You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Humanitarian Ministry Fraud: A kò tíì wẹ ẹnikẹ́ni mọ́ nínú ìwádìí ẹ̀sùn ṣíṣe owó mọ́kumọ̀ku- EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, ijẹkujẹ ati ajẹbanu ni Naijiria, EFCC ti kede sita pe awọn ko ti wẹ ẹnikẹni ti wọn fẹsun kan pe o lọwọ siṣe owo ilu mọkumọku mọ ni ti ẹka ijọba fun eto iboju-aanu woni, paapa minisita ti wọn ni ko lọ rọọkun nile, Betty Edu.
Ninu oṣu kinni, ọdun 2024, Aarẹ Bola Tinubu palasẹ pe ki ajọ EFCC bẹrẹ si ni ma ṣe iwadii lori ẹsun naa ki wọn si ri pe wọn ṣawari awọn to lọwọ ninu siṣe owo ilu mọkumọku.
Bẹẹ ba gbagbe Ileeṣẹ Aarẹ Naijiria ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi wọn ṣe fi akoto owo aladani gba owo ₦585.189m to jẹ owo iranwọ to wa fun awọn enìyan kan ni ìpinlẹ Akwa Ibom, Cross River, Ogun ati Eko.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ajọ EFCC, Dele Oyewale fi lede fun awọn akọroyin lo ti ṣalaye sii.
O sọ pe ko ki n ṣe ẹnikan ni awọn n ṣe iwadii fun ẹsun siṣe owo to to ọgbọn bilọnu mọkumọku sugbọn gbogbo ọna ti owo gba lọ ati awọn iwa ibajẹ to wa ni ẹka ijọba naa ni awọn n ṣe iwadii le lori
Owo Covid 19, owo Banki Agbaye, owo Abacha wa lara owo ti ẹka yii lu ni ponpo
Agbẹnusọ EFCC tẹsiwaju pe iwadii awọn tun ṣawari awọn owo bi owo Covid-19, ẹyawo Banki agbaye ati owo Abacha ti ijọba fun ẹka ijọba fun eto iboju-aanu woni lati tan isẹ ati osi lawujọ, eyi ti ko tun ni alaye bi wọn ṣe na sita.
Oyewale ni gbogbo awọn osisẹ ijọba ni ẹka ijọba naa, paapa minisita tẹlẹ, Betta Edu ni awọn ti ransẹ pe wa si agọ EFCC lati wa wi tẹnu ati pe awọn ko ti wẹ ẹnikẹni mọ pe.
“Ajọ EFCC gbọ si iroyin to n ja kiri pe lori iwadii wa lori ẹsun siṣe owo ilu mọkumọku ni ẹka ijọba fun eto iboju-aanu woni.
“Ni ibẹẹrẹ iwadii, a ransẹ pe awọn osisẹ ijọba, eyi ti wọn ni ko rọọkun ati awọn ti wọn da duro lati wa wi tẹnmu wọn, ti iwadii naa si ti gba owo to le ni N32.7bn ati $445,000 pada.
“Iwadi wa tun ṣawari awọn owo mii ti wọn ṣe mọkumọku, to jẹ mọ, owo Covid 19, Owo banki agbaye, owo Abacha ti ijọba gbe fun ẹka naa lati ran awọn araalu lọwọ.