You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oúnjẹ àràmọ̀ǹdà mọ́kànlá tí wọ́n ń jẹ lágbààyé
Ounjẹ jijẹ jẹ ọrẹ ara, amọ jijẹ idin ninu burẹdi jẹ ohun to so si ni lẹnu, to si bu iyọ si.
Bayii ni ọrọ ri fun awọn to n gbe agbeegbe Sardinia ni orilẹede Italy, ti wọn fi idin se ounjẹ ajẹpọnnula.
Koda, wọn yoo dupẹ lọwọ ẹnikẹni to ba fun wọn ni burẹdi onidin jẹ.
Eyi lo mu ki wọn pinnu lati se afihan ile ounjẹ ti ko wọpọ lawujọ si awọn gbagede kan, eleyii to bẹrẹ ni Malmo, lorilẹede Sweden ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kẹwa, ọdun 2018.
Sise afihan ounjẹ yii yoo fi agbara fun ero awọn eniyan wi pe, ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.
Ẹ wo oúnjẹ àràmàndà 11 tí wọ́n ń jẹ lágbààyé
Yoruba bọ wọn ni bayii lati n se ni ilẹ wa, eewọ ibomiran ni.
Eyi lo mu ki onimọ nipa ihuwasi ati ise ọmọniyan, Samuel West sọ wi pe, ounjẹ jijẹ jẹ ohun abalaye to n se afihan ihuwasi eniyan ati ibi ti eniyan ti ṣan wa.
Italy: Burẹdi ati iyẹfun ti wọn fi idin se
China: Obinrin lo n jẹ oko Maalu funfun, nigba ti Ọkunrin yoo jẹ dudu
Ni orilẹede China, wọn ma n jẹ oko akọ maluu.
Awọn onimọ ni ki Obinrin o jẹ funfun, nigbati Ọkunrin yoo jẹ dudu rẹ.
Uganda: Tata ti wọn yi ni ata ati ẹfọ
Tata ni ounjẹ awọn ara Uganda, eleyii ti wọn ti yii lata.
Wọn a ma jẹ ẹ pẹlu ọti waini.
Amọ eewọ ni fun awọn obinrin oloyun, ki wọn ma ba a bi ọmọ ti ọpọ́n ori rẹ yoo jọ ti tata.
Mexico: Ẹyin kokoro ti wọn ti din
Ounjẹ ati papanu ni ẹyin kokoro jẹ lorilẹede Mexico.
Wọn ma n din, ti wọn si ma n gbadun rẹ lọpọ igba.
Vietnam: Ọkan ejo Sebe pẹlu ẹjẹ rẹ ninu ọti waini
Ọkan ejo Sèbé ni awọn eniyan ma fi n se ounjẹ jẹ.
Wọn ni o ma n fi agbara kun agbara wọn.
Wọn si le e jẹ ọkan ejo naa pẹlu ẹjẹ ejo tabi ọti waini Vodka.
Ilẹ Gẹẹsi: Ẹjẹ ẹlẹdẹ sise
Ounjẹ aarọ to peleke ni ki eniyan o fi ẹjẹ ẹlẹdẹ ti wọn ti sè, kun ounjẹ to fẹ jẹ lojumọ.
Ounjẹ owurọ ko i tii pe ni Ilẹ Gẹẹsi ti ko ba si ẹjẹ ẹranko ti wọn ti se nibẹ.
Wọn ni o dara fun eroja asaraloore iron, zinc ati protein.
Peru: Omi ara Ọpọlọ
Omi ara ọpọlọ ti wọn ti rẹ ni awọn fi n se ara rindin, ti wọn si tun n ta a fun awọn eniyan gẹgẹbi omi ẹlẹrindodo to n mu araji pepe.
Ohun to wọpọ ni orilẹede Turkey ni lati fi igba aya ati ọmu akukọ se ounjẹ jijẹ.
China: Fifi Ekute ile se ọti waini ẹlẹrin dodo
Eleyii ya ni lẹnu pupọ ju.
Orilẹede China a ma a fi ekute ile se ọti waini ẹlẹrin dodo.
Amọ awọn ekute yii gbọdọ jẹ eyi ti wọn sẹsẹ bi, ti ko i ti pẹ ju nilẹ.
Wọn ni o ma n sisẹ fun aisan ikọfe e ati aisan jẹdọjẹdọ.
Japan: Fifi omi ara ẹja to n sere ibalopọ se ọbẹ
Ko buruju ti wọn ba fi omi ara ẹja to n sere ibalopọ se ọbẹ ti wọn yoo jẹ.
Moloka ni wọn n pe orukọ ounjẹ naa.
Orilẹede Japan naa a ma a jẹ ounjẹ yii.