You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta a ni Oba Olaitan tí ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re kéde gẹ́gẹ́ bíi olórí tí yóò rọ́pò Ayo Adebanjo?
Ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ti yan Oba Oladipo Olaitan gẹgẹ bii olori ẹgbẹ tuntun.
Ikede yii lo wa ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade oloṣooṣu to waye ni ile olori ẹgbẹ naa to di oloogbe, Pa Ayo Adebanjo, niluu Isanya Ogbo nipinlẹ Ogun.
Ipade naa ni awọn aṣoju lati ipinlẹ mẹfa to wa ni ilẹ Yoruba pẹlu ipinlẹ Kogi, Kwara ati Itsekiri nipinlẹ Delta wa ni ijokoo.
Akọwe agba fun ẹgbẹ Afenifere, Oloye Sola Ebiseni ati agbẹnusọ ẹgbẹ naa Justice Faloye lo buwọlu atẹjade naa.
Atẹjade naa ni, "Oba Olaitan yoo di eeyan to di ipo olori ẹgbẹ mu titi a o fi pari eto isinku Papa Ayo Adebanjo, lẹyin eto isinku, yoo bọ si ipo gẹgẹ bii Olori ẹgbẹ Afenifere."
"Lẹyin ọpọ jiroro, ẹgbẹ Afenifere buwọlu Oba Oladipo Olaitan gẹgẹ bi olori ẹgbẹ Afenifere."
Ni ọsẹ to kọja ni eekan ẹgbẹ naa, Pa Ayo Adebanjo jade laye.
Ni owurọ ọjọ, Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2025 ni Adebanjo dagbere faye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un (96).
Ile rẹ to wa ni agbegbe Lekki, ipinlẹ Eko ni Adebanjo dakẹ si.
Pa Adebanjo bẹrẹ si ní dari ẹgbẹ Afenifere nigba ti aarẹ ẹgbẹ naa, Fasoranti ni ki o maa dele fun oun nitori ọjọ ori oun.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Oba Oladipo Olaitan, Senator Femi Okunrounmu, Senator Gbenga Kaka, igbakeji gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Pekun Awobona, Tola Mobolurin, Tokunbo Ajasin, Bayo Adenekan, Leke Mabinuori, Olayemi Olajuyinu, Olu Pessu ati Olusegun Olawoyin.
Ta a ni Oba Olaitan?
Oba Olaitan di agbẹjọro ni 1971, to si tun jẹ oludamọran pataki lori ọrọ oṣelu fun gomina tẹlẹri nipinlẹ Eko, Lateef Jakande,.
Bakan naa lo tun jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ ijọba ipinlẹ Eko lati 1979 – 1983; ọmọ ile igbimọ aṣofin ati olori ẹgbẹ oṣelu AD ni ile igbimọ aṣofin lati ọdun 1999 – 2003.
O ti wa ninu ẹgbẹ Afenfere fun ọdun marundinlaadọta, to si tun ti di ọpọ ipo mu ninu ẹgbẹ naa. Lara wọn ni alumojuto isuna labẹ iṣakoso Oloye Reuben Fasoranti ati igbakeji olori labẹ Oloye Ayo Adebanjo.
Ninu ọrọ rẹ, olori ẹgbẹ tuntun ni gbogbo ohun ti yoo mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ naa ni oun yoo gunle, ti oun yoo si ri pe isọkan wa ninu ẹgbẹ.