Wo ìgbà márùn ún tí ẹ̀rọ apínnáká Naijiria ti kọṣẹ́ nínú ọdún 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun ọpọ wakati lawọn eeyan fi wa ninu okunku birimu lọjọ Aje ni Naijiria lẹyin ti ẹrọ to n pinna ka tun kọṣe.
Iṣẹlẹ naa ni igba karun un ti ẹrọ ọhun yoo kọṣẹ ninu ọdun 2024 nikan ṣoṣo.
Iroyin lati ọdọ ajọ apinnaka, Transmission Company of Nigeria (TCN), ṣafihan pe ni nnkan bii aago kan abọ ọsan ọjọ Aje, iye ina ti ẹrọ naa n gbe jade ja lati 3,241 MW si 1,255 MW.
Lasiko naa ni ẹrọ mọkanlelogun to n fa ina kaakiri Naijiria kọṣẹ jalẹ nigba ti mẹtadinlogun ṣi n ṣiṣẹ.
To n tumọ si pe bi awọn agbegbe kan ṣe wa ni okunkun birimu lawọn agbegbe kereje mii ni ina ọba.
Ajọ TCN ko sọrọ lori eredi ti ẹrọ naa tun fi kọṣẹ lasiko yii.
Wayi o, ki ṣe igba akọkọ ti ẹrọ naa yoo kọṣẹ ree ninu ọdun 2024.
Igba marun ti ẹrọ apinaka Naijiria kọṣẹ lọdun 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun yii ni ẹrọ naa kọkọ kọṣẹ, ninu eyii ti ajọ TCN fi sọ pe iye ina ti awọn n gbe jade ja silẹ lati 2,407MW si 31MW, ṣugbọn nigba ti yoo di ọsan gangan, ina naa ja si 0MW
- Igba keji ti ẹrọ to n pin ina ọba si gbogbo Naijiria kọṣẹ ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, eyii to jẹ ọjọ mẹtalelaadọta pere lẹyin iṣẹlẹ akọkọ
- Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹje ni igba kẹta ati ẹkẹrin ti ẹrọ ọhun yoo tun kọṣẹ
Ṣaaju lọjọ kinni, oṣu Karun un. ọdun 2024 ni TCN sọ pe adinku ti de ba bi ẹrọ naa ṣe maa n kọṣẹ.
Agbẹnusọ TCN, Ndidi Mbah, sọ lọjọ naa pe adinku 76.47% lo de ba bi ẹrọ ọhun ṣe n da iṣẹ silẹ laarin ọdun 2015 si 2019.
Amọ o ṣeni laanu pe ẹrọ naa tun kọṣẹ lọjọ Aje, ọjọ karun un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 ti a wa yii.
Ọpọ araalu lo ti bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ fun bi ẹrọ naa ṣe maa n kọṣẹ ni gbogbo igba, wọn si ti ke si ijọba apapọ lati wa ojutu si ọrọ ina ọhun ni kankan.















