Mọ̀ síi nípa Ola Ibironke, Dudu Heritage, ọkọ Bimbo Oshin tó jẹ́ gbajugbaja to n gbé iṣẹ́ olórin síta tó ṣáláìsí

Opọ awọn eeyan ni wọn ti n ṣe idaro Ola Ibironke to jẹ oludari Dudu Heritage to doloogbe.

Koda awọn akẹgbẹ Bimbo Oshin to jẹ oṣere fiimu Yoruba lo ti lọ si ile wọn ni agbegbe bodija nibadan. Ara ore ojulumo ti pejopo lati kedun.

O jẹ ẹni to n ba awọn eeyan gbe orin jade.

O gbe ni ilẹ America fun ọpọlọpọ ọdun ko to ko pada wa si Naijiria.

Dudu Heritage jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Osun.

Ola Ibironke kawe gboye ni Naijiria, o tun ka ni London ati America.

Lọdun 2005 ni iroyin ni o gbe Bimbo Oshin niyawo.

Oluwa fun wọn ni ọmọ meji: Michael Olusegun Ibironke ati Iyanuoluwa Ibironke.

Ikú dóró! Dudu Heritage, olówó orí Bimbo Oshin ti jáde láyé

Ola Ibironke, ti ọpọ eeyan mọ si Dudu Heritage to jẹ ọkọ fun gbajugbaja oṣerebinrin Bimbo Oshin ti jade laye.

Iroyin naa ni ọkunrin naa deede subu ni nilu Ibadan.

Ola Ibironke gbe nilẹ America fun ọpọlọpọ ọdun ko to pada wa si Naijiria wa

Titi di asiko yii a ko tii le sọ ohun to pa a ṣugbọn ẹbi wọn ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe Ola Ibironke ti doloogbe.

Wọn ni pe o deede ṣubu ni lale ọjọ Aiku ni Ibadan.

Dudu Heritage n gbero lati gbalejo awọn agbabọọlu ẹyin ori papa gọọfu ni Naijiria laipẹ fun idije to m bọ lọna ni ọlọjọ de.