Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ láàrin Verydarkman àti ẹbí Falana

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ giga kan ni Ikeja ti paṣẹ fun gbajumọ ori ayelujara nni, Martins Vincent Otse (VeryDarkMan) lati mu fidio ibanilorukọ jẹ to fi sori ayelujara nipa Amofin agba Femi Falana ati ọmọ rẹ, Fọlarin Falana, kuro.

Bakan naa ni kootu paṣẹ pe VDM, bi wọn tun ṣe maa n pe gbajumọ ori ayelujara yii, ko gbọdọ pin fidio ibanilorukọ jẹ ọhun kiri mọ.

Aṣẹ yii waye latari fidio kan ti VDM fi sori ayelujara nipa Amofin Femi Falana ati ọmọ rẹ, Folarin Falana.

Nibi to ti sọ pe awọn mejeeji fẹẹ da oju idajọ ododo bole nitori Idris Okuneye( Bobrisky), ọkunrin to n mura bii obinrin to si jẹjọ nipa fifi abuku kan naira.

Ninu fidio to jade lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an ọdun 2024 naa ni VDM ti sọ pe yoo jẹ nnkan iyanu foun bi Femi Falana ati Folarin ba lọwọ ninu ọrọ Bobrisky.

O ni Folarin,tawon eeyan mọ si ‘Falzthebadguy’, ba baba rẹ sọrọ nipa bi yoo ṣe ran Bobrisky lọwọ, ki wọn le da oju idajọ ododo bolẹ.

Adájọ́ pàṣẹ

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Mahmud Dawodu to n gbọ ẹjọ naa, paṣẹ pe ki VeryDarkMan mu fidio ibanilorukọjẹ ati ọrọ to kọ sibẹ nipa Femi ati Folarin kuro ni gbogbo oju opo ayelujara rẹ.

Kootu tun fun Amofin agba Femi Falana ni anfaani lati pese gbogbo iwe ipẹjọ lori olujẹjọ.

Ṣaaju ni VeryDarkMan ti sọ pe fọn-an-ran ohùn kan to n ṣalaye pe oun san miliọnu mẹẹẹdogun naira, koun ma baa ṣe ẹwọn tijọba paṣẹ, jẹ ti Bobrisky.

O ni Bobrisky sọ pe oun sanwo naa fun awọn alaṣẹ, ki wọn baa le fi oun si ile adagbe to tura, yatọ si ẹwọn oṣu mẹfa tijọba paṣẹ.

Ṣugbọn Bobrisky yari kanlẹ pe ohùn to lu sita naa ki i ṣe ti oun.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

Lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an ọdun yii, VDMju fọn-an-ran ohùn kan sita, nibi ti eeyan meji ti n sọrọ lorii foonu.

O ni Bobrisky ni ẹni to n ba ẹnikan sọrọ ninu fọn-an-ran naa, (eyi ti BBC ko le fidi rẹ mulẹ).

Ninu rẹ ni lo ti ni Bobrisky n sọ fun ẹnikeji pe oun san miliọnu mẹẹẹdogun naira (15m), fun oṣiṣẹ EFCC kan ti ko darukọ, ki oun ma baa ṣe ẹjọ lorii fifi abuku kan naira.

Ẹsun yii fa awuyewuye nigba naa lori awọn oṣiṣẹ EFCC ati ti ọgba ẹwọn, ti minisita fun ọrọ abele, Olubunmi Tunji-Ojo si da si i.

Oṣiṣẹ ọgba ẹwọn meji ti wọn jẹ ọga ni ajọ Nigerian Correctional Service, paṣẹ fun un lati lọọ jokoo nile na.

Bẹẹ ni ile igbimọ aṣoju ṣi n jiroro lorii awọn EFCC ati ti ọgba ẹwọn pẹlu.

Kí ló léwu nínú ọ̀rọ̀ yíí?

Gẹgẹ bi agbẹjọro kan, Jiti Ogunye, ṣe ṣalaye, o ni ọrọ to lewu pupọ ni eyi labẹ ofin, paapaa fun awọn eeyan to kan.

Lọọya Ogunye ṣalaye pe VeryDarkMan ki i ṣe ajọ abanigba-gbese.

O ni ta a lo fun un laṣẹ lati maa fi ọrọ tawọn eeyan ba sọ lori foonu ba wọn lorukọjẹ kiri, debi ti yoo mọ pe ẹnikan n san gbese abi abẹtẹlẹ.

O ni oun ro pe Bobrisky n tọrọ owo ninu fọn-an-ran naa ni, o si wa n parọ lati ri nnkan gba lọwọ ẹni ti wọn jọ n sọrọ.

O ni ṣugbọn VDM ko farabalẹ mọ ohun ti ọrọ yii jẹ, to fi bọ sori ayelujara.

Bẹẹ, ori ayelujara jẹ itakun kan ti iroyin ofege ti maa n waye pupọ.

Amofin Ogunye waa kilọ fun awọn ọmọ Naijiria, pe iwa ọdaran ni lati fi ọna ẹburu ka ohùn awọn eeyan to n sọrọ lorii foonu silẹ, tabi ki eeyan gbe lẹta abi fidio wọn sita lọna aitọ.

Ko si tun waa kọ ọrọ ti yoo mu wọn dabi ọbayejẹ si i pẹlu, o ni iwa to lodi labẹ ofin leyi, o si ni ijiya to tọ.