You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP gbọn Dotun Babayemi yọ nínú ẹgbẹ́ bí jìga
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun ní àwọn ti lé Dotun Babayemi kúrò nínú ẹgbẹ́ náà.
Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dájọ́ pé Ademola Adeleke ni ojúlówó olùdíje sípò gómìnà ẹgbẹ́ náà níbi ètò ìdìbò abẹ́nú tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje.
Dotun Babayemi ló ti ṣaájú gba ilé ẹjọ́ lọ wí pé kí ilé ẹjọ́ wọ́gilé ètò ìdìbò abẹ́nú tó gbé Ademola Adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bí olùdíje PDP kí wọ́n sì kéde òun bíi ẹni tó gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.
Àtẹ̀jáde kan tí adelé alága PDP Osun, Adekunle Akindele fi síta lọ́jọ́bọ̀ ní Dotun Babayemi kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ àwọn mọ́ fún ìgbésẹ̀ tó gbé náà.
Akindele ní Babayemi kò lẹ́tọ̀ọ́ kankan mọ́ báyìí láti dá sí ọ̀rọ̀ tó bá jẹmọ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Bákan náà ló kan sáárá sí ilé ẹjọ́ fún ìdájọ́ náà wí pé àwọn ti ń ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdájọ́ ilé ẹjọ́.
Ó ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Dotun Babayemi ni àwọn yóò tún fẹ̀sùn kàn wí pé ó ń ṣekuṣẹyẹ pẹ̀lú ẹgbẹ́ tí yóò sì kojú ìjìyà tó péye.
À ti pé gbogbo àwọn tó bá ń ṣojú méjì nínú ẹgbẹ́ ni àwọn yóò gbọ̀n dànù ni àwọn máa gbọ̀n dánú láì wẹ̀yìn wò.
Adeleke mókè nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ, òun ni ojúlówó olùdíje PDP
Ẹ ó rantí pé a mú ìròyìn wá fún-un yín ní àná wí pé Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gómínà tí wọ́n dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ni ojúlówó olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.
Nínú ìdájọ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún tí ilé ẹjọ́ náà gbé kalẹ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní ẹjọ́ tí Dotun Babayemi pè wí pé òun ni ojúlówó olùdíje tí ẹgbẹ́ PDP yàn níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Wọ́n ní ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ilé ẹjọ́ là kalẹ̀ kí ẹni tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní láti fi gbé ẹjọ́ wọn wá sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ti kọjá kí Dotun Babayemi tó gbé ẹjọ́ rẹ̀ wá.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbẹ́jọ́ Adeleke àti Oyetola rèé...
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Osun ti sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹwàá.
Èyí wáyé láti fún àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC, gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Ademola Adeleke àti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP láti ṣara jọ lórí ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún.
Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ lónìí, ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹsàn-án, Agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayode Olatoke ní àwọn ti ṣetán tí àwọn sì ti wà ní digbí fún ìgbẹ́jọ́ náà.
Olatoke ní àwọn ti buwọ́lu fọ́ọ̀mù TF008 láti tẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ náà.
Àmọ́ Agbẹjọ́rò àjọ INEC, Ben Ananaba ní òun kò ì tíì lè tẹ̀síwájú lórí ìgbẹ́jọ́ náà nítorí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìwé ìpẹ̀jọ́ ránṣẹ́ sí òun ní òwúrọ̀ òní ni.
Ananaba ní òun ṣì ní ọjọ́ méje láti fi fèsì sí ìpẹ̀jọ́ náà nítorí náà kí ilé ẹjọ́ fún òun láyè si.
Bákan náà ni Agbẹjọ́rò Adeleke, Bamidele Abolarin àti Agbẹjórò PDP, Nathaniel Oke náà bèèrè fún ìsúnsíwájú ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún.
Wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ fún àwọn ní ọjọ́ méje láti fèsì sí àwọn ẹ̀sùn náà àti láti gbáradì.
Nígbà tó ń gbé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ kalẹ̀, alága ìgbìmọ̀ náà, Adájọ́ Tertsea Kume wá sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹwàá.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olatoke ní ìgbésẹ̀ tí adájọ́ náà gbé kìí ṣe ohun tó burú nítorí àwọn tó yẹ kí wọ́n jẹ́jọ́ ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí ìwé ìpẹ̀jọ́ gbà ni.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ní Ademola Adeleke gbà pé àlékún ìbò wà nínú èsì ìbò gómìnà Osun?
Onírúurú awuyewuye ló ń jẹ jáde lẹ́yìn ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun níbi tí Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti jáwé olúborí.
Lára ohun tó wáyé lẹ́yìn ìdìbò náà ni pé gómìnà tó wà lórí ipò Gboyega Oyetola, tó tún jẹ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ èsì ìdìbò náà.
Lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Gómìnà Oyetola wọ Sẹ́nétọ̀ Adeleke àti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò lórí èsì ìdìbò náà.
Se lootọ ni Adeleke gba pe ibo waye ju bo se yẹ lọ ni agọ idibo 750?
Lára àwọn ẹ̀sùn tí gómìnà Oyetola fi kàn ni wí pé ìbò dídì wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò 750 ju iye ìdìbò tó yẹ kó wáyé láti ibẹ̀ lọ.
Ẹ̀wẹ̀, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ìròyìn tún gba ìgboro pé gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn náà, Sẹ́nétọ̀ Adeleke náà fọwọ́ si pé àlékún ìbò wáyé ní àwọn ibùdó náà.
Èyí ló mú BBC News Yorùbá kàn sí gómìnà tuntun náà láti gbọ́ látẹnu rẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an.
Gómìnà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti wá sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn pé àwọn àlékún ìdìbò wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò kan ju bó ṣe yẹ lọ.
Adeleke ní dípò ibùdó 750 tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Gómìnà Gboyega Oyetola ń gbé kiri pé àwọn èsì ìbò tó wáyé níbẹ̀ pọ̀ ju iye tó yẹ kó jẹ́ lọ.
Ó ní ibùdó mẹ́fà ni irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé.
Àgọ́ ìbò mẹ́fà ni àlékún ìbò ti wáyé, kìí ṣe 750 - Ademola Adeleke
Agbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ìròyìn náà ló mú kí àwọn gbé àtẹ̀jáde kan síta lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022.
O ni atẹjade naa lo wa láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ pátá gbáà ni ìròyìn náà.
Rasheed ní lóòótọ́ ni àwọn ṣe àyẹ̀wọ̀ àwọn èsì ìbò tí àwọn ènìyàn dì lẹ́yìn tí gómìnà Oyetola àti APC gbé àwọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Ó ní ohun tí àwọn ṣàwárí ni pé dípò ibùdó ìdìbò 750 tí APC ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ti wáyé, ibùdó ìdìbò mẹ́fà ni àwọn àlékún náà ti wáyé.
Ó fi kun pé àwọn ẹ̀rí wà tó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ pátápátá ní gbogbo ohun tí Oyetola ń sọ, tí ó sì hàn sílé ẹjọ́ pé Sẹ́nétọ̀ Adeleke fìdí Oyetola janlẹ̀ níbi ètò ìdìbò náà.
‘Alekun ibo ni agọ idibo mẹfa ko to 2000, ko si le se akoba fun esi ibo Adeleke’
Rasheed sọ pé àwọn ìwé ẹ̀rí akọsilẹ esi ibo tí kò pé ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC kó síwájú ilé ẹjọ́.
O ni èyí tó lòdì sí ohun tó wà nínú ẹ̀rọ BVAS àti fọ́ọ̀mù EC8A tó jẹ́ ojúlówó àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n lò lásìkò ìdìbò náà.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn gbà wí pé lóòótọ́ ni àwọn èsì ìbò kan pọ̀ju iye ènìyàn tó yẹ kó lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní àwọn ibùdó ìdìbò mẹ́fà.
Àmọ́ ó ní kìí se ibùdó 750 ni irú rẹ̀ tí wáyé gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí Oyetola àti APC ń gbé kiri.
Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àṣìṣe ẹ̀rọ BVAS ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ìbò ibùdó náà kò le ṣàkóbá fún èsì ìdìbò Adeleke tí wọ́n bá yọ ọ́ kúrò nínú èsì ìbò tó gbé Adeleke wọlé.
Bákan náà lo ní kò yẹ kí Gómìnà Oyetola àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC máa lọ sọ̀rọ̀ sórí ayélujára àti àwọn iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ìdìbò náà lẹ́yìn tí ẹjọ́ ti wà nílé ẹjọ́.
Ó wá rọ̀ wọ́n láti gba ilé ẹjọ́ láyè láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tó àti bó ṣe yẹ.