Àríwísí àwọn gbajúmọ̀ rèé lẹ́yìn tí Bobrisky la àwọn obìnrin mọ́lẹ̀ gbadé obìnrin tí imura rẹ ta lẹ́nu jùlọ

Oríṣun àwòrán, Bobrisky Instagram
Ojumọ kan ara kan.
Eyi to gbode bayii ti awọn eeyan n ran lẹnu nipa ilumọọka gbajumọ nii Bobrisky si ni pe o gbade obinrin ti imura rẹ ta lẹnu julọ laarin awọn obiinrin to peju sibi afihan ere sinima nii: ‘’Ajanaku: Beast of Two Worlds’’.
Bobrisky ti orukọ rẹ gangan a maa jẹ Idris Okuneye jẹ ọkunrin to n mura bii to si n pe ara rẹ ni obinrin.
O la gbajumọ oṣere mii bi Toyin Abraham, Mercy Aigbe, Odunlade Adekola, Sola Sobowale ti wọn ro dẹdẹ nibi afihan sinima yi lati gba ẹbun owo miliọnu kan Naira.
Lọjọ Karundinlọgbọn oṣu Kẹta ni eto yi waye ni Circle Mall lagbegbe Lekki nilu Eko.
Aṣọ dudu rẹ to n tana yẹriyẹri ti Bobrisky ko si lo mu ki awọn adajọ idije ranpẹ naa gbade fun.
Oludije Big Brother Naija Level Up, Groovy lo gba ami ẹyẹ ọkunrin ti imura rẹ dantọ julọ.
Kaakiri loju opo ayelujara si ni awọn eeyan ti n tẹnu bọ ọrọ Bobrsiky yi tawọn oṣere ati gbajumọ oju opo ayeluajara naa si ti n da si.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Instagram screenshot
"Bẹẹ ni mo gbọ pe wọn gbe ami ẹyẹ fun Bobrisky pe oun ni obinrin ti imura rẹ ta lẹnu julọ.Ṣe obinrin tootọ abi ayederu obinrin ni?''
Ibeere ree lẹnu olorin nii Portable gẹgẹ bo ṣe wi ninu fọnran fidio kan to fi soju opo ayelujara.
Oṣere Nollywood ti awọn eeyan mọ bi owo nii, Dayo Amusa sọ ni tiẹ pe :
''Mo maa lọ si ibi afihan sinima akẹgbe mii kan ni lana ti wọn si lawọn fẹ fami ẹyẹ da obinrin ati ọkunrin to mura julọ lọla.Ẹ ma ṣi mi gbọ o, ko si laburu ki wọn fun ẹni to ba pegede lami yi ṣugbọn ọkunrin to n mura bi obinrin ti ṣe jẹ,Ki lo n daamu wa na? Ko ye mi o''
“Mi o gbọdọ ṣo pe awọn adajọ tabuku awọn obinri to wa nibi yi.Wọn ni kẹ mu ọkunrin kan ti obinrin kan, ẹ wa fọwọ rọ gbogbo wahala awọn agbatẹru eto yi danu pẹlu bi ẹ se gbe ọmọ ọba fọsun.Ki lo n daamu wa gaan?''
O fikun pe ti awọn to gbe eto ba fẹ fun ọkunrin to n mura bi obinrin ni ami ẹye, ki wọn kuku gbe eto kalẹ fun wọn labẹ isọri yi.
Daniel Regha naa sọ pe: ‘’Ododo ni Dayo Amusa sọ.Itabuku awọn obinrin to mura wa sibi ayẹye ni bi wọn ṣe gbe ami ẹyẹ fun Bobrisky.Amọ awọn agbatẹru eto nikan kọ lo lẹbi, awọn to fi bi ere bi ere tẹwọ gba ami ẹye yi naa da kun itabuku yii''
Bi Bobrisky ṣe ṣo ara rẹ di ilumọọka gbajumọ nidi imura bi obinrin
Lọdun 206 ni awon eeyan kọkọ bẹrẹ si ni jẹ orukọ Bobrisky lẹnu loju opo Snapchat.
Ko si ṣeyin bo ṣe n mura bi obinrin.
O fẹsẹ ara rẹ mulẹ loju opo yi de bi pe awọn eeyan a maa san owo to to ẹgbẹrun mẹwaa lati fi maa wo irn rẹ nibẹ.
Lati igba naa lo ti wa loju ọpọn ti ẹnu ko si sin lara rẹ pẹlu orisi awuyewuye to fi mọ eleyi to waye laarin oun ati aayo rẹ Tonto Dikeh.
Bẹẹ naa lo da awuyewuye mii silẹ nigba to n sọrọ nipa iṣẹ abẹ to loun n ṣe lati fi da biobinrin.
Koda a tun maa gba awon obinrin ni imọran lọna bi wọn yoo ṣe pade awọn ọkunrin to lowo lọwọ ti yoo maafẹ wọn.
Awọn to n tẹle joku opo rẹ ni Instagram sunmọ miliọnu marun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images















