Orílẹ́èdè Afirika níbi táwọn èèyàn ti ń pa ara wọn jùlọ lágbàáyé rèé

Matlohang Moloi ree nilee rẹ.
Àkọlé àwòrán, Matlohang Moloi ree nilee rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Orilẹede Lesotho wa ni Guusu ilẹ Africa, ibẹ ni iya kan, Matlohang Moloi; ẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79) n gbe.

Orilẹede naa ni akọsilẹ sọ pe awọn eeyan ti n gba ẹmi ara wọn ju lagbaaye bayii.

Ọmọ mẹwaa ni Matlohang bi, akọbi rẹ, Tlohang, ẹni ọdun mejidinlogoji, wa lara awọn ti wọn gba ẹmi ara wọn ni Lesotho.

" Ọmọ daadaa ni, o ti sọ fun mi tẹlẹ nipa aipeye ilera rẹ. Koda, lọjọ to para rẹ gan-an, o ti kọkọ waa sọ fun mi pe ọjọ kan ni ma a gbọ pe oun ti para oun''

Matlohang, iya arugbo naa lo ṣalaye fun BBC bayii nipa akọbi rẹ to gba ẹmi ara rẹ. He had told me about his mental health struggles," Ms Moloi says.

"Iku rẹ dun mi pupọ, bawo ni ko ba ti dun to kani o sọ kulẹkulẹ ohun to dun un lọkan fun mi. Ero ọkan rẹ ni pe awọn eeyan yoo bu u to ba sọrọ jade nipa iṣoro rẹ.''

Bẹẹ ni iya naa fi ẹdun ọkan ṣalaye nipa Tlohang to pa ara rẹ nitori ailera.

Aworan Tlohang to pa ara rẹ ree ninu kaadi idanimọ rẹ.
Àkọlé àwòrán, Aworan Tlohang to pa ara rẹ ree ninu kaadi idanimọ rẹ

Ìdá 87.5 èèyàn ló ń pa ara wọn lọ́dún ni Lesotho

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eleto Ilera Agbaye (World Health Organization), ida mẹtadinlaaadọrun o le marun-un (87.5) ninu eeyan 100,000 ni wọn n pa ara wọn ni Lesotho lọdọọdun.

Orilẹede Guyana to wa ni South America lo ṣikeji, ṣugbọn ida ogoji eeyan (40%) lo n gba ẹmi ara wọn nibẹ yẹn.

Onka awọn to n pa ara wọn yii n kọ ọpọ eeyan lominu, to si ti fa a ti ajọ kan, HelpLesotho, ṣe pinnu lati yi nnkan pada fun wọn.

Ọkan ninu awọn to n ri si eyi ni obinrin kan, Lineo Raphoka.

Ninu awọn eeyan to n ta ajọ yii lolobo ni ọmọbinrin kan, Patience, ẹni to sọ pe mẹta ninu awọn ọrẹ oun lo ti pa ara wọn.

Koda, o ni oun funra oun ti gbiyanju lati pa ara oun ri.

Lineo Raphoka, ọkan ninu awọn to n gba awọn eeyan niyanju lati ma ṣe pa ara wọn nitori ailera.
Àkọlé àwòrán, Lineo Raphoka, ọkan ninu awọn to n gba awọn eeyan niyanju lati ma ṣe pa ara wọn nitori ailera.

Ṣàṣà èèyàn ni kò tí ì ronú láti pa ara wọn rí ní Lesotho

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fẹre ma si ẹnikan ti ko ti i figba kan ri ni ero lati pa ara rẹ ni Lesotho, bẹẹ ni gbogbo wọn ni wọn mọ eeyan to jẹ funra wọn ni wọn pa ara wọn.

Iriri obinrin kan, Ntsoaki, lo mu ko maa ronu lati pa ara rẹ.

Obinrin naa ṣalaye pe, ''Dokita fipa ba mi lo pọ nileewosan, o ni mo ti rẹwa ju, ki n jẹ koun ba mi lo pọ tabi koun pa mi ti mi o ba gba.

"Dokita naa yọ ibọn si mi, o si ṣe ohun to fẹẹ ṣe. Ti mo ba ti ranti, ero bii ki n pa ara mi lo maa n wa si mi lọkan. Ohun kan to n mu mi duro ko ju ti awọn eeyan mi ti wọn n ki mi laya, wọn ni akọni ni mi, ṣugbọn emi gbagbọ pe mo fuyẹ ju ẹgbọn owu lọ.''

Ẹgbẹ to n gbogun ti iparaẹni ọhun lo pada ki i laya, wọn dunnu si bo ṣe sọ ohun to ṣẹlẹ si i, kawọn eeyan mi-in naa le sọrọ, ki wọn si ma ṣe pa ara wọn.

Idi tawọn eeyan fi n pa ara wọn maa n ruju nigba mi-in, ifipabanilopọ ni ti awọn mi-in, ainiṣẹlọwọ lo n mu awọn kan gba ẹmi lẹnu ara wọn, iku ololufẹ ni ti awọn mi-in, bẹẹ ni aṣilo oogun ati ọti amupara ni iṣoro to n da ọkan awọn mi-in laamu.

Ida mẹrindinlaadọrun (86%) ninu awọn obinrin Lesotho lo n koju idaamu ati ijiya nile ọkọ ni Lesotho, gẹgẹ bi akọsilẹ agbaye kan ṣe sọ lẹyin iwadii ni 2022.

Ohun kan tawọn eeyan maa n sọ ju ni Lesotho ni pe ko dẹrun fawọn lati maa sọ ohun to n ṣẹlẹ fawọn eeyan, nitori wọn le maa da awọn lẹbi.

Ni bayii ṣaa, igbesẹ oriṣiiriṣii ti n waye lati ṣẹgun iṣoro yii.

Ipolongo ti bẹrẹ lati ileewe alakọọbẹrẹ de ileewe giga, pe kawọn eeyan yee pa ara wọn.

Ẹni to ba ni ipenija arun ti ko gboogun yoo ri ile itọju lọ ni Lesotho

Awọn ọkunrin Lesotho nibi ti wọn ti n sọ pe awọn n ran ara awọn lọwọ.
Àkọlé àwòrán, Awọn ọkunrin Lesotho nibi ti wọn ti n sọ pe awọn n ran ara awọn lọwọ.

Ìyá ṣàbẹ̀wó sí ibojì ọmọ tó pa ara rẹ̀

Matlohang ree ni iboji ọmọ rẹ, Tlohang. Ibi ti wọn sin oku naa si ko jinna sile wọn rara.
Àkọlé àwòrán, Matlohang ree ni iboji ọmọ rẹ, Tlohang. Ibi ti wọn sin oku naa si ko jinna sile wọn rara.

''Ohun ti mo fẹẹ sọ fawọn eeyan ni pe gbigba ẹmi ara ẹni ko yanju iṣoro , ohun to yẹ ki wọn ṣe ni pe ki wọn sọ ẹdun ọkan wọn fawọn eeyan to ba sun mọ wọn, ki wọn le ṣe iranlọwọ''

Bẹẹ ni iya agba, Moloi. ti akọbi rẹ para rẹ wi fun BBC.