You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọmọọmọ Ọbabìnrin Elizabeth mẹ́jọ ṣe àìsùn níbi ìtẹ́ òkú rẹ̀
Ọmọọmọ Ọbabìnrin Elizabeth mẹ́jọ, tó fi mọ́ Ọmọọba Wales àti Duke ti Sussex ló dúró bí ọmọ ogun láti ṣe àìsùn. ́
Gbọngan Westminster níbi ti wọn tẹ òkú ọbabìnrin naa si lawọn ọmọ ọmọ naa duro si.
Ọmọọba Harry náà wọ aṣọ ogún lẹ́yìn tí Ọba Charles ti ní kí wọ́n gbà kí òun náà wọ aṣọ ọmọ ogun.
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí yóò wọ aṣọ ogun láti ọdún 2020 tó ti wọ aṣọ náà kẹ́yìn.
Láti ìgbà tí ọbabìnrin Elizabeth ti papò dà, ọmọọba Harry kò ì tíì wọ aṣọ ogun níbi gbogbo ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe.
Ìròyìn ní ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn ọmọọmọ ọba yóò máa kópa níbi ètò ìsìnkú ọba.
Àwọn ọmọ-ọmọ náà ni William àti Harry tó jẹ́ ọmọ Ọba tuntun, Ọba Charles Kẹta, Peter Phillips àti Zara Tindall tó jẹ́ ọmọ Ọmọọbabìnrin Anne.
Àwọn yòókù ni Ọmọọbabìnrin Beatrice àti Eugenie tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọọba Andrew.
Arábìnrin Louise Windsor àti James Viscount Severn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọọba Edward.
Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ni àwọn ọmọọmọ náà fi dúró bí ológun sí ẹ̀gbẹ́ pósí òkú ọbabìnrin náà.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, àwọn ọmọ Ọbabìnrin Elizabeth, to fi mọ́ Ọba Charles dúró sí ibí òkú rẹ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá.
Atọ́nà wa ni Ọbabìnrin Elizabeth
Ṣaájú kí àìsùn náà tó bẹ̀rẹ̀, Beatrice àti Eugenie ní ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún àwọn láti jẹ́ ọmọọmọ ọbabìnrin Elizabeth.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí àwọn méjéèjì fi síta ní àwọn máa ṣe àfẹ́kù ọbabìnrin náà gidi gan nítorí atọ́nà àwọn ló jẹ́ pàápàá lórí ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé wọn.
Bákan náà ni wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ ọbabìnrin náà fún gbogbo ohun tó ṣe nínú ìgbé ayé àwọn àti gbogbo àgbáyé.
"Gbogbo ayé ló ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀, a sì mọ̀ wí pé gbogbo nǹkan tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa rẹ yóò máa dá ẹ̀rín pa ẹ̀kẹ́ rẹ àti pé yóò ṣàfihàn pé olórí gidi ni ẹ́"
Wọ́n fi kun pé àwọn nígbàgbọ́ pé ọbabìnrin yóò ti pàdé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.
Wọn fikun pe Ọba Charles yóò tọpasẹ̀ rere tí ọbabìnrin náà fi lélẹ̀ bó ṣe ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fi ẹ̀mí rẹ̀ jìn iṣẹ́ ìsìn ọmọnìyàn.
Àìsùn ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọmọọba Harry yóò wọ aṣọ ogun láti ìgbà tó ti fi iṣẹ́ oyè sílẹ̀ lọ́dún 2020.
Ní ìlú California ló ń gbé báyìí pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Meghan àti àwọn ọmọ wọn méjì.
Bákan náà ni ọmọọba Andrew wọ aṣọ ogun nígbà tí òun náà ṣe àìsùn lọ́jọ́ Ẹtì.
Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe níbi Ètò BBC kan Newsnight, nípa ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan tó ń kojú ẹ̀sùn nípa ìbálòpọ̀, Jeffrey Epstein ni Andrew fi iṣẹ́ oyè sílẹ̀ lọ́dún 2019.
Nígbà náà ni wọ́n gba gbogbo oyè ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀.