Koko ni ara mi le, mo ṣetán láti sìn Nàíjíríà - Bola Tinubu

N kò kú tàbí sàìsàn, bẹ́ẹ̀ ni mò ń díje fún ipoò ààrẹ - Tinubu

Owe Yoruba kan lo ni ẹnu ara ẹni la fi n kọ mejẹ, ẹnu ara ẹni naa si la fi n pe Temidire.

Idi ree ti oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu se n pariwo sita pe oun ko tii yọwọ kuro ninu idije sipo aarẹ naa.

Tinubu, ẹni to fi fidio kan sita nibi to ti n wa kẹkẹ ere idaraya loju opo ayelujara rẹ nirọlẹ ọjọ Aiku lo pariwo bẹẹ.

Tinubu wa sẹ lori ahesọ ọrọ tawọn eeyan kan n sọ kiri pe o ti ku tabi pe o lọ gba itọju loke okun ni tabi pe ko nifẹ lati dije fun ipo aarẹ mọ.

Mo lokun daadaa, mo si setan lati sisẹ sin yin"

Loju opo Twitter ati Facebook rẹ naa ni Asiwaju ti salaye pe “Ọpọ eeyan lo ni mo ti papoda, ọpọ ni n ko dije sipo aarẹ mọ.

Rara o... ko ri bẹẹ.

“Ohun to n sẹlẹ gan ree: Mo lokun ati agbara daadaa, ti mo si ti setan lati sisẹ sin Naijiria lati ibẹrẹ pẹpẹ.” Oselu APC naa.

Eyi si ri bẹẹ nitori pe ko ba awọn oludije sipo aarẹ yoku peju sibi eto ti ajọ eleto idibo se pe ki wọn wa fi ọwọ siwe adehun lati gba alaafia laaye lasiko ipolongo ati idibo.

Ọjọbọ to kọja si ni eto naa waye amọ ti Asiwaju Bola Tinubu ko ba wọn peju sib.

Sugbọn dipo ko yọju, igbakeji rẹ, Kashim Shettima lo soju rẹ lati tọwọ bọ iwe adehun naa.

Atiku, Obi, Shettima t’ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn àlàáfíà fún ìbò 2023

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn oludije fun ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023 lorilẹede Naijiria ti tọwọ bọ iwe adehun alaafia, pẹlu ileri ati rii daju pe eto ipolongo ibo wọn ko mu wahala tabi rogbodiyan dani rara.

Bakan naa ni wọn tun fohun ṣọkan lati tẹle ilakalẹ ofin idibo ni Naijiria ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa ki eto gbogbo lee lọ nirọwọrọsẹ.

Ninu ọrọ to sọ ranṣẹ sibi ayẹyẹ naa ninu akasilẹ fọnran fidio kan, nibi ayẹyẹ naa, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari rọ awọn oludije lati rii pe ọrọ nipa koko ohun ti wọn fẹ gbe ṣe ni wọn n gbe leke lasiko ipolongo wọn dipo ikọlu, ọrọ alufansa ati ọrọ aitọ to lee da wahala silẹ.

Aarẹ Buhari tun rọ wọn lati yago fun iroyin ofege lasiko ti wọn ba n polongo ibo wọn.

 Aarẹ Buhari ko dije ni ibo to n bọ nitori saa keji ti ofin fi aye rẹ silẹ lo n lo lọ lọwọ.

Olori ijoba ologun lorilẹede Naijiria nigba kan ri, Ọgagunfẹyinti Abdusalami Abubakar lo gbe ero naa kalẹ pẹlu atilẹyin awọn aṣiwaju ẹsin ni Naijiria bii Biṣọbu agba ijọ aguda lẹkun Sokoto, Mathew Hassan Kukah ati Olori ẹsin Musulumi ni Naijiria, , Sultan Sa’ad Abubakar kẹta tilu Sokoto

 Ọgagunfẹyinti Abdusalami ni awọn oloṣelu gbọdọ ni oye pe “idibo kii ṣe ogun jija”, nitoei naa ki wọn yago fun awọn ọrọ to le fa yanpọnyanrin.

Lara awọn Oludije to wa nibẹ ni Atiku Abubakar ti PDP, Peter Obi ti Labour, Rabiu Kwankwaso ti NNPP.

Kashim Shettima to jẹ Igbakeji oludije ti APC, lo soju fun Bola Tinubu.

L’Ọjọru ni ipolongo ibo bẹrẹ lorilẹede Naijiria fun eto idibo apapọ tiyoo waye loṣu keji ọdun 2023.

Lọdun 2015 ni eto yii bẹrẹ nitori iriri awọn wahala to waye lẹyin idibo lorilẹede Naijiria lọdun 2011 eyi to gbẹmi ọgọrọ eeyan lọdun naa.