Ìpolongo ìbò 2023 gbéra sọ, wo nkan tí àwọn olùdíje kò gbọdọ̀ ṣe

Oni, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni eto ipolongo ibo fun awọn ẹgbẹ osẹlu bẹrẹ, ni imurasilẹ fun idibo gbogbo gbo ọdun 2023.

Ipolongo ibo naa yoo waye fun oṣu maarun-un gbako titi si oṣu Keji ọdun 2023, ti idibo yoo waye.

Igba akọkọ niyii ti eto ipolongo ṣaaju ọjọ idibo, wọ oṣu maarun-un ninu itan idibo ni Naijiria.

Ṣaaju asiko yii, kii ju bi oṣu mẹta lọ.

Bi oludije kọọkan ati ẹgbẹ oṣelu wọn yoo ṣe ma a lọ kaakiri lati fa awọn oludibo loju mọra, ajọ INEC ti fi awọn ilana ti wọn gbọdọ tẹle sita.

Awọn ilana ati ofin naa ko yọ awọn alatilẹyin wọn naa silẹ.

Awọn ilana naa lo wa ni ibamu pẹlu ofin idibo ọdun 2022.

Wo àwọn ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn olólùfẹ́ wọn lè ṣe àti èyí tí wọn kò lè ṣe lásìkò ìpolongo ìbò 2023

Bẹrẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2022, awọn ẹgbẹ oṣelu at’awọn ololufẹ wọn yoo lanfani ati bẹrẹ ipolongo ita gbangba fun idibo to n bọ lọdun 2023 lorilẹede Naijiria.

Lati le rii daju pe gbogbo nnkan lọ ni mẹlọmẹlọ, ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti ṣalaye gbogbo ofin makan ti awọn oludije, ẹgbẹ oṣelu won, at’awọn ololufẹ wọn gbodo tẹle.

Igba akọkọ si niyi latigba ti Naijiria ti n seto idibo, ti wọn yoo maa la aadọjọ ọjọ tabi oṣu marun un silẹ fun ipolongo ibo ni ibamu pẹlu abala kẹrinlelaadọrun iwe ofin idibo tọdu. 2022.

Abala yii tun laa kalẹ pe gbogbo eto ipolongo gbọdọ pari nigba to ba ku wakati mẹrinlelogun si ọjọ ibo gangan.

Abala naa ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu tabi ololufẹ rẹ yoowu to ba dagunla gbedeke wakati mẹrinlelogun si ọjọ yiilati dẹkun ipolongo ibo wọn yoo san owo itanranto to ẹgbẹrun lọna ẹdẹgbẹta naira.

Bo ba si jẹ ileeṣẹ iroyin lo tapa si ofin yii, miliọnu kan naira lowo itanran rẹ

Yatọ si ofin to de akoko ipolongo, ki lawọn ohun miran to yẹ k’awọn eeyan mọ niyii.

Ko gbọdọ ṣi ọrọ alufansa tabi eebu gẹgẹ bi abala ikejilelogun iwe ofin idiboNaiiria tọdun 2022 ṣe sọ. Ko gbọdọ si ilo ọrọ to lee fa wahala, rukerudo tabi yanponyanri lasiko ipolongo ibo naa.

Awọn Ibudo ipolongo

Awọn agbegbe kan wa ti ofin ko tilẹ fi aye rẹ silẹ fun ẹnikẹni lati ṣe ipolongo idibo tabi ipade ipolongo ita gbangba.

Ipin kẹta abala kẹtalelaadorun iwe ofin idibo Naijiria ṣalaye pe tokan sí awọn agbegbe naa gẹgẹ bí ile ijọsin, agọ ọlọpaa atawon ọfiisi ijọba gbogbo.

Gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo lẹtọ lati seto ipolongo ibo

Ofin naa fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu at’awọn oludije wọn ni anfani lati seto ipongo nigbakugba to ba wu wọn.

O lodi si ofin idibo Naijiria fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ lati kọlu ẹgbẹ oṣelu kankan tabi eto ati ilana ti wọn sinmi le.

Nitori eyi, ko gbọdọ si ẹgbẹ oṣelu tabi oludije kankan to gbọdọ lo egungun fun ipolongo idibo.

Bakanna lo tako ofin lati ko awọn agbero tabi januku jọ lati kọ wọn, tabi ko ohun ija oloro le wọn lọwọ nitori oṣelu.

 Ijiya fun didi awọn miran lọwọ láti ṣe ipolongo

Awọn alamojuto ibo ni agbekalẹ ijiya to yẹ fun ẹgbẹ oṣelu yoowu tabi oludije yoowu to ba tẹ oju ofin mọlẹ nipa did awọn miran lọwọ siseto ipolongo wọn nirọwọrọsẹ.

Owo itanran milionu kan naira tabi fi ẹwọn oṣu mejila oludije to ba ṣe eyi yoo fi jora.

Bo ba si jẹ ẹgbẹ oseluni, miliọnu meji naira ni fun igba akọkọ, milionu kan naira ni yoo maa san lẹyin eyi.

Bo ba si jẹ pe nṣe lonitọhun n ṣe agbodegba fun iwa itapasofin yii, ẹẹdẹg ẹta ẹgbẹrun naira ni yoo fi jora tabi ẹwọn ọdun meta tabi mejeeji gan.

Bi o ba lo iwa ipalati fi mu ki eeyan kan ti ẹgbẹ oṣelu kan lẹyin, ẹsẹ nla leyi labẹ ofin idibo Naijiria, bi o ba jẹ oludije kan ni tabi ọpọ eeyan ni, miliọnu kan naira ni ọwọ itanran wọn.

Bi o ba wa jẹ egbe oṣelu lo ṣe eyi, miliọnu meji naira ni owo itanran rẹ, bi won ba si tun sẹ ẹṣẹ yii, okare

Bawo ni awọn agbofinro ṣe gbọdọ huwa?

Ọrọ abo jeyo labẹ iwe ofin idibo Naijiria, ọdun 2022.

Gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo l’asẹ ati ẹtọ si abo agbofin.

Bẹẹni awọn kọmiṣọna olopaa fun ipinlẹ kọọkan ati olu iLu Nàìjíríà lo sí gbọdọ fun won.

Ipin keji abala ofin naa sọ pe agbofinro ti wọn ko ba ran lọ si ibudo ipolongo ibi ko gbọdọ si ni sakani ibẹ.

Bakanna ni ipin kẹta abala kọkanlelaadọrun iwe ofin idibo Naijiria tun fa awọn ọlọpaa at’awọn agbofinro yoku leti pe, bi o ti wu ki agbara ti awọn abala iwe ofin mirqn fun wọn ṣe le pọ to, ojuṣe kan ṣoṣo tí wọn ni nibudo ipolongo ni kiwon o mojuto alaafia nibẹ.

 Awọn ileesẹ iroyin ijọba ati ipolongo idibo

Ko si oludije tabi ẹgbẹ oṣelu to laṣẹ lati lo dukua ilu – ninu eyi ti ileeṣẹ iroyin wa, fun anfani ara rẹ laifun awọn oludije miran niru a fani bẹẹ.

Gbogbo awon ileesẹ iroyin ti ijọba ati aladani gbọdọ ya iye akoko tabi aye kan naa si ọtọ fun gbogbo oludije tabi ẹgbẹ oṣelu niwọn igba ti wọn ba ti san owo to yẹ ki wọn san.

Bi ileeṣẹ iroyin kan ba tapa si ofin yii, owo itanran miliọnu meji ni yoo san fun ìgbà àkọkọ. To ba run tapa si ofin tii lẹyin eyi, miliọnu marun un naira ni yoo maa san.

Awọn lọgalọga nileese iroyin bẹẹ yoo si tun fi miliọnu kan nairan owo itanran jura tabi ẹwọn oṣu mẹfa.

Lakotan, ofin yii ko fi aye silẹ fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu kankan lati fi ẹsin, ẹya tabi ohun ẹya kan polongo tako ẹgbẹ oṣelu kankan.

Bi o ba jẹ eeyan kan lo rufin yii, owo itanran miliọnu kan naira ni tabi ẹwọn oṣu mejila, o si lee fi mejeeji jora.