Kókó mẹ́rin tó wà nínú ọ̀rọ̀ Kamala Harris níbi ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú Democratic Party tó wáyé

Lalẹ Ọjọbọ to kọja ni Kamala Harris sọ pe oun ti gba lati jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu Democratic ninu eto idibo to n bọ, o sọ eyi lasiko to n sọrọ, to si sọ awọn koko ohun ti eto ipolongo yoo nilo – to si tun fi itan tuntun miran lelẹ.
Itan tuntun to fi balẹ ni bi wọn ṣe yan-an gẹgẹ bi obinrin akọkọ ti ko ni alatako ti wọn yoo fa kalẹ fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ naa.
“Ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni sọ iru eeyan ti o jẹ fun ẹ,” ohun ti Harris sọ ree. “O ni lati jẹ ki wọn mọ iru eeyan ti o jẹ.”
Fun bi iṣẹju marundinlaadọta l’Ọjọbọ, o gbiyanju lati sọ nipa iru eeyan to jẹ fun gbogbo ara Amẹrika – ati awọn ohun ti yoo ṣe to ba yege fun ile funfun (White House).
Awọn koko pataki mẹrin amurele to mẹnuba ba lasiko to n kadi ọrọ rẹ nilẹ.
Harris ṣe agbelarugẹ fun awọn gbongbo ibi to ti wa
Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ni wọn mọ iru eeyan ti Harris jẹ, ṣugbọn kii ṣe pupọ wọn lo mọ awọn ohun to gbagbọ ninu rẹ tabi ẹkunrẹrẹ nipa ibi to ti ṣẹ wa. Fun igba akọkọ, awọn ọrọ rẹ nibi ipagọ naa ṣe awọn ayipada.
O ṣe iranti awọn irin ajo mama rẹ gẹgẹ bi ẹni to wa tẹdo si Amẹrika lati orileede India. O sọ nipa bi awọn obi rẹ ṣe pade – ati bi wọn ṣe kọ ara wọn silẹ. O sọrọ nipa kekere rẹ ati bo ṣe bẹrẹ iṣẹ ni Oakland, California.
“Mo wa lati idile ti kii se olowo, ti ebi ko si pa wa,” o sọ bẹẹ. “Iya mi gbe odiwọn le iye to n na. A n gbe pẹlu iye to n wọle fun wa. Sibẹ, a n fẹ awọn ohun kan. Ati pe o n fẹ ka maa ṣamulo awọn oniruuru anfaani to ba n gba iwaju wa kọja.”
Arabinrin Harris tun sọ nipa idi to fi yan iṣẹ agbẹjọro laayo – ati iṣẹ olufẹsunkanni nile ẹjọ. O ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ibẹrẹpẹpẹ rẹ nile ẹjọ ati iṣẹ isinlu gẹgẹ bi oloṣelu.
“Gbogbo igbe aye mi nidi iṣẹ yii, onibara kan ṣoṣo ni mo ni,” o jẹ ko di mimọ. “Awọn eeyan.”
Afojusun fun ọjọ iwaju – pẹlu alaye diẹ
Ninu awọn ọrọ Arabinrin Harris lo ti pe fun iṣọkan ati opopona to kọja “ikoro ọkan, gbigba pe awọn eeyan ni ifẹ ara ẹni, ogun apinni” ninu eto oṣelu igbalode ilẹ Amẹrika.
O sọ pe ilẹ Amẹrika ni anfaani “iyebiye, ohun ti kii pẹ” lati “wa ọna agbekalẹ tuntun fun itẹsiwaju”. Ṣugbọn agbekalẹ naa ni alaye diẹ ninu.
Pipe fun iṣọkan ati ọna agbekalẹ to kọja ojusaaju jẹ ohun ti pupọ awọn to n woju fun ipo aarẹ ti lo sẹyin.
Nigba ti Arabinrin Harris n mẹnuba awọn agbekalẹ ilana, o sọ ọ bo ṣe ri kaakiri.
O loun yoo gbajumọ jija owo ohun ti awọn eeyan yoo maa nilo lojoojumọ walẹ - bii eto ilera, owo ile ati awọn ẹṣọ. O mọ-ọn-mọ tẹnumọ ẹtọ lati ṣẹ oyun – to si lo wa lara ọna lati daabo bo ominira, eyi to ti n jẹ ohun atẹnumọ nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu Democratic.
“Amẹrika ko le ṣe aṣeyọri ayafi bi anfaani ba wa fawọn ọmọ ilẹ Amẹrika lati ṣe ipinnu ara wọn lori igbesi aye wọn, paapaa lori ohun to nii ṣe pẹlu ọkan ati ile,” ọ sọ bẹẹ.
Arabinrin Harris, ninu ọrọ rẹ, mu erongba rẹ to yatọ lọna to rọrun, to si tan imọlẹ si awọn agbekalẹ ilana rẹ tuntun ati ti ọga rẹ, ọkunrin to ni ireti lati rọpo, Joe Biden.
“Gbogbo ibi ti mo ba lọ, ati awọn ti mo ba ba pade, mo ri orileede to ṣetan lati tẹsiwaju,” o sọ eyi. “A ṣetan fun igbesẹ to kan, ninu irin ajo daradara ti ilẹ Amẹrika.”
Ohun ti ẹkunrẹrẹ igbesẹ naa jẹ, ju gbogbo rẹ lọ, ni yoo pinnu rẹ.
Awọn atẹjiṣẹ ogun Gaza ti ko yi pada
Pẹlu bi awọn alatilẹyin Palestine ṣe korajọ siwaju ile ipagọ naa, Arabinrin Harris sọrọ lori ohun to ṣe koko nipa ilana to nii ṣe pẹlu ọrọ ile okeere, to si mẹnuba ogun to n waye ni Gaza.
Nibi, lẹẹkan si, awọn iyatọ diẹ lo wa laarin arosọ ati erongba rẹ ati ti Ọgbẹni Biden – to si ti so ara rẹ papọ mọ aarẹ lọpọ igba
“Aarẹ Biden ati emi jọ n ṣiṣẹ yipo agogo,” o sọ bẹẹ, “nitori pe ni bayii, o ti to asiko lati tọwọ bọwe adehun ti yoo da ogun duro.”
O tun ṣeleri lati rii daju pe awọn Israel n ni agbara lati daabo bo ara rẹ, ki wọn si mu iwe kan ni pato nipa ikọlu Hamas lọjọ keje, oṣu Kẹwaa.
Fun igba diẹ, o sọ ọ bi ẹni pe awọn eero yoo dide, ṣugbọn Arabinrin Harris sare tẹsiwaju pẹlu ohun ti awọn ara Palestine n fẹ, to si ni bi wọn ṣe n jiya jẹ eyi to “ba ni lọkan jẹ.”
Eyi lo ṣoro lati tẹ awọn oluwọde to wa nita lọrun, bii pe ki wọn pada sile wọn – awọn kan ti wọn wa logun ogun bii Michigan – ni wọn ṣe iyemeji sii pe iṣakoso Aarẹ Harris yoo jẹ itẹsiwaju ilana Biden si ogun to n waye ni Gaza.
‘Alawada’ ni Trump, ṣugbọn to tun jẹ ewu
Lọjọ meji sẹyin, Michelle ati Barack Obama da ẹgbẹ kan silẹ to yẹpẹrẹ aarẹ tẹlẹri, Donald Trump, ni eyi ti wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ohun idaamu atigbadegba ti ko ṣe pataki ati ẹni yẹpẹrẹ
Arabinrin Harris sọrọ nipa alatako rẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu Republic, ṣugbọn to jẹ agbekalẹ ọwọ fun Democratc – to fi mọ Biden – lati bi oṣu meloo kan sẹyin.
“Ni ọpọ ọna, Donald Trump kii ṣe ẹnikan to ṣe pataki, nitori pe ọrọ rẹ ko ṣee ka si,” o sọ bẹẹ. “Ṣugbọn atubọtan lati fi Trump ṣeyin White House lewu gidigidi.”
O ṣe iranti ikọlu ọjọ kẹfa, oṣu Kinni to waye ni US Capitol pẹlu awọn alatilẹyin Trump, to si tun mẹnuba awọn iwa ọdaran to ti gba idajọ rẹ.
Bakan naa lo tun mẹnuba ohun ti awọn Democratic ti sọ di baagi abẹṣẹkubiojo, iṣẹ akanṣe Heritage Foundation ti ọdun 2025, to jẹ agbekalẹ nla fun iṣejọba Republican.
Bo tilẹ jẹ pe aarẹ ana naa ti sọ pe oun ko nii tẹwọ gba a, o sọ pe oludamọran pataki oun lo kọ ọ jade, ti yoo si “fa orileede wa pada sẹyin si ohun to ti kọja”.
Ọjọ iwaju ati ọjọ to ti kọja ti jẹ ohun atẹnumọ ti ipolongo Harris tipẹ, bẹẹ lo si wa ninu ọrọ rẹ to fi gba iyansipo.
O jẹ ọkan lara awọn ọna ti igbakeji aarẹ naa ti n lo, kii ṣe fun alatako rẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu Reblican nikan, bi ko ṣe fun ọga rẹ ti ko gbajumọ mọ, Joe Biden, ẹni ti wọn ni ko lọ jokoo lọsẹ diẹ sẹyin.















