbajọba amọ lẹyin wakati diẹ ni ijọba orilẹede naa ni awọn ti gba agbara pada.

Lorilẹede Burkina Faso nikan ṣoṣo, igba meji ọtọtọ ni ologun gbajọba nibẹ.

Iwọnyii ni alakalẹ orileede atawọn akoko ti ologun ditẹgbajọba nilẹ Afrika lati ọdun 2020 si asiko yii

1. Mali

Ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2020, ọgagun marun un gba ijọba mọ Aarẹ Ibrahim Boubacar Keita lọwọ.

Nigba ti yoo di inu oṣu Karun un ọdun 2021, ologun tun ditẹ gbajọba mọ ijọba fidihẹ to wa nibẹ lọwọ.

Ọgagun Assimi Goita to gbajọba nigba mejeji naa ṣeleri lati ṣeto idibo lọdun 2024 amọ eto idibo naa ko waye latari ikọlu awọn alakakiti ẹsin Islam.

2. Chad

Ni Chad, Aarẹ Idriss Deby ku latari ọgbẹ to gba ninu ija kan lọdun 2021.

Awọn ọmọ ogun orilẹede naa da ijọba to wa lode ru wọn si fi ọmọ rẹ, Mahamat Kaka Deby, sipo gẹgẹ bii Aarẹ fidihẹ.

Lọdun 2025, o kopa ninu eto idibo o si bori lati pada sori aga Aarẹ.

3. Guinea

Ninu oṣu Kẹsan an ọdun 2021, ọpọlọpọ ọmọ igun ti ọgagun Mamady Doumbouya ko sọde gba ọpa aṣẹ ijọba mọ Aarẹ Alpha Condé lọwọ.

Ni bayii, Doumbouya ti kede pe oun yoo dije fun ipo Aarẹ ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025 yii.

4. Sudan

Inu oṣu Kẹwaa ọdun 2021 ni ọgagun Abdel Fattah al-Burhan gbajọba ni Sudan lẹyin gbas-gbos kan laarin araalu ati ologun.

Lati ọdun naa wa ni ija ti n waye laarin ọmọ ogun ijọba atawọn ọmọ ogun Rapid Support Forces. Ẹgbẹlẹgbẹ araalo si ti ba ija naa lọ.

5. Burkina Faso

Igba meji ọtọtọ ni ologun gbajọba nibẹ lọdun 2022 nikan ṣoṣo.

Ninu oṣu Kinni, ọgagun Paul-Henri Sandaogo Damiba le Aarẹ Roch Marc Christian Kaboré kuro lori oye.

Ni gba ti yoo di oṣu Kẹsan an, wọn le Dambila danu, ọgagun Ibrahim Traoré si joko sori aga ijọba.

Ninu oṣu Kẹta ọdun 2025, ijọba Ibrahim Traoré fi ọdun marun un kun ijọba wọn.

Pẹlu gbogbo eyii, ijọba ologun naa ko tii rẹyin ogun awọn alakakiti ẹsin Islam nibẹ.

6. Niger

Ninu oṣu Kẹfa ọdun 2023, awọn ẹṣọ to n ṣọ Aarẹ Mohamed Bazoum gbajọba mọ lọwọ ti ọgagun Abdourahamane Tiani, si gba ọpa aṣẹ ijọba.

Ninu oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, ijọba naa fi ọdun marun un kun saa wọn.

7. Gabon

Lẹyin ọdun marunlelaadọta ti mọlẹbi Bongo ti n tukọ orilẹede naa, awọn ologun gbajọba lọwọ Ali Bongo Ondimba ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2023 lẹyin to tun fi madaru bori ibo Aarẹ.

Ọgagun Brice Oligui Nguema lo n tukọ orilẹede naa ki wọn to fi ibo gbe wọle ninu oṣu Karun un, ọdun 2025 lẹyin to bori ida 95.85% ibo Aarẹ.

8. Madagascar

Ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni awọn ologun yọ Aarẹ Andry Rajoelina bii jiga lẹyin ti awọn ọdọ "Gen Z" ṣe ifẹhonuhan ọlọjọ pupọ.

Ọgagun Michael Randrianirina to n tukọ orilẹede naa bayii sọ pe oun yoo ṣeto idibo laarin ọdun meji pere.

9. Guinea-Bissau

Guinea-Bissau wa lara awọn orilẹede ti iditẹgbajọba ti waye julọ ni Afrika.

Oṣu Kọkanla ọdun yii ni ologun tun kede pe awọn tun ti gbajọba lọwọ Aarẹ Umaro Sissoco Embalo.

10. Benin

Inu oṣu Kejila ọdun 2025 yii ni awọn ọmọ ogun kan kede lori tẹlifiṣọn pe awọn ti ditẹgbajọba lọwọ Aarẹ orilẹede naa.

Ijọba Naijiria tilẹ fi ọmọ ogun pajawiri ṣọwọ sibẹ fun iranlọwọ ki ijọba wọn to kede pe awọn ti rẹyin ikọlu naa ati pe ijọba ti gba agbara pada.