Àgbàrá òjò wú òkú tó lé ní 500 jáde ní ìpínlẹ̀ Niger

Ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ iboji oku, ti agbara ojo bajẹ ni ilẹ isinku kan nilu Mariga, nipinlẹ Niger.

Bakan naa lo tun wọ́ iboji to le ni ẹẹdẹgbẹta lọ.

Omiyale bẹrẹ lẹyin ti ojo nla ti n rọ fun ọpọlọpọ ọjọ ni agbegbe naa.

Imaamu ilu naa, Alhassan Musa Na’ibi, sọ fun BBC pe iru iṣẹlẹ alagbara bẹẹ ko waye ri ni ilẹ isinku naa lati bi ẹẹdẹgbẹta(500) ọdun ti wọn ti kọ ọ.

Bakan naa ni imaamu sọ pe awọn ti tun oku bi ẹgbẹrun kan to ti jẹra sin.

Bo tilẹ jẹ pe iroyin sọ pe iboji oku naa sun mọ odò kan, awọn olugbe agbegbe ọhun sọ pe awọn to n wa kusa goolu nitosi ilẹ isinku ọhun lo mu ki iṣẹlẹ naa buru to bẹẹ nitori pe “ilẹ ibẹ ko l’agbara mọ’.

Ẹkun omi naa ni eyi to buru ju ti ipinlẹ Niger koju lati bi ọdun mẹwaa.

Lati ibẹrẹ oṣu Keje, ko din ni ọọdunrun eeyan to ti ku nitori ẹkun omi, ti ọpọ to ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan si di alainile lori tabi sa asala kuro nilu wọn.

Awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe ọpọ ẹkun omi ni yoo tun waye nitori awọn ojo nla ti yoo tun rọ.