Ìjọba ti ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti n ta 'omi ayẹta ìbọn' fun àwọn olùjọ́sìn ní Kogi

Ijọba ipinlẹ Kogi ti ti ile ijọsin kan pa fun ẹsun pe alufaa ijọ naa n ta omi ayẹta fun awọn ọmọ ijọ.

Ọjọ Aje ni wọn gbe ilẹkun ile ijọsin naa, New Jerusalem Deliverance Ministry lẹyin ti Gomina Yahaya Bello paṣẹ rẹ

Pasitọ ijọ naa, Peter Adeiza tun ṣi ileewosan lai gba aṣẹ lọwọ ijọba lati ọdun 2008.

Igbagbọ wa pe ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nitori ilana ti wọn n gba ṣe itọju wọn.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe, yatọ si pe wọn n ṣe itọju aisan, ati igbẹbi alaboyun nibẹ, wọn tun n lo ṣọọṣi naa fun itọju aarun ọpọlọ, ti wọn si so ọpọ wọn pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ.

Ijọba sọ pe Alufaa Adeiza n lu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti nipa ti ta omi kan fun wọn, ‘ti ko ni i jẹ ki ọta ibọn ko ran wọn’.

Awọn ọmọ ijọ naa kan sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni baba wọn ninu Oluwa ọhun n fun awọn ni iwosan lori oriṣiriṣi aisan ati aarun.

Oludamọran lori aabo fun ijọba ipinlẹ Kogi, Jerry Omodara, sọ pe awọn ọlọpaa ati DSS ti kọkọ mu pasitọ naa nigba kan, lati tọpinpin nkan to n ṣẹlẹ ninu ṣọọṣi naa.

Omodara sọ pe awọn ni ẹri to to lati fihan nile ẹjọ pe iṣeṣi pasitọ naa tako ilana ẹsin ati iṣegun oyinbo.

O ṣalaye pe laipẹ ni wọn o gbe e lọ sile ẹjọ.