Kílódé tí ìgbẹ́jọ́ kò fi wáyé lórí ẹ̀bẹ̀ Adedoyin láti lọ tọ́jú ara rẹ̀?

Igbẹjọ iku Timothy Adegoke to yẹ ko waye ni ọjọ Ẹti foriṣanpọn.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn agbofinro ko ṣe gbe awọn afurasi to n jẹjọ ipaniyan naa.

Nibi igbẹjọ to yẹ ko waye lonii, ni oludasilẹ ile itura Hilton Resorts Hotel, Ile-Ife, Rahman Adedoyin, yẹ ko ti mọ boya ile ẹjọ yoo gba beeli rẹ nitori ilera ara rẹ.

Agbejoro olùjẹ̀jọ́ rọ ile-ejọ ṣáájú lati bere fún ìwé ipo ilera Ogbeni Adedoyin ti o ni awọn ailera diẹ ni ọgbà ẹwọn ti o wa.

Ṣugbọn agbẹjọro naa paapaa ko yọju sile ẹjọ lọjọ Ẹti.

Abejoro Fatima Adeshina to n soju ẹbi oloogbe Adegoke nikan lo wa. Bakan naa ni agbẹjọro ọkan lara awọn afurasi naa, to jẹ oun gan-an ni afurasi akọkọ, naa wa sile ẹjọ.

Agbejoro awọn prison naa wa ni ile ẹjọ bakanna.

Adajo Adepele Ojo ti wa sun ẹjọ naa di ọjọ kẹwa, oṣu Kẹwaa, ọdún 2022 lati fun àwọn agbejoro Timothy Adegoke ni aaye lati ko awijare wọn jọ lori idi ti ile ẹjọ naa ko gbọdọ fi fun Adedoyin ni beeli.

Rahman Adedoyin fẹ́ kí ilé ẹjọ́ gba béèlì rẹ̀ nítorí ìlera rẹ̀

Oni, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2022, ni igbẹjọ Rahman Adedoyin yoo tun tẹsiwaju niluu Osogbo.

Ohun ti igbẹjọ oni yoo da le lori ko ṣẹyin ẹbẹ Adedoyin pe ki ile ẹjọ fun oun laafani lati lọ tọju ara oun.

Afurasi ọhun atawọn mẹfa mii, ti wọn jẹ oṣiṣẹ rẹ nile itura Hilton, eyii to wa niluu Ile Ife ni wọn n jẹjọ niwaju adajọ lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku Timothy Adegoke, to jẹ akẹkọọ fasiti Ile Ife, OAU.

Ko pẹ ti igbẹjọ naa bẹrẹ ti awọn agbẹjọro Adedoyin ti n bẹ ile ẹjọ pe ki wọn fun ni beeli nitori aisan kan to n ba finra.

Gẹgẹ bii awijare wọn, itọju ti afurasi naa n gba lọgba ẹwọn to wa ko koju oṣuwọn to, wọn si n fẹ lati gba beeli rẹ, ko le lọ ṣetọju ara rẹ nigba ti ẹjọ naa yo si maa tẹsiwaju.

Lara awọn agbẹjọro to dantọ to n sọju mọlẹbi oloogbe naa ni agbẹjọro agba Naijiria, o tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan Femi Falana.

Kíló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ẹ ó rántí pé àjọ ọlọ́pàá ti kọkọ wọ́ ẹni tó ni ilé ìtura Hilton náà, Dókítà Ramon Adedoyin àti àwọn mẹ́fà mìíràn lọ sí ilé ẹjọ́ gíga kan nílùú Abuja lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sí ilé ìtura náà lọ́jọ́ kẹfà, oṣù kọkànlá, ọdún 2021.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun, lẹ́yìn tí wọ́n pé fùn gbígbé ẹjọ́ náà lọ sí ìpínlẹ̀ náà nítorí níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.

Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn Adedoyin ni sínsin òkú Adegoke lọ́nà àìtọ́, pípa ẹ̀rí ìwé owó tí Timothy Adegoke fi san owó rẹ́ àti yíyọ ẹ̀rọ ayàwòrán (CCTV) ilé ìtura náà rẹ́ lójúnà àti pa àwọn ohun tí kò bá jẹ́ ohun ẹ̀rí rẹ́.

Ẹ̀sùn ìpànìyàn, ìlẹ̀dí-àpòpọ̀, àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ni wọ́n fi kan àwọn mẹ́fà tó ku.