'Ikú yá ju ẹ̀sín lọ ni mo ṣe dáná sun ara mi'

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù Kẹsàn-án ni ìròyìn ọkùnrin kan tó fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ gba ìgboro.

Orúkọ ọkùnrin náà Muritala Afolabi tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún.

Ìròyìn ní ọkùnrin náà ṣàdédé gbé epo bẹntiróòlù tó sì dáà sí gbogbo ara rẹ̀ kó tó ṣáná si ara rẹ̀.

Èyí ló mú kí BBC News Yorùbá kàn sí ọkùnrin náà ní ilé ìwòsàn tó wà ní ìlú Iree ní ìpínlẹ̀ Osun láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan múlẹ̀.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó mu ṣe ìpinu láti pa ara rẹ̀, Afolabi ní nígbà tí òun jókòó tí òun ro ìgbésí ayé òun ló mú kí òun pinnu pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ.

Tí kò bá ti si ọjà báyìí ni gbogbo nǹkan máa ń sú mi

Afolabi tó ní iṣẹ́ àwọn tó máa ń fẹ́ táyà ni òun ń ṣe ṣàlàyé tí òun bá ti wà ní ṣọ́ọ̀bù tí alájé kò sì wá ni ìrònú òun máa ń pọ̀ si tó sì máa ń fa èròkerò sí òun lọ́kàn.

Ó ní ìdí nìyí tí òun fi lọ ra epo bẹntiróòlù tí òun sì lọ sí inú igbó kan láti lọ dáná sun ara òun.

“Fúnra mi náà ni mo lọ ra epo ní ilé epo, kìí ṣe àárín ìgboro ni mo ti ṣe é, inú igbó kan báyìí ni mo lọ.”

“Mo wá da epo náà sára, tí mo sì ṣáná si.”

Afolabi ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn tó rí òun níbi tí òun ti ń jóná ni wọ́n sáré dìgbàdìgbà láti dóòlà ẹ̀mí òun.

Ó ní àwọn ènìyàn náà ló sáré pa iná náà kí wọ́n tó gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn.

Mi o jẹ ènìyàn lówó ìyàwò ti mo ní ni ìṣòro ayé mi

Afolabi ní kìí ṣe wí pé òun jẹ ènìyàn lówó tàbí wà nínú okùn gbèsè kan, ó ní ìyàwó tí Ọlọ́run jogún fún òun ni àgbélèbú tó ń da ìgbésí ayé òun láàmú.

Ó ní èpè ni ìyàwó òun máa ń gbé òun ṣẹ́ ní ojoojúmọ́.

Ó ṣàlàyé pé ní kété ti àwọn bá ti jí ní òwùrọ́ báyìí ni ìyàwó òun yóò ti gbégbá èpè bọnu tí kò sì ní fi ọ̀kan pe méjì fún òun.

“Tí mo bá ki káàárọ̀ báyìí, èpè ló ma fi dámi lóhùn.”

“Nínú oṣù Keje náà ni a fẹ́ ara wa àmọ́ èpè ló fi ń bámi gbé láti ìgbà tó ti kó wọlé mi kódà a ò tíì bímọ kankan.”

“Tí mo bá sọ̀rọ̀ ẹyọ̀kan, èpè mẹ́wàá ló ma fi dámi lóhùn, ó sì ti mọ lára.”

Afolabi tẹ̀síwájú pé nítorí èpè tí ìyàwó máa ń gbé òun ṣẹ́ ló ṣokùnfà tí òun kìí fí sunlé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.

Bákan náà ló ní òun ti lọ fi sun àwọn mọ̀lẹ́bí ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀ kankan.

Mo sọ fún àwọn ènìyàn pé mó fẹ́ pa ara mi ṣùgbọ́n wọ́n ni kí n má ṣè é

Nígbà tí akọ̀ròyìn BBC Yorùbá ń bèèrè lọ́wọ́ Afolabi wí pé kí ló dé tí kò fi fọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ àwọn ènìyàn kó tó gbèrò láti gbẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀, ó ní òun ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó ní gbogbo àwọn tí òun sọ fún ni wọ́n gba òun nímọ̀ràn láti má ṣe bẹ́ẹ̀.

“Nígbà tí mo fẹ́ lọ ṣe gangan mi ò sọ fún ẹnìkankan mọ́.”

Ó fi kun pé ara òun ti ń balẹ̀ tí òun sì ti ń rí ìtọ́jú gbà ní ilé ìwòsàn tí òun wà.

Ọkọ ìyàwó tuntun dáná sun ara rẹ̀ ni Osun nítorí pe ìyàwó kò fií lọ́kàn balẹ̀

Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Muritala Afolabi ti farapa lẹyin to dana sun ara rẹ nipinlẹ Osun.

Amọ awọn eeyan kan tete doola rẹ, ti wọn si gbe digbadigba lọ sile iwosan kan niluu Iree, nibi to ti n gba itọju.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle Punch sọrọ lori ibusun aisan to wa,gni Afolabi ni oun gbe igbesẹ lati pa ara oun nitori bi iyawo oun ko ṣe fi oun ni ọkan balẹ.

Gẹgẹ bii oun to sọ, inu oṣu Keje, ọdun 2022 ni wọn ṣe igbeyawo, amọ ojojumọ ni iyawo rẹ naa maa n gbe ṣepe, to si ma n sọ awọn ọrọ kobakungbe si.

O ni “Mo kan pinnu lati fopin si gbogbo rẹ naa ni.”

“Mo lọ sile epo, mo ra epo bẹtiro, mo si lọ sinu igbo to wa ni ẹyin ile ẹkọ Baptist High School, ni Iree, lati dana sun ara mi.”

“Mo ronu nipa gbogbo ohun ti mo n la kọja, mo si pinnu lati pa ara mi.

 “Ko si owo lọwọ mi, iyawo mi si maa n gbe mi ṣepe lojojumọ lo jẹ ki n sọ ireti nu, bẹẹ, inu oṣu Keje ọdun yii ni a ṣe igbeyawo.”

O tẹsiwaju pe “Lẹyin ti mo dana si ara mi tan lawọn eeyan kan sara wa sibi ti mo wa lati doola mi, ti wọn si gbe mi wa sile iwosan yii.”

Ki ni kiyawo rẹ sọ?

Nigba ti awọn akọroyin kan si iyawo ọkunrin ọhun, Ifedolapo, o ni irọ ni pe oun maa n gbe ṣepe.

Obinrin naa ni “Mi o mọ eredi to ṣe lọ dana sun ara rẹ.”

“Emi ni iyawo rẹ lootọ amọ mi o tii bi ọmọ fun.”

A ṣi n gbiyanju lati ba tọkọtaya naa, ati ẹbi wọn sọrọ. Ẹ tẹti leko.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọrọ a n dana sun ara ẹni yoo waya laarin lọkọ-laya

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu ọdun yii naa ni obinrin kan, Ifeoluwa Bamidele, dana sun ọkọ rẹ lori ẹsun pe oloogbe naa n yan ale nipinlẹ Osun yii kan naa.

Iroyin ni afurasi naa tan ẹrọ amunawa ‘generator’ lasiko to dana sun ọkọ rẹ Bamidele lori ibusun ki ariwo ẹrọ naa ma ba jẹ ki awọn eeyan gbọ igbe rẹ lati doola ẹmi rẹ.

Amọ lẹyinorẹyin ti iroyin kan Ifeoluwa lara pe ọkọ rẹ Bamidele ti ku, ti awọn agbofinro si n wa kiri, loun naa ba gbe oogun jẹ, to si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe.