Mọ nípa àwọn àǹfàní tó ń ṣara lóore nínú ata jíjẹ

    • Author, Jessica Brown
    • Role, BBC Future
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Jijẹ ata jẹ nnkan to ti wa lati ọjọ pipẹ koda a ko ro pe eeyan kan wa ti wọn ko ki n ata ni ijumọ kan.

Ọpọ nnkan ni awọn a ma fi ata kun koda a ma fi sinu nnkan mimu .

Laipẹ yii ni awọn ata kan ti di ounjẹ igbala

Turmeric, fun apẹẹrẹ, ni wọn ti n lo ni agbegbe Asia fun ọjọ pipẹ ti di nnkan ti wọn fi sinu kọfi kakiri agbaye, koda lasiko igbele Korona, ata jijẹ n gbe ogun ti kokoro naa.

Ṣugbọn n jẹ ata jijẹ n se saara loore , se n da bobo wa lọwọ asian, ati pe se o le se akoba fun wa?

Anfani jijẹ ata

Ọkan ninu ata to wọ pọ ni an n pe ata bawa. Ọpọ iwadii fihan pe ke ni awọn ipa lara wa.

Capsaicin ni eronja to wa ninu ata . Ti wọn aba jẹ Capsaicin ma mu ara yaa.

Awọn iwadii ni capsaicin ma fun ki ẹmi gun.

Ni ọdun 2019, iwadii itali ṣalaye pe eeyan to ba jẹ ata ni ẹmẹrin lọsẹ yoo ni ẹmi gungun ju eeyan ti ko jẹ rara.

Ni ọdun 2015, awọn oniwadii China ṣe iwadii lori jijẹ ata , ti wọn si ri pe ọpọ eeyan to n jẹ ata ni orekoore ni wọn ni ẹmi gungun.

Ẹwẹ jijẹ ata pupo le se akoba fun ilera, to si le ma da bobo eeyan lọwọ asian.

Ọjọgbọn QI ni aisan ko ri aye de si lara eeyan to ba n jẹ ata nitori eronja Capsaicin.

“Awọn eronja to wa ninu ounjẹ to ba ni ata bi capsaicin mu ayipada to dara de ba ara, eyi to ṣafihan ninu iwadii wa .”

Ọpọ iwadii tun ti se afihan pe eroja capsacin yii tun fun eeyan ni okun ati agbara, ti ko si ni jẹ ki ebi ma pa eeyan.

Zumin Shi, ọjọgbọn ni fasiti Qater ni ata jijẹ ko ki n jẹ ki eeyan sanra ju, to si dẹkun ifunpa .

Awọn kẹmika to wa ninu ata

Awọn kẹmika to wa ninu ata lo n fun ni adun, ti ko si lewu fun awọn eeyan, Duane Mellor, olukọ ni ile ẹkọ Aston Medical ni UK ṣalaye.

“Ọpọ awọn nnkan to wa ninu ounjẹ ti a n gbadun lo wa nibẹ lati da bobo awọn ohun ọgbin yii lọwọ awọn kokoro.”

O ni fun apẹẹrẹ- awọn eroja bi polyphenois to wa ninu ọpọ ohun ọgbin lo ni ipa to n ko.