You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló dé tí APC yọ Omisore, Omoworare àtàwọn mí-ìn kúrò nínú ìbò abẹ́lé sípò gómìnà Osun?
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti fodin de igbakeji gomina Osun nigba kan, Senetọ Iyiola Omisore ati awọn agba oloṣelu mi-in lati ma ṣe kopa ninu idibo abẹle sipo gomina ipinlẹ Osun to n bọ lọna.
Yatọ si Omisore, awọn mi-in ti APC tun fofin de ni Senetọ Babajide Omoworare, Kunle Adegoke (SAN), Akin Ogunbiyi, Benedict Olugboyega Alabi toun naa ti figba kan jẹ igbakeji gomina, Dotun Babayemi ati Babatunde Haketer Oralusi.
Ibo abẹle si ipo gomina Osun naa ni wọn ni yoo waye lọjọ kẹtala, oṣu Kejila ọdun 2025.
Gẹgẹ bi igbimọ to ṣeto ayẹwo fun awọn oludije ti wọn fofin de yii ṣe wi lanaa ọjọ Ẹti, eyi ti Amofin Obinna Uzor, lewaju, wọn ni Ọnarebu Mulikat Adeola Jimoh ati Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji, nikan ni wọn yege ni gbogbo ọna lati kopa ninu ibo abẹle yii.
Igbimọ ẹlẹni mẹtadinlogun to yẹ awon oludije naa wo, sọ pe awọn wọnyi ni wọn tẹle ilana alakalẹ ofin idibo ẹgbẹ ati ti ajọ eleto idibo.
Kí ni Omisore àti àwọn mẹ́fà yókù ṣe?
Ninu iwe oloju ewe mẹfa ti wọn fi ṣalaye igbesẹ to yọ Omisore ati awon yoku rẹ, eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ yoku fọwọ si, wọn ṣalaye pe ipinnu naa waye latari ifisun kan to wa lati ọdọ ẹgbẹ Osun APC Renewal Group.
Iwe ifisun naa beere fun yiyọ meji danu ninu awọn oludije naa, wọn ni wọn ko yege awọn ofin ati ilana ti ẹgbẹ la kalẹ to jẹ dandan.
Eyi ni igbimọ wo, ti wọn si ni léyin ayẹwo finni-finni, awọn ri i pe ifisun naa lẹsẹ nilẹ, o si wulo bawọn ba n fẹ otitọ nipa ayẹwo awọn oludije naa.
Lati rin in lọna to tọ, igbimọ sọ pe awọn tun lo ṣe ayẹwo kan naa fun awọn ọludije yooku.
" Igbimọ tẹsiwaju pẹlu awon oludije mẹsan-an to ku, a ri i daju pe gbogbo awọn to fa oludije kalẹ tabi ti wọn n ran wọn lọwọ ni wọn wa ni ibamu pẹlu abala 9.3(i) ati 31.2(ii) ofin ẹgbẹ APC, ati ila kẹfa (Paragraph 6(c) ofin naa bo ṣe la a kalẹ."
Bẹẹ ni apa kan iwe ti igbimọ fi jábọ̀ naa ka.
Lẹyin ọjọ meji ti wọn fi ṣe ayẹwo ọhun ni wọn fidi ẹ mulẹ, pe Jimoh ati Oyebamiji nikan ni odù wọn kun.
Wọn ni awọn ni wọn yege gbogbo alakalẹ ẹgbẹ APC lati ibi iforukọsilẹ debi ọrọ owo dida deede ninu ẹgbẹ.
Igbimọ naa woye, pe Senetọ Omisore ati Omoworare pẹlu Babayemi, Ogunbiyi, Alabi, Adegoke ati Oralusi, ko ri ẹni fa wọn kalẹ lati o kere tan, ọwọ ọmọ ẹgbẹ marun-un to n dawo deede ninu ẹgbẹ lati ijọba ibilẹ kọọkan. Bẹẹ, dandan leyi bi ofin ẹgbẹ ṣe sọ.
Ṣugbọn ṣaa, igbimọ naa fi orukọ awọn meje yii ranṣẹ si igbimọ Apapọ Amuṣẹṣe, National Working Committee (NWC) lati ṣe ayẹwo igbẹyin, boya wọn yoo ṣi le ri nnkan ṣe si i ki idibo too waye.
Ẹwẹ, igbimọ ayẹwo Ko-tẹ-mi-lọrun, ti Senetọ Tola Odebiyi n lewaju, ni ireti wa pe wọn yoo pade niluu Abuja lonii ọjọ Abamẹta, lati yẹ ọrọ awọn ti wọn yọ ọwọ wọn lawo naa kuro, atawọn miran to ba tun ni ikunsinu kan tabi ikeji ninu ọmọ ẹgbẹ.
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Omisore to fẹ dupọ gomina Osun
Omisore dupo gomina ni ọdun 2014 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Igbagbọ wa pe o wa lara awọn oludije to ṣee ṣe ki wọn gba tikẹẹti lati soju ẹgbẹ APC ninu eto idibo to n bọ.
Omisore, jẹ igbakeji gomina laaarin ọdun 1999 si 2003 labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), to si tun di sẹnetọ to soju ipinlẹ Osun laaarin 2003 si 2011.
Sẹnẹtọ Omisore fidirẹmi ninu ibo gomina lọdun 2014, nigba ti Rauf Aregbesola wọle eto idibo naa.
Bakan naa lo tun ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) nigba kan ri.
Omisore tun dupo gomina lọdun 2018, ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2021.
Lara awọn ipo ti Omisore ti dimu ri ipo akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC.