Àwọn dókítà ti ń káyà sókè torí ìlera Ọbabìnrin Elizabeth Keji

Ọbabinrin Elizabeth Keji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹ lọwọ ni yajo yajo ti fi ye wa pe Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Elizabeth keji ti wa labẹ itọju fun ilera rẹ.

Aafin Balmoral ni Ọbabinrin wa, to ti n gba itọju naa.

Gẹgẹ bi ikede kan to tẹ BBC lọwa lati aafin Burkingham, awọn dokita to n se itọju Ọbabinrin Elizabeth ti n paya lori ilera rẹ.

“Nitori ayẹwo ti wọn se fun Ọbabinrin ni aarọ yii, awọn dokita to n se itọju Ọbabinrin Elizabeth ti n paya lori ilera rẹ.

Awọn dokita naa si ti daba pe ko wa labẹ itọju to lagbara.

Amọ ara Ọbabinrin ko lelẹ ni Balmoral.”

Ọbabinrin Elizabeth ko le pari ipade ori ayelujara to n se lọwọ lọjọru

Wọn ti wa fi ipo ti ilera Ọbabinrin Elizabeth Keji wa, to awọn mọlẹbi rẹ leti.

Ikede yii lo waye lyin ti Ọbabinrin Elizabeth keji, tii se ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun yẹba kuro ninu ipade igbimọ kan to n waye lori ayelujara lọjọ Iọjọ ana.

Awọn dokita si lo gba niyanju lati lọ fun ara nisinmi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọkan mi ati ti awọn olugbe orilẹede UK wa pẹlu Ọbabinrin - Olootu ijọba

Olootu agba, Liz Truss ni iroyin ailera Ọbabinrin Elizabeth keji ti ko irẹwẹsi ọkan ba ọpọ eeyan nilẹ UK.

“Ọkan mi ati ti awọn olugbe orilẹede UK wa pẹlu Ọbabinrin ati awọn mọlẹbi lasiko yii.”

Ọbabinrin yan Ms Liz Truss, gẹgẹ bi olootu ijọba ni Balmoral lọjọ Iṣegun lẹyin ti ko le gbera lọ sibi ayẹyẹ naa niluu London.