You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin kan dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó gùn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́bẹ pa nítorí gbèsè
Ileẹjọ giga nipinlẹ Eko to n joko ni Ikeja ti ni ki Bitrus Wurawa lọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn lẹyin to sekupa ọrẹ rẹ, Ezekiel Yohana, ẹni to gun lọbẹ pa ninu ọja Kara ni Ibeju Lekki nipinlẹ Eko.
Afurasi ọhun lo foju ba ileẹjọ lọjọ kẹwaa oṣu kẹrin niwaju Onidajọ P.E Nwaka lori ẹsun ipaniyan.
Yahana, ẹni ọdun mẹtalelogun ni o ya owo toto ẹgbẹrun mẹrinla lọwọ Wurawa ninu oṣu kinni, to si se ileri lati da owo naa pada laarin ọsẹ diẹ.
Lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ, Yahana ko ri owo naa san pada, eyi to fa ede ayede laarin oun ati Wurawa.
Ni bi ti awọn mejeeji ti n fa ọrọ naa, ni Yahana ti fa ọbẹ bọ sita, ti Wurawa si lọ mọ lọwọ, to si fi gun ẹyin ati ọwọ.
Agbẹjọro Olupẹjọ wa rọ ileẹjọ pe ki wọn fi Wurawa si ahamọ titi asiko ti idajọ yoo waye lori isẹlẹ naa.
Onidajọ Nwaka ti wa sun igbẹjọ naa siwaji di Ọjọ Karun, ọsu Karun, ọdun 2023.
Ọmọge mẹ́rin lọ patí ọjọ́ ìbí ní Ile-Ife, afurasí afinisòwòẹrú fi òògùn orun sínú ọtí wọn láti gbé wọn lọ ṣẹrú ní Libya
Ọwọ ti tẹ afurasi afiniṣowo ẹru kan, Adebisi Muideen to fẹ fi ọdọbinrin mẹta ṣe owo ẹru lati ipinlẹ Osun lọ si Libya.
Muideen ni ọwọ tẹ ni Kano lẹyin ti o fi oogun orun si ounjẹ awọn ọdọbinrin naa ni ile ifẹ, ti wọn si ji ba ara wọn ni ilu Kano.
Awọn ọdọbinrin naa, to ba ara wọn ni Kano ni wọn sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si pe awọn obi wọn lati ibẹ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fi lede, lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ree...
Awọn obinrin mẹta ti wọn jajabọ pe obi wọn amọ wọn ko i tii ri ẹni kẹrin wọn
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ni afurasi naa lo fi iwe pe awọn ọdọbinrin naa si ibi ayẹyẹ ọjọ ibi ni ile itura kan ni Ile-Ife, to si fun wọn ni ounjẹ ati omi.
Kete ti awọn ọmọ naa jẹ ounjẹ ati omi naa tan, ni wọn sun lọ fọnfọn.
Jiji ti wọn yoo ji ni wọn ba ara wọn ni agbegbe kan ni ilu Kano, nibi ti wọn ti n ṣe iwe bi wọn yoo ṣe mu wọn rin irinajo lọ si Libya.
Ọlọpaa ni lẹyin ti awọn ọdọbinrin ti wọn jigbe naa ji si ara, ni wọn fi ẹṣẹ fẹ, ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn mẹta ti wọn jajaye naa, ni wọn pe obi wọn amọ wọn ko i tii ri ẹni ikẹrin wọn titi di akoko yii.
‘’Awọn obi awọn mẹtẹẹta to moribọ ni wọn kan si ọlọpaa, ti iwadii si bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Nibayii, awọn ọmọge mẹtẹẹta naa ti pada si ọdọ obi wọn.
Ohun ti afurasi afiniṣowo ẹru ṣọ niyii
Ọpọ obinrin ti wn gbe lọ si Libya ni mo ba ninu ile afinisowoẹru ni Kano - Afurasi
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Muideen Adebisi ko jẹwọ delẹ delẹ, wọn ni ohun to n sọ ni pe awọn ọdọbinrin naa faramọ lati lọ si Libya lati lọ ṣe owo ẹru.
Bakan naa ni o ni ibatan oun ọkunrin to wa ni Tripooli ni Liya, lo paṣẹ pe ki oun wa awọn obinrin naa.
O ni o sọ pe ki oun si mu wọn lọ si ile ọkunrin kan ni Kano, ti yoo gbe wọn lọ si Libya.
Ọlọpaa ni Adebisi fikun un pe iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun de ile arakunrin naa ni Kano, ti oun si ba ọpọlọpọ ọdọbinrin nibẹ ti wọn fẹ mu lọ si Libya.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn yoo ṣe iwadii iṣelẹ naa lẹkunrẹrẹ, ti awọn yoo si gbe afurasi naa lọ si ileẹjọ.