Aráàlù lu afurasí afipábánilòpọ̀ pa bó ṣe ti obìnrin mọ́ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ n‘Ìbadan

Awọn ara adugbo ti pa ọkunrin ti wọn fẹsun kan pe o ma n fi ipa ba awọn obinrin lopọ lẹyin to ba ja wọn lole ni agbegbe Adagbada/Arola ni Apete, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Iwe iroyin Tribune ni afurasi to n fipa ba awọn obinrin lopọ naa, lo ṣekọlu si ile kan ni agbegbe naa ni aago mẹrin owurọ, to si gba ẹrọ ilewọ ati owo wọn.

Wọn ni gẹgẹ bi o ṣe ma n ṣe, n ṣe lo ti ọkan ninu awọn obinrin naa sinu ile igbọnṣẹ, to si ni ki ikeji sun si ilẹ ki oun le fipa ba lopọ.

Amọ wọn ni obinrin to ti mọnu ile igbọnṣẹ naa, tu ara rẹ silẹ, to si salọ lati ke pe awọn ara adugbo.

Ọpọ ero lo pejọ lati wo oku afurasi naa nibi to wa ni ilẹ nlẹ, ti wọn si n fo fun ayọ

Iwe iroyin naa ni kia ni awọn ara adugbo pe jọ, ti wọn si bẹrẹ si ni le afurasi naa lẹyin to gbiyanju lati salọ.

Wọn ni ọpọlọpọ ero lo darapọ mọ awọn adugbo, ti wọn si mu afurasi naa lasiko to fẹ salọ.

Wọn ni ọkunrin naa ju awọn foonu to gba si ẹyin ogiri ile naa, ti ọlọpaa si mu lẹyin iṣẹlẹ naa.

Wẹrẹ ti ọwọ awọn ara adugbo tẹ ni wọn bẹrẹ si ni naa, titi ẹmi fi pọ ni ara rẹ.

Ọpọlọpọ ero lo si pejọ lati wo oku rẹ nibi to wa ni ilẹ nlẹ, ti wọn si ni wọn fo fun ayọ.

Awọn ara adugbo ni afurasi naa fipa ba ọmọge ti ko mọ ọkunrin ri lopọ lọsẹ mẹta sẹyin

Lara awọn to sọ iriri wọn fun iwe iroyin Tribune, salaye pe awọn n gbe ile pẹlu ifoya ni lati igba ti ole yii ti bẹrẹ si ni ja, to si n fi ipa ba awọn eniyan lọpọ.

O ma n fi ada halẹ mo awọn ti o ba de ni alejo, ti yoo si ṣe bi ẹni pe awọn ekeji rẹ wa ni ita pẹlu ibọn ti wọn ba gbiyanju lati pariwo.

Ọṣẹ mẹta ṣẹyin ni wọn ni afurasi naa fi ipa ba obinrin ti ko mọ ọkunrin ri nibi ti afẹṣọna rẹ wa.

Wọn ni niṣe lo ti afẹsọna obinrin naa mọ ile , to si fi ipa ba lopọ.

Wọn fikun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ti lọ gbe oku rẹ ni agbegbe naa, ti wọn si gbe lọ si mọsuari.

Titi di asiko yii gbogbo igbiyanju wa lati gbọ ọrọ lati ẹnu agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ lo jasi pabo nitori o kọ lati gbe ẹrọ ilewọ rẹ.

Iná sẹ́yọ ni gbàgede ìgbéyàwó, ẹni orí yọ, ó di ilé ni àwọn àlejò fi ṣe

Igbayawo kan lo ti forisanpọn nipinlẹ Eko lẹyin ti ina saa dede sẹyọ lasiko ti ajọyọ naa n lọ lọwọ

Ninu fọnran kanto wa lori ayelujara, ọpọ awọn alejo ni wọn saa kijo fun ẹmi ara wọn lẹyin ti ina gba ode mọ wọn lọwọ, ti awọn miiran si n gbinyanju lati pa ina ọhun.

Isẹlẹ naa lo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹrin, ọdun 2023 ni Gbagede Yard 158 ni agbegbe Oregun nipinlẹ Eko

Ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ti bu ẹnu atẹlu gbogbo osise to mojuto gbagede igbeyawo naa.

Asiko ti tọkọtaya fẹ ma mu ọti ebo ni ina sẹyọ, to si da nnkan ru fun wọn.

A ko ti le sọ boya ẹnikẹni farapa lasiko ti ijamba ina naa waye .

Ki ni awọn eeyan sọ lori isẹlẹ naa lori Ayelujara

Ọpọ awọn eeyan lo ti bu ẹnu atẹlu isẹlẹ naa ti wọn si gba awọn tọkọtaya naa ni iyanju lati ma se ni erongba buburu si isẹlẹ ijamba naa.

@delasotv1 ni “Awọn eeyan dudu ko ni igbagbọ isẹlẹ yii ko ni ọwọ aye ninu nitori asise awọn eeyan kan sugbọn wọn ki gbagbọ, afi ki wọn na ika si awọn ana wọn pe awọn lo fa isẹlẹ

@danieludehdante ni : "Ẹni to se agbatẹru gbagede yii lo fa bi ina se sẹyọ. Ohun to baninu jẹ ni isẹlẹ yii sugbọn koko ni pe wọn ti se igbeyawo.

@nonnistics_ ni: "Koko nipe ẹnikẹni ko ba isẹlẹ naa lọ, o yẹ ki tọkọtaya ma dun ni."