You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lóòótọ́ ni mi ò kí ń dárúkọ Jesu nínú orin mi, Jesu kò ní ká polongo òun – Sola Allyson
Gbajugbaja olorin ẹmi, Sola Allyson, ti sọ pe oun kii ṣe olorin ẹsin, bikoṣe olorin ẹmi.
Allyson lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ori ayelujara, Oyinmomo TV.
Inu ifọrọwerọ naa lo ti tu pẹrẹpẹrẹ nipa igebsi aye rẹ, bo ṣe dagba, bo ṣe bẹrẹ orin kikọ, oju to fi wo ẹsin, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
"Lootọ ni mi o ki n daruko Jesu ninu orin, Jesu ko ni ka ṣe ipolongo fun oun"
Nigba to n sọrọ nipa irufẹ orin to n kọ, o ni oun kii ṣe olorin to n gbe ẹsin lori amọ orin ijinlẹ ẹmi loun n kọ, ko si sẹni ti ko le gbọ orin oun lai fi ti ẹsin ṣe.
O ni "Mi o mu wa ni ti ṣein, mi o kọ orin ẹsin o.
"Mo ti maa n sọ ọ tipẹ, mi o kọ orin ẹsin, orun ẹmi ni mo n kọ. Ẹmi ni gbogbo wa, ẹmi lo n ri ẹmi."
Sola sọ pe bi oun ṣe maa n bo ori lọpọ igba kii ṣe nitori ẹsin amọ o o jẹ nitori pe oun fẹ ki awọn eeyan maa ri oun gẹgẹ bii ọmọ bibi ilẹ Afrika tootọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, asiko to ba n ṣiṣẹ tabi kọ orin lori itage nikan loun maa n bori.
"Awọn kan sọ pe ẹmi ẹsu lo wa ninu mi"
Allyson sọ siwaju pe oun gba Jesu gbọ gẹgẹ bii Kristẹni amọ oun ko gbe ẹsin lori.
Latari irufẹ orin to n kọ, o ni awọn kan fẹ maa pe oun lawọn orukọ kan bii pasitọ amọ oun kọ jalẹ.
O ni "Ẹmi ni Ọlọrun, a si gbọdọ sin in ninu ẹmi ati ni otitọ, kii ṣe nipa ṣiṣẹ karimi tabi oju aye.
"Awọn ẹlomii a fẹ pe mi ni pasitọ maa ni irọ ni, wọn a ni ẹmi eṣu lo wa ninu mi ni mi o fi gba ki wọn maa pe mi ni pasitọ.
"Awọn ẹlomii a ni ajihinrere ni mi maa ni rara wọn a ni 'mo ti sọ fun yin, ẹmi ẹsu wa ninu rẹ ni ko ṣe gba orukọ awọn ọmọ Ọlọrun.'
"Mo sọ fun wọn pe orukọ mi ni Sola Allyson, olorin ẹmi ni mi. Ko ju bẹẹ lọ."
"Mo ti n kọ orun fun nnkan bii ọdun marundinlogun ki n to kọ Eji Owuro"
Sola sọ siwaju sii pe o ti pẹ ti oun ti n kọ orin, amọ baba kan to ti di oloogbe lo tunbọ ru oun soke lati maa kọ orin lasiko ti oun darapọ ẹgbẹ akọrin ijọ Celestial lọpọ ọdun sẹyin.
Bo tilẹ jẹ pe o ti le ni ọdun mejilelogun to kọ orin Eji Owuro to sọ ọ di ilumọọka, o ni oun ti n kọ orin lati nnkan bii ọdun marundinlogun ṣaaju asiko naa.
Lalapọ, Sola ni o ti le ni ọdun mẹrindinlogji ti oun ti n kọ orin faraye gbọ.