You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde orúkọ àti ojú ọlọ́pàá mẹ́ta tó fi pankẹ́rẹ́ na aráàlú, fi tipá ti obìnrin
Awọn osisẹ ọlọpa mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe wọn yọ pankẹrẹ ti araalu loju popo nilu Portharcourt, nipinlẹ Rivers, ti han sita.
Atẹjade ti alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, Olumuyiwa Adejobi fisita lo sisọ loju awọn afurasi oniwa ibajẹ ọlọpaa naa.
Bẹẹ ba gbagbe, fidio kan lo gba ori ayelujara kan lọjọ Aje, nibi ti osisẹ ọlọpaa kan ti n ko pankẹrẹ ti ọkunrin kan to da mọto rẹ duro.
Bakan naa ni osisẹ ọlọpaa ọhun tun yan ọkunrin naa ni igbanu lasiko ti onitọun n fesi sọrọ to sọ.
Ko tan sibẹ o, osisẹ ọlọpaa mii to wa nibi isẹlẹ naa, tun sun mọ aya ọkunrin ti wọn n na naa, to gbe ikoko lọwọ, lati ti i wọnu ọkọ ayọkẹlẹ wọn pẹlu ipa.
Nibayii, Adejobi ti wa fi aworan awọn ọlọpaa naa han loju opo Twitter rẹ.
Bakan naa, Adejobi tun kede orukọ awọn ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe wọn naa araalu ọhun.
Orukọ awọn afurasi ọlọpaa naa ni Insipẹkitọ Adejoh Siaka, Insipẹkitọ Friday Obaka ati Sajẹnti Ndiwa Kpuebari.
Adejobi ni awọn ọlọpaa naa lo wa si olu ileesẹ ọlọpaa milu Abuja lati wa jẹ ipe ọga agba ọlọpaa to ransẹ pe wọn.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa naa wa kede pe igbẹjọ wọn yoo bẹrẹ laipẹ, ti oun yoo si maa bun araalu gbọ, bi igbẹjọ naa ba se n waye.
Ọlọ́pàá fí kùmọ̀ lú ọkúnrín tó dá dúró lójú pópó, ariwo sọ
Fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ti ṣafihan bi ọlọpaa ṣe fi iya jẹ araalu ni ilu Port Harcourt, tii se olu ilu ipinlẹ Rivers.
Fidio naa lo ṣafihan ọlọpaa naa to mu kumọ dan,i to si fi n lu ọkunrin ọhun ti iyẹn si n sun si ẹyin fun.
Ninu fidio naa ni ọkunrin naa ti n pariwo pe ki lo de ti ọlọpaa fi n fi iya jẹ oun, ti ọlọpaa keji si n woran pẹlu bi ọkunrin naa ṣe n beere pe ṣe oun jale ni.
Aimoye igba ni awọn araalu ti fi aidunnu wọn han si bi awọn ọlọpaa ni Naijiria ṣe n fi iya jẹ awọn araalu.
‘’Se mo jale ni, ma na mi’’ - Araalu beere lọwọ ọlọpaa to n fi kumọ naa
Awọn ibeere ti ọ̀kunrin ti wọn na naa n beere niyẹn ti o si n sunmọ kuro ni ọdọ ọlọpaa naa, amọ to si n tẹlẹ.
Ọkan lara awọn ọlọpaa to gbe ibọn dani naa lo gbe kumọ rẹ soke to fi n na ọkunrin ọhun.
Bio tilẹ jẹpe ko si ẹni to tii mọ ọkunrin naa, amọ nise lo n sọ wi pe ọlọpaa ma na mi, ṣe mo jale ni? ṣe mo jale ni?
Amọ obinrin to wa pẹlu ọkunrin naa ni wọn fipa mu lọ si inu mọtọ, to si n pe ọkunrin naa ki o maa bọ.
Bẹẹ si ọlọpaa naa ko jawọ nina ọkunrin naa, to si n fọ eti rẹ, to si n sọ fun pe ko maa lọ, to si n naa, pe ko maa lọ.
Titi di askio yii ko i tii han si gbangba idi ti ọlọpaa fi da awọn mejeeji duro ninu ọkọ wọn.
Awọn araalu to fi aidunnu wọn han lori ẹrọ ayelujara tabuku ọhun ti ọlọpaa na sẹ, ti wọn si kesi ijọba lati fi iya to tọ jẹ awọn ọlọpaa to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Ẹ fi panpẹ mu awọn ọlọpaa to lu araalu ninu fidio – Ileeṣẹ ọlọpaa paṣẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers ti paṣẹ pe ki wọn fi panpẹ ọba mu awọn ọlọpaa meji to fi iya jẹ araalu ninu fidio.
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Rivers, CP Okon Effiong lo fi aṣẹ naa lede ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa fi lede.
Effiong ni awọn ti ri awọn ọlọpaa naa to ṣe aṣemaṣe ọhun amọ wọn ko darukọ wọn.
Ninu ọrọ rẹ, o bu ẹnu atẹ lu ohun ti awọn ọlọpaa naa ṣe pe ko bojumu, ti awọn yoo si ṣewadi iṣẹlẹ naa lati fi otitọ ọrọ mulẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa fi da awọn araalu loju pe awọn yoo fi ofin mulẹ ni ipinlẹ naa, ti awọn ko si ni gba iwa ibajẹ laaye.
Nibayii, wọn ti kesi arakunrin to wa ninu fidio naa lati yọju si wọn, ti wọn si rọ awọn araalu lati tubọ maa fi awọn iwa aitọ han fun ileeṣẹ ọlọpaa,ki wọn le dẹkun wọn.
Ọwọ ti tẹ awọn ọlọpaa to na araalu loju popo - Ileesẹ ọlọpaa
Wayii o, ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa ti kede pe ọwọ oun ti tẹ awọn ọlọpaa to lu araalu loju popo nilu Portharcourt.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi lo sisọ loju ọrọ yii ninu ikede to fi sita loju opo Twitter rẹ.
Adejobi ni wọn n gbe awọn ọlọpaa naa wa si olu ileesẹ ọlọpaa to wa nilu Abuja lọjọ Isẹgun.
Bakan naa lo salaye pe ọlọpaa mẹta ni awọn afurasi naa, wọn kii se meji.
O fikun pe ihuwasi awọn ọlọpaa naa ko safihan ileesẹ ọlọpaa lọna to bojumu.