Odunlade Adekola: Kò sí ohun tó jọ eré ìfẹ́ láàrín èmi àti ọ̀gá mi - Adenike Hamzah

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oṣere tiata Yoruba, Adenike Hamzah ti sọ pe oun ko ba ọga oun, Odunlade Adekola ṣere ifẹ gẹgẹ bii iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri.

Adenike lo fi ọrọ naa lede ninu fidio kan loju opo Instagram rẹ nibi to ti ke si awọn eeyan lati ma ba ọjọ ọla oun jẹ ninu iṣẹ tiata.

O ni "Mo n ṣe fidio yii lati fesi si ọrọ to n lọ nigboro kan pe mo n fẹ ọga mi Odunlade Adekola."

"Emi Adenike Hamzah ko ṣe nnkan to jọ bẹẹ o, mi o ṣe iru rẹ ri, mi o si ni ṣe bẹẹ lailai."

O ni oun ko tii fi igba kankan fi eeyan sinu ere ri ki Odunlade Adekola ba le nianfaani lati ba irufẹ ẹni bẹẹ lopọ.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, irọ nla ati ahesọ ọrọ ni awọn eeyan kan n gbe kiri pe ere ifẹ wa laarin oun ati Odunlade Adekola.

O ni ọpọlọpọ eeyan lo ti di gbajumọ lati ara Odunlade Adekola ko si tọ ki awọn eeyan ba orukọ oṣere naa jẹ nipa sisọ ọrọ kobakungbe pe o n ba awọn ọmọ abẹ rẹ ni ibalopọ.

Lẹyin naa lo ke si awọn eeyan to n sọ ọrọ naa pe ki wọn dẹkun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ ọhun kiri.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Odunlade Adekola naa ti kọkọ fi fidio kan lede oju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe oun ko ba ọkankan ninu awọn ọmọ abẹ oun lopọ.

Ninu fidio naa lo ti pe awọn to n sọ ọrọ naa nija lati mu ẹri wọn jade.

Bẹẹ naa lo tun ke si awọn oṣere ti ọrọ kan lati wa sọ ni gbanba to ba jẹ pe oun ti fi igba kankan fi ibalopọ lọwọn ri ki oun to fi wọn sinu ere.