Wo ìgbé ayé àwọn obìnrin ní Iran kí ìjìjàgbara Islam tó dé

Ọdun 1979 ni ijijagbara ẹsin Islam waye ni Iran, eyii to mu ọpọ ayipada ba igbe aye awọn obinrin orilẹ-ede naa.

Ọna kan gboogi ti iyipada naa ti farahan ni bi wọn ṣe n mura.

Ṣaaju lẹyin ọdun 1930, ni ijọba ilẹ naa ti kọkọ fofin de ibori fun awọn obinrin, awọn ọlọpaa si maa n fi agidi yọ ibori lori awọn obinrin ọhun laarin igboro.

Amọ lẹyin ọdun 1980, ẹsin Musulumi gbilẹ lorilẹ-ede Iran to bẹẹ ti ijọba ẹlẹsin Musulumi naa kan nipa fun gbogbo obinrin lati maa lo ijaabu.

Aworan awọn obinrin Iran ṣaaju ijijagbara ẹsin Islam

Awọn oibinrin fasiti Tehran lọdun 1977: Awọn mọlẹbi kan ko gba ki awọn ọmọ wọn obinrin maa lọ sile ẹkọ, amọ ijọba ṣe ilaniyọyẹ fun wọn nipa afaani to wa ninu ẹkọ.

Awọn obinrin to n na ọja lọdun 1976: Ọpọ eeyan lo n lo ijaabu lọdun 1976 amọ ko pọn dandan, bẹẹ si ni awọn obinrin kan yan lati maa ṣi irun wọn silẹ.

Lara awọn aṣọ ti wọn maa n wọ lọdun naa ṣaaju Islam ni ‘jeans,’ yẹri ti ko de orokun, atawọn aṣọ penpe miran.

Faaji ita gbangba lọjọ Jimoh ni 1976: Ọpọ awọn eeyan Iran lo fẹran ati maa ṣe faaji ni iwaju ile wọn ati leti okun lai bo ori wọn.

Ọjọ Ẹti jẹ opin ọsẹ ni Iran, wọn si maa n lo ọjọ Ẹti naa lati gbadun ara wọn.

Ṣọọbu ti wọn ti n ṣe irun ni yọyọ ni 1976: Awọran yii jẹ iru eyii ti eeyan ko le ri mọ bayii ni Iran, amọ eyii ko tumọ si pe ko si awọn aṣerun ni yọyọ mọ lorilẹ-ede naa.

Obinrin to n rin laarin igboro lọdun 1976: Bo tilẹ jẹ pe o lodi si ofin lati da obinrin duro laarin igboro ni Iran, irufẹ aworan yii, to n ṣafihan yẹti ati atike obinrin to sọwọn bayii lorilẹ-ede ọhun.

Ohun to ṣẹlẹ lẹyin iojijagbara ẹsin Islam

Awọn obinrin to n ṣe ifẹhonuhan lodi si ijaabu lọdun 1979: Lẹyin ti adari ijọba tuntun, Ayatollah Ruhollah Khomeini gori alefa tan lo kede pe gbogbo obinrin gbọdọ maa wọ ijaabu.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta ọdun naa lawọn ibinrin tu sita lati ṣe iwọde tako aṣẹ tuntun naa.

Awọn mọlẹbi to n lọ gbadura ni Mọṣalaṣi ni 1980: Ofin ẹsin Islam tuntun ko gba awọn obinrin ati ọkunrin lati joko papọ lasiko adura ninu Mọṣalaṣi.

Obinrin ko si gbọdọ jade lai si ọkọ rẹ tabi ọkunrin ti yoo daabo bo lẹgbẹ rẹ.

Awọn obinrin to n rin laarin igboro ni 2005: Kii ṣe gbogbo awọn obinrin Iran lo n wọ aṣọ ti yoo bo gbogbo ara wọn, amọ dandan ni ibori.

Ibori leti okun lọdun 2005: Ofin ko gba awọn obinrin Iran laaye lati wẹ leti okun pẹlu aṣọ to ṣi ara wọn silẹ.

Bẹẹ si ni ọkunrin ati obinrin ko gbọdọ wẹ ninu odo kan lasiko kan naa.

Iwọde fun atilẹyin ijaabu lọdun 2006: Lẹyin nnkan bii ọdun marundinlọgbọn ti Islam gbilẹ ni Iran, awọn obinrin ṣe iwọde ninu eyii ti wọn ti fẹsun kan ijọba pe kọ fi ẹsẹ ofin to kan ijaabu nipa mulẹ bo ṣe yẹ.

Awọn obinrin to n wo bọọlu lọdun 2008: Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni ki awọn obinrin ma wo bọọlu ni Iran, amọ ọpọ igba ni wọn ki n gba wọn laaye lati wọ inu papa iṣere lọna ati wo bọọlu ọhun.