You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bimbo Oshin sọ̀rọ̀ sókè bí ikú ọkọ rẹ̀, Dudu Heritage ṣe pé ọdún kan
Mo rò pé ẹ̀mí mi ti dúró, ayé parẹ́, òòrùn kò yọ mọ́ nígbà tí kọ́ mi kú - Bimbo Oshin
Ọjọ ree bi ana, ti iji ja, ti afẹfẹ lile fẹ, eyi to da omi inu agbọn nu nile gbajugbaja onileesẹ Dudu Heritage, ta mọ si Oladiran Ishola Ibironke tabi Ola Ibironke.
Ọjọ Kejila osu Kẹsan ọdun 2021 ni Ola Ibironke, tii se ọkọ gbajumọ osere tiata nni, Bimbo Oshin sadede dagbere faye eyi to ti pe ọdun kan sẹyin bayii.
Nigba to n ranti iku ọkọ rẹ́ naa ati bi akoko naa se waye, Bimbo Oshin, loju opo Instagram, sọrọ aro to lagbara eyi to se afihan ohun to la kọja laarin ọdun kan naa.
Bimbo Oshin, ninu fidio naa to ti n se idaro ọkọ rẹ, se akojọpọ awọn obinrin lorisirisi nipa oun ati oloogbe naa, to si fi ọrọ aro awunilori tii nidi.
"Mo ro pe oorun ko ni tan mọ, osupa ko si ni jade sita mọ nigba ti ọkọ mi ku"
Bimbo, kọ ọrọ sabẹ fidio idaro naa pe “Hmmmm...Bawo ni akoko se n lọ bayii, o ti yaa pe ọdun kan to fi wa silẹ lọ, Olowo Ori mi.
Mo ro pe aye ti duro si oju kan ni, nigba to ku, ti mo si ro pe oorun ko ni tan mọ, mo tun ro pe osupa ko ni jade sita mọ.
Koda, mo ro pe emi gan ko ni le mi mọ, ọkan mi gbọgbẹ pupọ amọ Ọlọrun pa gbogbo ohun to fi silẹ mọ lati ọdun kan sẹyin, ti aanu rẹ si duro lori wa.”
Bimbọ Oshin tun tẹsiwaju pe so ti yara pe ọdun kan naa nuu, ti mo gbọ ohun rẹ kẹyin, ọkọ mi, baba mi, ọrẹ mi.
Ọkan mi se ẹjẹ nigba ti mo ri pe emi ati ẹ ko tun ni le foju kan oju mọ, amọ awọn iranti rẹ to se iyebiye si mi ni maa di mu ni ọkan mi niwn igba ti mo ba wa loke eep.
Mo mọ pe o n sinmi ldọ Ẹlẹda rẹ ni, Sun re o Oladiran Ishola Ibironke, ta tun mọ si Dudu Heritage, a fẹ ọ, ta si n se aaro rẹ, Ọba mi.”
Ọpọ awọn osere tiata si lo ti n ki Bimbo Oshin ku idaro ọdun kan ti ọkọ rẹ papoda naa.
Ki ni ajọsepọ Ola Ibironke ati Bimbo Oshin?
Tọkọ taya ni Ola Ibironke ati Bimbo Oshin jẹ, ki oloogbe naa to papoda.
Ola Ibironke si lo ni ileesẹ kan ti wọn n pe ni Dudu Heritage, to maa n ba awọn akọrin gbe awo orin wọn jade.
O gbe ni ilẹ America fun ọpọlọpọ ọdun ko to ko pada wa si Naijiria, Dudu Heritage si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Osun.
Bi Ola Ibironke se kawe gboye ni Naijiria, lo tun ka ni London ati America.
Lọdun 2005 ni iroyin ni o gbe Bimbo Oshin, ẹni tii se gbajugbaja osere tiata lede Oyibo ati Yoruba niyawo.
Oluwa fun wọn ni ọmọ meji: Michael Olusegun Ibironke ati Iyanuoluwa Ibironke.
Amọ saaju ko to fẹ Bimbo Oshin, ni Ola Ibironke tii fẹ aya akọfẹ rẹ, Olusola Ibironke, ti onitọun si n gbe nilu oyinbo.